-
Notifications
You must be signed in to change notification settings - Fork 3
/
Copy pathyor_trans.txt
3971 lines (3774 loc) · 503 KB
/
yor_trans.txt
1
2
3
4
5
6
7
8
9
10
11
12
13
14
15
16
17
18
19
20
21
22
23
24
25
26
27
28
29
30
31
32
33
34
35
36
37
38
39
40
41
42
43
44
45
46
47
48
49
50
51
52
53
54
55
56
57
58
59
60
61
62
63
64
65
66
67
68
69
70
71
72
73
74
75
76
77
78
79
80
81
82
83
84
85
86
87
88
89
90
91
92
93
94
95
96
97
98
99
100
101
102
103
104
105
106
107
108
109
110
111
112
113
114
115
116
117
118
119
120
121
122
123
124
125
126
127
128
129
130
131
132
133
134
135
136
137
138
139
140
141
142
143
144
145
146
147
148
149
150
151
152
153
154
155
156
157
158
159
160
161
162
163
164
165
166
167
168
169
170
171
172
173
174
175
176
177
178
179
180
181
182
183
184
185
186
187
188
189
190
191
192
193
194
195
196
197
198
199
200
201
202
203
204
205
206
207
208
209
210
211
212
213
214
215
216
217
218
219
220
221
222
223
224
225
226
227
228
229
230
231
232
233
234
235
236
237
238
239
240
241
242
243
244
245
246
247
248
249
250
251
252
253
254
255
256
257
258
259
260
261
262
263
264
265
266
267
268
269
270
271
272
273
274
275
276
277
278
279
280
281
282
283
284
285
286
287
288
289
290
291
292
293
294
295
296
297
298
299
300
301
302
303
304
305
306
307
308
309
310
311
312
313
314
315
316
317
318
319
320
321
322
323
324
325
326
327
328
329
330
331
332
333
334
335
336
337
338
339
340
341
342
343
344
345
346
347
348
349
350
351
352
353
354
355
356
357
358
359
360
361
362
363
364
365
366
367
368
369
370
371
372
373
374
375
376
377
378
379
380
381
382
383
384
385
386
387
388
389
390
391
392
393
394
395
396
397
398
399
400
401
402
403
404
405
406
407
408
409
410
411
412
413
414
415
416
417
418
419
420
421
422
423
424
425
426
427
428
429
430
431
432
433
434
435
436
437
438
439
440
441
442
443
444
445
446
447
448
449
450
451
452
453
454
455
456
457
458
459
460
461
462
463
464
465
466
467
468
469
470
471
472
473
474
475
476
477
478
479
480
481
482
483
484
485
486
487
488
489
490
491
492
493
494
495
496
497
498
499
500
501
502
503
504
505
506
507
508
509
510
511
512
513
514
515
516
517
518
519
520
521
522
523
524
525
526
527
528
529
530
531
532
533
534
535
536
537
538
539
540
541
542
543
544
545
546
547
548
549
550
551
552
553
554
555
556
557
558
559
560
561
562
563
564
565
566
567
568
569
570
571
572
573
574
575
576
577
578
579
580
581
582
583
584
585
586
587
588
589
590
591
592
593
594
595
596
597
598
599
600
601
602
603
604
605
606
607
608
609
610
611
612
613
614
615
616
617
618
619
620
621
622
623
624
625
626
627
628
629
630
631
632
633
634
635
636
637
638
639
640
641
642
643
644
645
646
647
648
649
650
651
652
653
654
655
656
657
658
659
660
661
662
663
664
665
666
667
668
669
670
671
672
673
674
675
676
677
678
679
680
681
682
683
684
685
686
687
688
689
690
691
692
693
694
695
696
697
698
699
700
701
702
703
704
705
706
707
708
709
710
711
712
713
714
715
716
717
718
719
720
721
722
723
724
725
726
727
728
729
730
731
732
733
734
735
736
737
738
739
740
741
742
743
744
745
746
747
748
749
750
751
752
753
754
755
756
757
758
759
760
761
762
763
764
765
766
767
768
769
770
771
772
773
774
775
776
777
778
779
780
781
782
783
784
785
786
787
788
789
790
791
792
793
794
795
796
797
798
799
800
801
802
803
804
805
806
807
808
809
810
811
812
813
814
815
816
817
818
819
820
821
822
823
824
825
826
827
828
829
830
831
832
833
834
835
836
837
838
839
840
841
842
843
844
845
846
847
848
849
850
851
852
853
854
855
856
857
858
859
860
861
862
863
864
865
866
867
868
869
870
871
872
873
874
875
876
877
878
879
880
881
882
883
884
885
886
887
888
889
890
891
892
893
894
895
896
897
898
899
900
901
902
903
904
905
906
907
908
909
910
911
912
913
914
915
916
917
918
919
920
921
922
923
924
925
926
927
928
929
930
931
932
933
934
935
936
937
938
939
940
941
942
943
944
945
946
947
948
949
950
951
952
953
954
955
956
957
958
959
960
961
962
963
964
965
966
967
968
969
970
971
972
973
974
975
976
977
978
979
980
981
982
983
984
985
986
987
988
989
990
991
992
993
994
995
996
997
998
999
1000
ỌRỌ ÌYÀNJÙ
Odò to ba gbagbe orisun rẹ, gbigbe lo ma ngbe
Éyin ti ájà bá kọkọ ni, ónilè ẹ lò fi n gè jẹ
Ẹyin ọmọ Odùduwà ẹjẹ ki a ran rawa létí wípé Ẹni tólèdè lóni ayé ibi ti wọn ti nsọ
Mo bẹ yin ẹ maṣe jẹki a tara wa lọpọ nítorí náà ẹ maṣe jẹki èdè Yorùbà parẹ
Èdè ti a kọ silẹ, ti a ko sọ, ti a ko fi kọ ọmọ wa, piparẹ ni yio parẹ
Ẹjẹ ki a gbiyanju lati ṣe atunṣe nípa sísọ èdè Yorùbà botiyẹ kasọ lai si idaru idapọ pẹlu èdè miran
Yorùbá lọkùnrin ati lobirin ẹ ranti wipe Odò to ba gbagbe orisun rẹ, gbigbe lo ma ngbe
Lágbára Ọlọrun, aoni tajo sọnu sajo o, ao kere oko délé o. Àṣẹ
Ọpọlọpọ oriṣiriṣi ounjẹ Yorùbá nparẹ lọ, nípàtàkì larin awọn to ngbe ìlú nla
Òwe Yorùbá ni Ki àgbàdo to de ilẹ aye, adìyẹ njẹ, adìyẹ nmu
Itumo eyi nipe ki a to bẹrẹ si ra ounjẹ latokere, a nri ounjẹ ilẹ wa jẹ
Awọn to ngbe ilu nla bi ti Èkó ko ri aye lati se ọpọlọpọ ounjẹ ilẹ wa, èyí ko jẹki àlejò mọ wipe Yorùbá ni oriṣiriṣi ọbẹ, ounjẹ ati ìpanu
Ni ọpọ ọdun sẹhin, irẹsi ki ṣe ounjẹ ojojumọ ṣugbọn fun awọn ọmọ igbalode, Irẹsi Burẹdi ati Indomie ti di ounjẹ
Ọpọlọpọ ko ti ẹ fẹ jẹ ounjẹ ibilẹ bi awọn ounjẹ òkèlè Iyán, Ẹba, Láfún àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Ti a ba ṣakiyesi, ọpọ ọmọ to dagba si Èkó, ko mọ wipe Yorùbá ni ju ọbẹ ata ati ẹfọ lọ
Ọbẹ ata lo yá lati fi jẹ irẹsi, nítorí ọpọ ninu awọn ọmọ wọnyi le jẹ irẹsi lojojumọ, larọ, lọsan ati lalẹ
Ni ìlú Èkó, sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ ko jẹ ki obi tètè délé lẹhin iṣẹ ojọ wọn, ẹlo miran ti ji kuro nílé lati bi agogo mẹrinabọ lai pada sílé titi di agogo mẹwa alẹ nígbàtí awọn ọmọ tisùn
Nítorí èyí ọpọ òbí ko ri aye lati se ounjẹ Yorùbá
Àìsí ina manamana dédé tun da kun ifẹ si ounjẹ pápàpá
Ìyàlẹnu ni wipe ọpọ awọn ti ówà l'Okeokun ngbe ounjẹ Yorùbá larugẹ ju awọn ti ówà ni ilé lọ pàtàkì ni ilu nla
Oṣeṣe pe bi iná manamana ba ṣe dédé ounjẹ Yorùbá yio gbayi si, nítorí awọn òbì ma le se oriṣiriṣi ounjẹ pamọ
Ẹjọwọ ẹ maṣe jẹ ki a fi ounjẹ òkèrè dipo ounjẹ ilẹ wa, okùnfà gbèsè ni
ÌRÒYÌN ÌJÌ NLA JÀ NI ÌBÀDÀN
Òjò ati ìjì bẹrẹ ni arọkutu ọjọ ajé, ọjọ kejidinlogun oṣu keji ọdún ẹgbẹwa le mẹtala
Ìjì naa ba ílé ati ọna jẹ rẹpẹtẹ ni ìlú Ìbàdàn
Òwe Yorùbá sọ wipe Ogun àsọ tẹlẹ ki parọ to ba gbọn
O ṣeni lanu wipe ko si àsọ tẹl tabi ipalẹmọ fún ará ìlú ati ijọba
Iyalẹnu ni wipe lati ọpọ ọdun ti ìjì àti àgbàrá lati odò Ògùnpa ti mba ilé ati ọna jẹ lọdọdun, Ìjọba Ọyọ ko ti ri ogbọn kọ lati da ẹkun ati ibanujẹ ti iṣẹlẹ yi nda silẹ
A NGBA ÒRÒMỌDÌYẸ LỌWỌ IKÚ O NI WỌN O JẸ KI OHUN LỌ ATAN LỌJẸ
A le lo òwe yi lati kilọ fun ẹni to fẹ lọ si Òkè-òkun lọna kọna lai ni ase tabi iwe ìrìnà
Bi ẹbi, ọrẹ tabi ojúlùmọ to mọ ewu to wa ninu igbesẹ bẹ ba ngba irú ẹni bẹ niyanju, a ma binu wipe wọn o fẹ ki ohun ṣoriire
Bi ounjẹ ti pọ to l'atan fun oromọdiyẹ bẹni ewu pọ to
Bi ọna ati ṣoriire ti pọ to ni Òkè-òkun bẹni ewu ati ibanujẹ pọ to fun ẹniti koni aṣẹ ìrìnà
Ọpọlọpọ nku sọna, ọpọ si nde ọhun lai ri iṣẹ, lai ri ibi gbe tabi lai ribi pamọ si fun Òfin
Lati pada si ile a di isoro nítorí ọpọ ninu wọn ti ta ile ati gbogbo ohun ìní lati lọ oke okun
Bi iru ẹni bẹ ṣe npe si l'Òkè-òkun bẹni ìtìjú ati pada sile se npọ si
A le ka si ounjẹ osan
ỌJỌ GBOGBO NI TI OLÈ, ỌJỌ KAN NI TOLÓHUN
Ní ọjọ Ẹti ọjọ keji lelogun oṣu keji ọdún yi, Ẹrọ amóhùn máwòrán Iluọba tu asiri ọmọkùnrin kan ti o ni iwe ijẹri irina ọmọ Naijeria ni oruko ọtọtọ mẹta ti o fi nlu ìjọba ní jìbìtì gba iranlọwọ ti ko tọ si
O ti gba owó rẹpẹtẹ ki wọn to ri mu
Ni Ìlú Ọba Ìjọba pese ilé fún awọn abirùn ati aláìní ti o jẹ ọmọ onilu ati iranlọwọ miran lati mu ayé dẹrùn fún wọn
Àwọn àjòjì ti o fi èrú ati irọ gba àwọn iranlọwọ yi, wọn a dẹ tún fi ma yangan titi ọjọ ti olóhun yio fi muwọn
Irú iwa burúkú bi ka fi èrú gba ohun ti ko tọ wọnyi mba orúkọ jẹ
Ẹ jẹ ki a fi owé Yorùbá to wipe Ọjọ gbogbo ni tolè, ọjọ kan ni tolóhun se ikilo fun iru awọn oníjìbìtì bẹ ere jibiti, nítorí bi o ti wu ko pẹ to, ọjọ kan ọwọ òfin a ba iru àwọn bẹ
Nígbàtí wọn ba ri wọn mu, wọn a ko ìtìjú ba orúkọ idile ati ìlú wọn
Ìròyìn ikú Olóògbé Chinua Achebe, ògúnná gbongbo ninu Olukọwe ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú àti àgbáyé kàn ni ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kejì lélógún, oṣ̀u kẹta ọdún ẹgbẹ̀rún méjì le mẹ́tàlá
Ọmọ ọdún méjì le lọgọrin ni Olóògbé Chinua Achebe nígbà ti o pa ipòdà
Ìkan nínú ìwé ti Olóògbé Chinua Achebe kọ Nkan túká di kíkà fún àwọn ọmọ ilé-ìwé lati ilẹ̀ ènìà dúdú títí dé Òkè-òkun
Títí di àsìkò yi, ìwé na ngbayi si ni, nítorí wọn ti túmọ̀ ìwé yi sí èdè oriṣiriṣi
Àdánù nla ni ikú Olóògbé Chinua Achebe jẹ́ fún Naijeria, ìlú aláwọ dúdú àti gbogbo Olùkọ̀wé lagbaye
Olórí Òṣèlú Venezuela Hugo Chavez, pa ipò dà ní ọjọ́ ìṣẹ́gun ọjọ́ karun oṣù kẹta ọdún ẹgbẹ̀rún méjì lémẹ́tàlá
Nígbà ayé ologbe yi, ó fa àríyànjiyàn, bí ó ti fẹ́ràn àwọn ìlú kan bẹ lo korira àwọn ìlú míràn
Lati ìgbà tí ìròyìn ikú rẹ̀ ti kan, bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni gbogbo àgbáyé ti nsọfọ bẹni àwọn kan nfi àibìkítà han
Eleyi fihan wípé ohun tí ó kọju sí ẹnìkan ló kẹ̀hìn sí ẹlòmíran
Ìdábẹ́ jẹ ìkan nínú àṣà Yorùbá tí ólòdì si ẹ̀tọ́ àwọn obìnrin
Gẹ́gẹ́bí ìtàn ìdábẹ́, Yorùbá ndabẹ fún ob̀nrin ní àti ìkókó títí dé ọmọ ọdún kan, nwọn ní ìgbàgbọ́ wipe yio da ìṣekúṣe dúró lára obìnrin
Tiítí òde òní, àṣà Yorùbá ṣì nfi ìyàtọ̀ sí àárín obìnrin ati ọkùnrin, ní títọ́ àti ní àwùjọ
Gẹ́gẹ́bí Olókìkí Oló́rin Jùjú Ebenezer Obey ti kọ́ lórin Àwa ọkùnrin le láya mẹ́fà, kò burú, ọkùnrin kan ṣoṣo lọba Olúwa mi yàn fún obìnrin
Wọ́n ṣe àlàyé àlébù tí àṣà burúkú yi jẹ́ fún àwọn obìnrin tí wọ́n bá dábẹ́ fún, ara àlébù bi ọmọ lè kú ikú ẹ̀jẹ̀ dídà, ìṣòro tí irú ẹni bẹ bá fẹ tọ̀, ìsòro ní ìgbà ìbímọ àti bẹbẹ lọ
Ìjọba ti pèsè owó púpọ̀ lati fi òpin sí àṣà ìdábẹ́ ní Ìlú-Ọba
Bí a ti nṣe àjọ̀dún Ọjọ́ áwọn Obìnrin lagbaaye, oṣe pàtàkì kí Yorùbá ní ilé àti ní àjò, di àṣà tí ó bùkún àwọn ọmọ mú, kí a sì ju àṣà tí ó mú ìpalára dání dànù
Ẹ̀kọ́ áti àbójútó lati ọ̀dọ́ òbí ló lè dá ìṣekúṣe dúró, ki ṣe ìdábẹ́
Yorùbá nί Bί a bá ránni nί iṣẹ ẹrú, a fi tọmọ jẹ
Eleyi fi Ìwà ìkà ọmọ enia sί ọmọ enia han
Ọlọpa South Africa ṣi àṣẹ ti wọn nί lὸ, wọn rán wọn niṣe ẹrú, wọn o fi tọmọ jẹ
Bí a ti nṣe ní ilé wa, ewọ ibòmíì
A kì dàgbà jẹ Òjó
Òjó, Dàda, Àìná, Táíwò, Kẹhinde ati bebe lo je orúkọ amu tọrun wa
Pípa orúkọ Ilé-ìwé gíga ni Akoka, ilu Èkó da lẹhin aadọta ọdún dàbí ìgbà ti a sọ arúgbó lorukọ àmú tọrun wa
Apẹrẹ ẹni ti ki ṣe ibeji ko le pa orúkọ da si orúkọ àmú tọrun wa
A dupẹ lọwọ Olórí Ìlú Goodluck Jonathan to gbọ igbe awọn ènìyàn lati da orúkọ Ilé-ìwé Gíga ti o wa ni Akoko ti Ilu Èkó pada gẹgẹbi Olukọagba Jerry Gana, ti kọ si ìwé ìròyìn ni ọjọ Ẹti, oṣù keji ẹgbaa le mẹtala
ÒKÚ NSUKUN Ò̀KÚ, AKÁṢỌLÉRÍ NSUKUN ARA WỌN
Ọmọ ọdún mẹtadinladọrun ni nígbàtí ó dágbére fún ayé ni oṣù kẹrin ọjọ kẹjọ, ọdún ẹgbẹ̀rúnméjìlémẹ́tàlá
Yorùbá ni Òkú nsukun òkú, akáṣolérí nsukun ara wọn ìtumọ̀ èyí ni wípé kò sẹ́ni tí kò ní kú, olówó, aláìní, ọmọdé, arúgbó, Òṣèlú, Ọba àti Ìjòyè á kú tí àsìkò bá tó, nítorí náà, ẹni to sunkun, sunkun fún ara rẹ, ẹni tó mbinu, mbinu ara rẹ nítorí, ẹni tó kú ti lọ
Ojúọjọ́ dára, ètò ìsìnkú náà lọ dédé láìsí ìdíwọ́
Ìgbéyàwó ìbíle ní Ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ àsìkò ti ẹbí ọkọ àti ì̀yàwó ma nparapọ
A lè ṣe gbogbo ètò ìgb́eyàwó ìbílẹ̀ ni ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ púpọ̀ fún àpẹrẹ mọ̀mí-nmọ̀ẹ lọjọkan ati idana lọ́jọ́ keji tàbi ọjọ miran
Ní ayé àtijọ́, nígbàtí Yorùbá ma nṣe ayẹyẹ níwọ̀ntúnwọ̀sín, ilé ẹbí tàbi ọgbà bàbá àti ìyá ìyàwó ni wọn ti nṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó, ṣùgbọ́n láyé òde òní, àyè ọ̀tọ̀ bi ilé ìlú, pápá ìṣeré, ilé àlejò àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n nlo
Àṣà gbígba àyè ọ̀tọ tógbòde bẹ̀rẹ̀ nítorí àwọn adigun jalè àti àwọn ènìyàn burúkú míràn ti o ma ndarapọ pẹ̀lú àwọn àlejò tí a pè sí ibi ìyàwó lati ṣe iṣẹ́ ibi
Owó púpọ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ma nfi gba à̀yè ibi ṣíṣe ìyàwó
Bí òbí ba ti lọ́lá tó ni wọn ma náwó tó, nítorí ìdùnnú ni fún òbí pé a tọ́mọ, wọ́n gbẹ̀kọ́, wọn fẹ di òmìnira lati bẹ̀rẹ̀ ẹbí tíwọn, ṣùgbọ́n àṣejù ati àṣehàn ti wa wọ́pọ̀ jù
Nítorí ìnáwó ìgbéyàwó, ilé ayẹyẹ pọ̀ju ilé ìkàwé lọ láyé òde òní
Kí ṣe bi a ti náwó tó níbi ìgbéyàwó lo nmu àṣeyorí ba ọkọ àti ìyàwó, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ntuka láìpẹ́ lẹ́hin ariwo rẹpẹtẹ yi
Yorùbá ni A ki fọlá jẹ iyọ̀, nínú ìṣẹ layika ni ilẹ̀ Aláwọdúdú, ó yẹ ki a ṣe ayẹyẹ ìgbéyàwó níwọ̀ntúnwọ̀nsìn
Ẹ fojú sọ́nà fún ètò ìgbéyàwó ibilè
Àṣà àtọwọ́dọ́wọ́, ọwọ́ ni a fi njẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ Yorùbá, nítorí kò si ṣíbí tó dára tó ọwọ́ lati fi jẹ oúnjẹ òkèlè bi iyán, èyí jẹ kó ṣe pàtàkì lati fọ ọwọ́ mejeji lẹ́hìn oúnjẹ
Fífọ ọwọ́ kan kòlè mọ́ bi ka fọ ọwọ́ mejeji
Ọ̀rọ̀, ọ̀tún wẹ òsì, òsì wẹ ọ̀tún, lọwọ́ fi nmọ wúlò lati gba àwọn ènìà níyànjú wípé àgbájọwọ́ láàarín ẹbí, ọ̀rẹ́ àti ará ìlú lérè
Yorùbá ni Àgbájọ ọwọ́ la fi nsọya, ajẹjẹ ọwọ́ kan ko gbe ẹrú dórí, ọmọ Yorùbá nílélóko, ẹ jẹ́kí a parapọ̀ tún ílú ṣe
Òkìkí ikú Ìyáàfin Margaret Thatcher, obìnrin àkọ́kọ́ lati dé ipò Olórí Òṣel̀ú Ìlúọba kàn ní oṣù kẹrin, ọjọ́ kẹjọ, ọdún ẹgbẹ̀rúnméjìlémẹ́tàlá
Orin yi ba ìgbà ayé Olóògbé Ìyáàfin Margaret Thatcher mu
Gẹ́gẹ́bí Obìnrin àkọ́kọ́ tó di Olórí Òṣèlú Ìlúọba, ó ṣe ìwọ̀n tó lèṣe nítorí ìfẹ́ tí ó ní sí ìlù rẹ̀
Ọ̀rọ̀ tó wọ́pọ̀ ni Lẹ́hìn ọkùnrin tó ṣorire, obìnrin wa nbe, ṣùgbọ́n wíwo ìgbésí ayé àwọn og̀bójú obìnrin bi Olóògbé Fúrnmiláyọ̀ Ransome Kútì àti Olóògbé Margaret Thatcher fihàn wípé lẹ́hìn obìnrin tó bá́ ṣe orire, ọkùnrin wa nbẹ, ọkọ wọn dúró tìwọn gbọingbọin, èyí fi ọkàn àwọn aṣájú nínú àwọn obìnrin àgbáyé yi balẹ̀ lati tọ́jú àwọn ọmọ pẹ̀lú iṣẹ́ Òṣèlú tí obìnrin kò wọ́pọ̀ lásìkò tiwọn
Sùn re o, Ìyáàfin Thatcher
Yorùbá ní Bí ewé bá pẹ́ lára ọṣẹ, á dọṣẹ,ọ̀rọ̀ yí bá ẹgbẹ́ Yorùbá ni Ìlúọba mu pàtàkì àwọn ti o ngbe ni Olú Ìlúọba
Títí di bi ọgbọ̀n ọdún sẹhin, àti rí oúnjẹ Yorùbá rà ṣọ̀wọ́n
Ní àpẹrẹ, àti ri adìẹ tó gbó rà lásìkò yi, à fi tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá lọ si òpópó Liverpool, ṣùgbọ́n ní ayé òde òni, kòsí agbègbè ti ènìà kò ti lè rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ Yorùbá ra
Lati bi ogún ọdún sẹ́hin, Yorùbá ti pọ̀si nidi àtẹ oúnjẹ títà ni Olú Ìlúọba
Àwòrán àwọn ọjà wọnyi a bẹrẹ pẹ̀lú, Ọja Dalston àti Kingsland
Ẹ fojú sọ́nà fún àwọn ọja yókù
Ọ̀rọ̀ Yorùbá yi ba ìjọba Ìlúọba àti àwọn ará ìlú wi
Ìjọba njaya nítorí owó ti o nwọle kò kárí owó lati ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀tọ́ ti àwọn ará ìlú nri gbà
Àwọn ti o si ngba ẹ̀tọ́ lọ́dọ̀ ìjọba njaya nítorí, ẹ̀tọ́ ti Ìjọba ndiku yio mu ìnira bá wọn nítorí ẹ̀dín owó yi bọ́sí àsìkò ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ àti ohun ìtura míràn
Díẹ̀ nínú àwọn àtúnṣe yi ni ìdérí owó ìrànlọ́wọ́ si poun mẹrindinlọgbọn lọ́dún fún ìdílé, yíyọ owó fún yàrá tó ṣófo, àtúnṣe fún Ilé Ìwòsàn lapapọ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Yorùbá ni Kòsọ́gbọ́n tí o lèda, kòsíwà tí o lèhù tí o lè fi tẹ ayé lórùn, bí ọ̀pọ̀ ti nyin ìjọba bẹ́ẹ̀ni ọ̀pọ̀ mbu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu àtúnṣe wọnyi wípé Ìjọba ngba lọ́wọ́ aláìní fún àwọn tóní
Yorùbá ní Ẹnití Ọlọrun kò dùn nínú, tó nla ṣúgà, jẹ̀díjẹdí ló ma pá
Ọ̀rọ̀ Yorùbá yi ṣ̀e àtìlẹhìn fún iwadi tó fihàn wípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ìrẹ̀wẹ̀sì mbaja ma mu ọtí àti jẹ oúnje ọlọra, ti iyọja tàbí tí iyọ̀ ìrèké pọ̀ nínú rẹ
Oúnje dídùn àti ọtí mímu kò lè mú ìrẹ̀wẹ̀sì kúrò tàbí fa ìdùnnú, ṣùgbọ́n àyípadà ọkàn sí ìwà rere àti ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọrun ló lè mú inú dùn
Ẹkú ọdún Ajinde o, ẹ ma jẹ́un ju, Jésù ku fun ẹlẹ́sẹ̀ àti aláìní, nítorí náà ti ẹ ba ri jẹ, ẹ rántí áwọn ti ko ri
Yorùbá ni ajọjẹ kò dùn bẹni kan o ri
Nínú ìwé ìròyìn Vanguard, ti ọjọ́ Àìkú, oṣù kẹta, ọjọ́ , ọdún kẹrinlélógún, Ẹgbaalémétàlá, Olùkọ́ àgbà ti Èdè ati Àṣà, Akínwùnmí Ìṣọ̀lá, kébòsí wípé èdè Yorùbá àti èdè abínibí miran le parun ti a ko bá kíyèsára
Ìkìlọ̀ yí ṣe ìrànlọ́wọ́ fún akitiyan Olùkọ̀wé yi lati gbé èdè àti Yorùbá ga lórí ẹ̀rọ Ayélujára
Àwọn Òṣèlú tó yẹ ki wọn gbé èdè ìlú wọn lárugẹ n dá kún pí pa èdè rẹ
Òṣèlú ilẹ̀ Yorùbá ko fi èdè na ṣe nkankan ni Ilé-òsèlú, wọn o sọ́, wọn ò kọ́, wọn ò ká
Àwọn Òṣèlú ayé àtijọ́ bi Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólówọ̀, Olóyè Ládòkè Akíntọlá, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ gbé èdè wọn lárugẹ bi ó ti ẹ̀ jẹ́ wípé wọn kàwé wọn gboyè rẹpẹtẹ
Yorùbá ní Àgbà kì í wà lọ́jà kórí ọmọ tuntun wọ́
Ó yẹ ki àwọn àgbà kọ́ ọmọ lédè, kí à si gba àwọn ọmọ wa níyànjú wípé sí sọ èdè abínibí kò dá ìwè kíkà dúró ó fi kún ìmọ̀ ni
Yorùbá ní Ẹ̀bẹ̀ la mbẹ òṣìkà pé kí ó tú ìlú rẹ ṣe, A bẹ àwọn Òṣèlú́ Ilẹ̀ Yorùbá ni agbègbè Èkìtì, Èkó, Ògùn, Ondó, Ọ̀ṣun àti Ọ̀̀yọ́, lati ṣe òfin mí mú Kíkọ àti Kíkà èdè Yorùbá múlẹ̀ ní gbogbo ilé ìwé, ní pàtàkì ní ilé-ìwé alakọbẹrẹ ilẹ̀ Yorùbá nítorí ki èdè Yorùbá ma ba a parẹ́
Ewédú jẹ ikan nínú ọbẹ̀ Yorùbá tó wọpọ ni agbègbè Ọ̀yó, Ọ̀sun, Ògùn gẹ́gẹ́bi ilá ti wọ́pọ̀ ni agbègbè Ondo àti Èkìti
Fún ẹni tó́ nkanju, ilá yára láti sè ju ewédú lọ, nítorí àsìkò lati tọ́ ewédú ati lati fi ìjábẹ̀ ja, pẹ ju rírẹ àti síse ilá lọ
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ko ríra pe wọn nfi ìgbálẹ se ọbẹ̀ lai mọ wípé ìjábẹ̀ kò wà fún ilẹ̀ gbígbá
ọwọ̀ kukuru tuntun ti o wa fún ewédú
Ni ayé ìgbàlódé yi, dípò ìjábẹ̀, a le lọ ewédú nínú ẹ̀rọ ata ìgbàlode fún bi iṣeju kan, eleyi din àsìkò síse ewédú kù si bi ọgbọn ìṣéjú fún ewédú ọbẹ̀ enia mẹwa
Ewédú̀ dùn pẹ̀lú gbẹ̀gìrì tàbi ọbẹ̀ ata lati fi jẹ Ẹ̀kọ, Àmàlà, Láfún àti ounjẹ òkèlè yókù bi Ẹ̀bà, Iyán àti bẹẹbẹ lọ
Lẹhin ọdún mẹwa, ìdájọ bẹrẹ fún gbọmọgbọmọ to ji àwọn obinrin mẹta pamọ́ Nígbàtí ọwọ òfin tẹ Ariel Castro, gbogbo agbára to fi njẹ àwọn obinrin wọnyi niya di òfo
Ariel Castro nṣe ojú aanu bi ẹni pé ki ṣe ohun lo ṣe iṣẹ́ ibi fún ọdún mẹwa o le díẹ̀
Àdúrà Yorùbá́ ni Ki Oluwa gbani lọ́wọ́ ẹni tó nṣọni, ti a ko ṣọ, àdúrà yi gbà fún àwọn obinrin mẹta ti gbọmọgbọmọ ti jígbé lati bi ọdún mẹwa sẹhin
Ìkan nínú àwọn ọmọ obinrin yi bí ọmọ ti o ti pe ọdún mẹfa sínú àtìmọle yi
Ìbànújẹ́ tí kò lafi we ni ki ọmọ sọnu
Gẹgẹbi ọrọ Yorùbá Ọmọ́kú san ju ọmọ sọnu lọ pàtàkì lára ìyá ọmọ, ìrònú ọmọ sọnu pa ìya ikan nínú àwọn obinrin mẹta yi, o ṣeni laanu wípé kò rí ọjọ́ ayọ̀ ìtúsílẹ̀ nínú ìdè tí Ariel Castro fi àwọn obinrin yi si
Ìyanu ni wípé wọn jade laaye, nítorí ọpọlọpọ lo nsọnu ti wọn ki ri òkú tàbí aaye wọn
Ìròyìn pé àwọn Ọlọpa tú àwọn obinrin mẹta yi silẹ lati ilé ẹni tó gbé wọn dè jade ni ọjọ Ajé, oṣù karun, ọjọ́ kẹfa, ọdún ẹgbẹ̀rúnméjìlemẹtala
Òwe Yorùbá yi wúlò lati juwe òye àgbàlagbà lati wo ẹ̀hìn fún ẹ̀kọ́ nínú ìrírí tó ti kọjá lati yanjú ọ̀ràn tó ṣòro nígbàtí ọmọdé tí kò rí irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ lati kọ́ ọgbọ́n, má nwo iwájú
Ọ̀rọ̀ Yorùbá miran ni Ẹni tó jìn sí kòtò, kọ ará yókù lọ́gbọ́n
Nitotọ ọ̀rọ̀ miran sọ wípé Ìṣòro ni Olùkọ́ tó dára jù, ṣùgbọ́n dí dúró kí ìṣòro jẹ Olukọ fún ni lè fa ewu iyebíye, nítorí náà ó dára ká kọ́ ọgbọ́n lati ọ̀dọ̀ àgbà
Ọlọ́gbọ́n ma nlo ọgbọ́n ọlọ́gbọ́n lati yẹra fún ìṣubú
Ní àsìkò ẹ̀rọ ayélujára yi, òwe Bí ọmọdé bá ṣubú á wo iwájú, bí àgbà bá ṣubú á wo ẹ̀hìn ṣi wúlò fún àwọn ọmọdé tí ó lè ṣe àṣàyàn lati fi etí si àgbà, kọ́ ẹ̀kọ́, tàbí ka àkọsílẹ̀ ìrírí àgbà nínú ìwé tàbí lórí ayélujára lati yẹra fún àṣìṣe, kọ́ ibi tí agbára àti àilera àgbà wà fún lílò lọ́jọ́ iwájú
Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ wípé ọwọ́ ọmọde ko to pẹpẹ, tagbalagba ko wọ̀ kèrègbè, èyí tí a lè túmọ̀ sí wípé, ọmọdé kò ga to pẹpẹ láti mú nkan tí wọn gbé si orí pẹpẹ, bẹni ọwọ́ àgbàlagbà ti tóbi jù lati wọ inú akèrègbè lati mu nkan, nítorí náà àgbà̀ lèlo ìrànlọ́wọ́ ọmọdé
Ní ayé, oníkálukú ló ní ohun tí wọ́n lè ṣe
Àwọn nkan wa ti àgbàlagbà lè ṣe bẹ́ẹ̀ni ọpọlọpọ nkan wa ti ọmọdé lè ṣe
Láyé òde òní, ọmọdé le gbójúlé àgbàlagbà, ṣùgbọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àgbàlagbà gbójúlé ọmọdé láti kọ́ lílò ẹ̀rọ ayélujára
Ò̀we yi fi èrè ifọwọsowọpọ laarin ọmọdé àti àgbà han nítorí kò sẹ́ni tí kò wúlò
Ọmọ ìyá méjì ki réwèlè, Yorùbá ma nlo ọ̀rọ̀ yi nígbàtí ọmọ ìyá méjì ba ko àgbákó tó la ikú lọ
Irú ìsẹ̀lẹ̀ tó kó ìpayà ba gbogbo ènìà bayi ki ṣe ijamba lásán ṣù́gbọ́n àwọn ìyá méjì Tsarnev, ni wọn tọ́ka si fún iṣẹ́ ibi tó ṣẹlẹ̀ ni oṣù kẹrin ọjọ kẹdogun nibi ere ọlọnajijin tí wọn sá ni Boston
Kikọ ọmọ lati ṣe Ọmọlúàbí jẹ́ ohun ti àwọn òbí ayé àtijọ́ ndù ju ọ̀pọ̀lọpọ̀ òbí ayé òde òní tó ndu owó lati kó ọrọ̀ jọ ju wípé ká kọ́ ọmọ lọ
Kíka ọrọ ìfojúkojú nínú ìwé ìròyìn fihàn wípé ẹ̀kọ́ ti ìyá àti bàbá bá kọ́ ọmọ ni kékeré wúlò fún ẹbí àti ará lọ́jọ́ iwájú
Ẹkọ ti Gómìnà Fáṣọlá gbà lọ́wọ́ òbí wúlò fún ẹbí, ará àti ìlú Èkó
Bí orí bá pẹ́ nílẹ̀ á dire, bi o tiẹ jẹ wípé Gómìnà Fáṣọlá kò fẹ́ ṣe iṣẹ́ Òṣèlú, orí darí rẹ síbẹ̀
Òwe Yorùbá ni Orí olókìkí kò jẹ́ asán, wọ́n nkigbe ẹ nílé, wọ́n nkigbe ẹ́ logùn, nitòótọ Gómìnà Fáṣọlá gbìyànjú fún ìlú Èkó, ṣùgbọ́n omi pọ̀ ju ọkà lọ
Góm̀nà, ẹ kú orire adọọta ọjọ́ ìbí, orire naa dalẹ́, ẹ̀mí ọlá á gùn lati ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ ìbí láyé o. Àṣẹ
Èkó ò ní bàjẹ́ o!
Ni ọjọ Ẹti, oṣù kẹfa ọjọ keje, ọdún ẹgbẹrunméjìlemẹtala, Adájọ́ ṣe ìdájọ ẹ̀wọ̀n gbére fún Ọpẹmipọ Jaji, ọmọ ọdún méjìdínlógún fún dídó fàdíya
Laipẹ yi, Michael Adébọ́lájọ ati Michael Adébọ̀wálé wá si Iléẹjọ́ fún ẹ̀sùn apànìyàn
Ìròyìn burúkú yi ko ti lọ lẹ̀, nígbàtí ìròyìn ìdájọ ẹ̀wọ̀n gbére fún Ọpẹmipọ Jaji tún jade
Kíló nṣẹlẹ Yorùbá ni àgbà kì wá lọ́jà ki orí ọmọ tuntun wọ́
Àsìkoì tó ki àgbàgbà Yorùbá ni Ìlúọba parapọ̀ lati ṣe iwadi ohun tó fa àwọn ọmọ tíwọ́n bẹ̀rẹ̀ si hùwà burúkú wọnyi láàarín àwon ọ̀dọ́
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Yorùbá ló nṣe dáradára ní ilé àti àjò tí a kò gbọ́ ìròyìn wọn
Yorùbá ni Ẹni jalè ló bọmọ jẹ, ìròyìn iṣẹ́ rere ki tàn bi irú ìròyìn iṣẹ ibi ti Michael Adébọ́lájọ àti Michael Adé́bọ̀wálé tó kárí ayé
Ó yẹ ki Ìjọba àti gbogbo Yorùbá pa ẹnu pọ lati bá oníṣẹ ibi wi nítorí gẹ́gẹ́bí òwe Yorùbá Ẹrú kan ló́ mú ni bu igba ẹrú
Àṣà ilẹ̀ Yorùbá títí di àsìkò yi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin ma nni ìyàwó púpọ́ wọn si ma mbi ọmọ púpọ̀, wíwọ irú aṣọ kan naa fun ṣíṣe ma nfi ẹbi han
Aṣọ ẹbí bẹ̀rẹ̀ nípa ki ọkọ àti ìyàwó dá irú aṣọ kan nigba ìgbéyàwó àti wíwọ irú aṣọ kan naa lẹhin ìgbéyàwó lati fi han wípé wọn ti di ara kan
Bàbá ma nra aṣọ irú kan naa fun àwọn ọmọ nítorí ó dín ìnáwó kù láti ra irú aṣọ kan naa fún ọmọ púpọ̀ nípa ríra ìgàn aṣọ ju ríra ni ọ̀pá
Aṣọ ẹbí tún wa fún ẹbí àti ọmọ oloku, ìyàwó ṣíṣe, ẹgbẹ́ ìlú àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Nígbàtí wèrè ko ti wọ àṣà aṣọ ẹbí, ẹnití o ṣe ìyàwó, ṣe òkú, sọ ọmọ lórúkọ àti ṣiṣe yoku ma npe aṣọ ni
Kò kan dandan ki ènìá ra aṣọ tuntun fún gbogbo ṣíṣe, fún àpẹrẹ, aṣọ funfun ni wọn ma sọ wípé ki àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ wọ̀ fún òkú ṣíṣe, aṣọ ibilẹ̀ bi aṣọ òfi àti àdìrẹ fún ìgbéyàwó
Ẹbí ìyàwó le sọ wípé ki ẹgbẹ́ wọ aṣọ aláwọ ewé lati ba ohun yọ ayọ ìgbéyàwó, ki ẹbí ọkọ ni ki àwọn ẹgbẹ́ wọ àdìrẹ ti wọn ti ra tẹ́lẹ̀ fún ìgbéyàwó
Lati bi ogoji ọdun sẹhin, lẹhin ti ìlú ti bẹ̀rẹ̀ si naa owó epo, àṣejù ti wọ àṣà aṣọ ẹbí rírà
Àṣà aṣọ ẹbí ti káári ìlú kọjá ile Yorùbá si gbogbo Nàíjíríà
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ a ma jẹ gbèsè nítorí àti ra aṣọ ẹbí, pàtàkì ni Ìlúọba ti àwọn miran ti nṣiṣẹ àṣekú lati kó irú owó bẹẹ si aṣọ ẹbí, àwọn miran á kó owó oúnjẹ àti owó ilé ìwé lórí aṣọ ẹbí
Ìlú ńbàjẹ si, kò síná, kò sómi, ìṣẹ́ pọ, aṣọ ẹbí ko le mu ìṣẹ́ kúrò tàbi sọ ẹnití o jẹ gbèsè láti ra aṣọ ẹbí di ènìyàn nla nítorí Aṣọ nla, kọ lènìyàn nla – Yorùbá ni ilé lóko, ẹ dín wèrè aṣọ ẹbí kù
Ọ̀rọ̀ Yorùbá ní Ẹni tó Lórí kò ní Fìlà, Ẹni tó ní Fìlà kò Lórí
Tani eni Ẹni tó Lórí ti kò ní Fila
Enití gbogbo àyè wà fún lati ṣe nkan nla bi ka kọ́ ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ lati pèsè àyè à́ti ohun améyédẹrùn fún ìlú àti ará ìlú tí kò ló àyè yi
Tani Ẹni tí ó ni Fìlà tí kò Lórí
Eni tí ìlú tàbí òbí ti pèsè àyè àti gbogbo ohun améyédẹrùn fún láti lè kọ́ ẹ̀kọ́ ìjìnlẹ̀ ṣùgbọ́n tó kọ̀ láti kọ ẹ̀kọ́ tàbi kó kọ́ iṣẹ́ ọwọ
Kò sí ẹni tó le ni fìlà lai lórí, nítorí Ọlọrun dá Orí fún gbogbo ẹ̀dá alàyè, ṣùgbọ́n ènìà lè̀ lóri, kó má ni fìlà tí ó jẹ́ àtọwọ́dá ọmọ ènìà
Nítorí ìdí èyi, Ẹni tó lórí yẹ kó ní Fìlà, nípa lí lo orí lati pèsè àyè àti ohun amáyéderùn
Fún àpẹrẹ, ai lo orí lati pèse ohun améyédẹrùn ló fa sún kẹrẹ fà kẹrẹ ọkọ̀ ni ìlú Èkó nítorí bi Èkó bá lo ọkọ ojú omi, ọkọ̀ Ojúirin pẹ̀lú ọkọ̀ Orí ilẹ̀ lati kó ènìà àti ẹru lati ibìkan dé ibìkejì, sún kẹrẹ fà kẹrẹ ọkọ̀ á dín kù gidigidi àti wípé a dín ìyà àti àsìkò ti àwọn èrò nlo lójú ọ̀nà lójojúmọ́ kù
Ẹfi ojú sọ́na lọ́sọ̀sẹ̀ fún kíkọ nípa àwọn nkan wọnyi lédè Yorùbá àti ìtum̀ọ lédè Gẹ̀ẹ́sì Ìmúlò Òwe, Kíkọ Èdè, Ìtàn àti Ìròyìn tí a lè fi kọ́gbọ́n, Ẹgbẹ́ àti Oúnjẹ Yorùbá ni ìlú London, New York, Chicago, Orlando àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Ẹ bá wa sowọ́pọ̀ láti ri pé èdè wa kò kú nípa kíkọ àti kíkà èdè Yorùbá lórí ẹ̀rọ ayélujára
Ẹ ṣé púpọ̀, ilé àti èdè Yorùbà kò ní parun o lágbára Èdùmàrè. Àṣẹ
Òwe Yorù̀bá ni Ire kì í dé ká má gbọ́ ohun gudugudu, igbe ayọ̀ ti o ti jáde ni gbogbo àgbáyé kọjá gudugudu lati àná
Àwọn Ológun ti yin ọ̀kànlélógún sókè lati ki ọmọ titun káàbọ̀ si ayé
A kí bàbá àti ìyá ọmọ àti gbogbo ẹbí pé wọ́n kú orí-ire
Orúkọ ẹ̀yà ara ṣe pàtàkì lati mọ nípa kíkọ́ èdè nítorí ó ma nwà nínú ọ̀rọ̀
Mí mọ awọn orúkọ wọnyi á́ tún jẹ ki èdè Yorùbá yé àwọn ti ó ni ìfẹ́ lati kọ èdè
A lérò wípé àwòrán àti pípè tí ó wà ni abala àwọn ojú ìwé wọnyi yio wúlò
Ọ̀mùtí gbàgbé ìṣẹ́ fún ìgbaì diẹ ni, nítorí bí ọ̀mùtí bá jí tán, ìṣẹ́ rẹ kò tán
Bí Ìjọba, ẹbí àti ará ti ṣe ìkìlọ̀ tó nípa ọtí àmunpara, bi o ti ngba etí ọ̀tun wọlé lo ngba ti òsì jade fún àwọn ti ọ̀tí ba ti wọ lẹ́wù̀
Ìrònú pẹ̀lú nkan ti ó nfa ọtí àmun jù ṣùgbọ́n ọ̀tí kò lè pa ìrònú rẹ àfi ki ó dá kun, nítorí bi ọtí bá dá lójú ọ̀mùtí, ìrònú á padà
Ohun gbogbo níwọ̀ntúnwọ̀nsìn, ọtí àmunpara kò yẹ ọmọ ènìà
Ẹ bá wa gbé ọ̀rọ̀ yi yẹ̀wò
Àwọn Ilé Ìdájọ́ Àgbà ni ìlú Amerika ṣe ìdájọ wípé ìgbéyàwó ko di dandan kó jẹ́ laarin ọkùnrin àti obinrin
Bi wọn ti s'alaiye oro na si, wọn ni kò dára ki àwọn Aṣòfin ti a mọ si Congress, sọ wípé ìgbéyàwó lati jẹ́ laarin ọkùnrin àti obìnrin ni kan ṣoṣo
Àkíyèsí ti wọn ṣe ni wípé, ìdí ti àwọn Aṣòfin ṣe sọ bẹ́ẹ̀, ni pé wọn o fẹ́ràn àwọn ti o nṣe ìgbéyàwó ọkùnrin si ọkùnrin tabi obìnrin si obìnrin
Ẹ jẹ́ ki a yẹ ọ̀rọ̀ yi wo bó yá a fẹ́ràn ẹ, tàbi a o fẹ́ràn ẹ, ṣe àṣà àdáyébá Yorùbá kankan wa, bi òwe tàbí nkan bẹ́ẹ̀, ti ó sọ ìdí ti a ṣe n fun àwọn ti ó bá ṣe ìgbéyàwó ni ọpọlọpọ ẹ̀tọ́ ti a n fun wọn
Ẹ jọ̀wọ́, ẹyin ará Yorùbá blog, ẹ bá wa da si
Ẹ sọ ìdí ti aṣe n fun àwọn ti ó bá ṣe ìgbéyàwó ni oriṣiriṣi ẹ̀tọ́, ẹ̀bùn lọ́jọ́, ìgbéyàwó àti àyẹ́sí fún àwọn tó bá wà ni ilé ọkọ
Ìdájọ́ yi ṣe pàtàkì, bi o ti ẹ jẹ wípé Amerika lo yi òfin padà pe ìgbéyàwó ki ṣe laarin ọkùnrin àti obìnrin mọ́ lọ́jọ́ òní, ni ọjọ́ kan, Yorùbá, orílẹ̀ èdè Nàíjíríà àti gbogbo ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú yio ṣe ipinu ọ̀rọ̀ yi
Àìní ìtẹ́lọ́rùn ló bí gbogbo ìwà burúkú bi irọ́ pípa, olè jíjà, àgbèrè, ojúkòkòrò àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Òṣèlú̀ ilẹ̀ Nàíjíríà á fi ọ̀nà ẹ̀rú wá ipò nítorí àti kó owó ìlú jẹ, wọn ki wúlò fún ìlú ṣùgbọ́n fún ara wọn
Il̀ú á dára si ti àwọn ènia bá lè mú òwe Yorùbá tí ó wípé Ìtẹ́lọ́rùn ni Baba Ìwà yí lò
lẹhin ọdún mẹrindinlọgbọn wa rí fún ìṣekúṣe si àwọn obìnrin kékèké fún ogún ọdún ó lé
Ìwà burúkú kò mọ àgbà tàbí àwọ̀, nítorí náà, o yẹ́ ka kíyèsára pàtàkì àwọn òbí
Yorùbá ni wọ́n mú olè lẹkan ó ni òhun ò wá rí, tani fi ọ̀nà han olè
Nígbàtí wọn kọ́kọ́ fi ẹ̀sùn ẹṣẹ yi kan Stuart Hall, ó ni kò si nkan tó jọ bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n pẹ̀lú àtilẹhin ò̀fin fún àwọn ọmọ obìnrin mẹtala yi pé kò si ẹni tó kọjá òfin, ó jẹ́wọ́ ni ilé-ẹjọ́
Ajá àwọn obìnrin mẹtala yi lẹ́ni lẹhin nítorí lai si Ìjọba, Ọlọpa àti àwọn Amòfin lẹhin wọn, kò si bi wọ́n ti lè dojú kọ Stuart Hall fún ẹ̀ṣẹ̀ ti o ti kọjá fún ọdún mẹrindinlọgbọn sẹhin
Ajá wọn ti pa ọ̀bọ, nítorí Adájọ ti sọ Stuart Hall si ẹ̀wọ̀n oṣù mẹdogún
Ni abúlé Yorùbá nígbàtí ko ti si ẹ̀rọ asọ̀rọ̀-mágbèsì tabi ẹ̀rọ amú-òhùn-máwòrán àti ẹ̀rọ ayélujára, àwọn ọmọdé má nkó ara jọ lati ṣe eré lẹhin iṣẹ́ oojọ Bàbá àti Ìyá wọn
pàtàkì, ni igba ọ̀gbẹlẹ̀ nígbàtí iṣẹ́ oko din kù
Àwọn ọmọdé kunrin mẹta bẹ̀rẹ̀ si ṣe eré ìdárayá leti òkun lai bikità ohun ti ó nlọ ni àyíká
Ọmọ kini lérí pé ohun lè gun igi ọ̀pẹ pẹ̀lu ọwọ́ lásá̀n, ekeji ni ohun lè wẹ òkun yi já, ẹni kẹta ni ohun lè ta ọfà si ọ̀run
Àjàpá gbọ́ gbogbo ìlérí àwọn mẹta yi ṣe, ó gbé ìròyìn lọ fún Ọba, pé ohun ti ri àwọn ti ó lè ṣe nkan ti ẹni kan kò ṣerí
Ọba àti àgbà ìlú kò fẹ́ gba ohun ti Àjàpá wi gbọ́ nítorí ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n o ni ki Ọba ṣe ohun ti ó bá fẹ́ fún ohun ti ìròyìn ti ohun mú wá kò bá ṣẹ
Ọba ránṣẹ́ pé àwọn ọmọdé kunrin mẹta yi, pé ki wọn wa ṣe ohun ti wọn ṣèlérí pé wọn lè ṣe
Yorùbá ni Ẹnu àìmẹ́nu, ètè àìmétè, ló́ nmú ọ̀ràn bá ẹ̀rẹ̀kẹ́
Ìbẹ̀rù ba àwọn ọmọ yi, ẹbí wọn bẹ Ọba pe eré ọmọdé lásán ni àwọn ọmọ yi fi sọ gbogbo ohun ti wọn sọ, ṣùgbọ́n ẹ̀pa ò bóró mọ́ gbogbo ará ìlú ti pé jọ lati wòran
Àwọn ọmọde mẹta yi bẹ̀rẹ̀ si kọ orin arò bayi
Èyi ti ó ni ohun lè gun ọ̀pẹ, dé ìdí ọ̀pẹ pẹ̀lú ẹkún
Ariwo sọ, inú ará ìlú dùn
Nígbàtí ọmọdé keji ti o ni ohun lè wẹ́ òkun ja, gbọ́ ariwo ìdùn nú yi, eleyi ki láyà
Bi ti ẹni àkọ́kọ́, ọmọdé keji ti ó ni ohun lè wẹ òkun já, o wẹ dé odi keji, nibiti wọn ti fi ijó àti ayọ̀ pàdé rẹ
Eleyi ló fún ọmọdé kẹta ni ìgboiyà pe ohun na lè ṣe ohun ti ohun ti ṣe ìlérí rẹ
Ni igbà kẹta ọfà na lọ sókè ọ̀run lai padà
Ariwo sọ, ṣùgbọ́n ìtìjú bo Àjàpá
Ìwà àti ìṣe ọ̀dọ́ ìgbàlódé, kò fi àṣà àti èdè Yorùbá hàn rárá
Aṣọ àlòkù ti gbòde, dipò aṣọ ìbílẹ̀
Ọpọlọpọ aṣọ àgbàwọ̀ yi kò wà fún ara àti lilò ni ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú
Ọ̀dọ́ miran a wọ asọ àti bàtà òtútù ninu ooru
Ọ̀pọ̀ Olùṣọ́-àgùntàn àti Oníhìnrere, ki wọ́ aṣọ ìbílẹ̀, wọn a di bi ìrẹ̀ pẹ̀lú aṣọ òtútù
Èdè ẹnu wọn kò jọ òyìnbó, kò jọ Yorùbá nítorí àti fi ipá sọ èdè Gẹẹsi
Òwe Yorùbá ti ó ni Ṣòkòtò àgbàwọ̀, bi kò ṣoni lẹsẹ á fúnni nítan
Bi a bá wo òwe yi, àti tun ṣòkòtò àgbàwọ̀ ṣe lati báni mu, ni ìnáwó púpọ̀ tàbi ki ó má yẹni
Bi a bá fi òwe yi ṣe akiyesi, aṣọ àlòkù ti wọn kó wọ̀ ìlú npa ọrọ̀ ilẹ̀ wa
Àwọn ti ó rán-aṣọ àti àwọn ti ó hun aṣọ ìbílẹ̀, ko ri iṣẹ́ ṣe tó nítorí aṣọ àlòkù ti àwọn ọdọ kó owó lé
A lè fi òwe yi bá àwọn ti ó nwọ aṣọ-alaṣọ àti àwọn ti ó fẹ́ gbàgbé èdè wọn nítorí èdè Gẹẹsi wi
Òwe yi tún bá àwọn Òṣèlú ti ó nlo àṣà Òṣè́lú ti òkè-òkun lai wo bi wọn ti lè tunṣe lati bá ìlú wọn mu
Atunse aṣọ àlòku ju àti rán aṣọ ni titun lọ
Ki Òṣèlú bá àwọn ará ìlú jíròrò lati ṣe òfin àti àṣà àti dari ìlú, dára ju pé ki á gba àṣà aláṣà lọ
Gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó ni Iṣẹ́ ni oogun ìṣẹ́, jẹ́ òtítọ́, bi òṣìṣẹ́ bá ri owó gbà ni àsìkò, tàbi gba ojú owó fún iṣẹ́ ti wọn ṣe
Òṣìṣẹ́ ti ó ṣiṣẹ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò lórí owó kékeré, kò lè bọ́ ninu ìṣẹ́, nítorí, ọlọ́rọ̀ kò ni ìtìjú lati jẹ òógùn Òṣìṣẹ́
Ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́, a fi ìtìjú gé ara wọn kúrú nípa àti bèrè ẹ̀tọ́ wọn
Òṣìṣẹ́ míràn a ṣe iṣẹ́ ọ̀fẹ́ fún ọlọ́rọ̀ tàbi ki wọn fúnra wọn gé owó ise wọn kúru lati ri ojú rere ọlọ́rọ̀, nípa èyi, wọn á pa owó fún ọlọ́rọ̀ ni ìparí ọdún
Ọ̀rọ̀ Yorùbá ti o ni Ọ̀dájú ló bi owó, ìtìjú ló bi igbèsè ṣe ló lati ba oloro tàbi o ni ilé-iṣẹ́ ti á lo gbobo ọ̀nà lati ma gba Ẹgbẹ́-òṣìṣẹ́ láyè
Ọlọ́rọ̀ kò ni ìtìjú lati lo òṣìṣẹ́ fún owó kékeré
A lè lo ọ̀rọ̀ yi lati gba Òṣìṣẹ́ ni ìyànjú ki wọn má tara wọn ni ọ̀pọ̀, nípa bi bèrè owó ti ó yẹ fún iṣẹ́ ti wọn ṣe àti pé ki òṣìṣẹ́ gbìyànju lati kọ iṣẹ́ mọ́ iṣẹ́ lati wà ni ipò àti bèrè ojú owó
Ọ̀pọ̀ ẹranko ti ó ni ìwo lóri, ma nlo lati fi gbèjà ara wọ́n ti ewu bá dojú kọ wọ́n
Ni ìdà , ìwo igbin wà fún lati fura ninú ewu, nítorí náà, bi igbin bá rò pé ewu wa ni àyíká́, igbin àti ìwo rẹ̀, a kó wọ karaun fún àbò
Fún ẹranko àti igbin, ìwo ti ó le ẹranko àti ìwo rírọ̀ igbin wà fún iṣẹ́ kan naa, mejeeji wà fún àbò ṣùgbọ́n fún iwúlò ọ̀tọ̀tọ̀
O yẹ ki igbin mọ iwọn ara rẹ̀ lati mọ̀ pé irú ìwo ohun kò wà fún ohun ijà, lai si bẹ́ẹ̀, wọ́n á tẹ igbin pa
A lè lo òwe Yorùbá ti ó ni A sọ̀rọ̀ ẹran ti o ni ìwo, ìgbín yọjú yi fún àwọn ẹ̀kọ́ wọnyi a lè fi bá ẹni ti ó bá jọ ara rẹ lójú wi, aimọ iwọn ara ẹni léwu, ọgbọ́n wà ninu mi mọ agbára àti àbùkù ara ẹni, ki á lo ohun ti a ni fún ohun ti ó yẹ – bi a bá lo ìmọ̀ òṣìṣẹ́ fún irú iṣẹ́ ti wọn mọ̀, á din àkókò àti ìnáwó kù, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Fún àpẹrẹ ilé ti ó ni òrùlé, ilẹ̀kùn àti fèrèsé, àdìrò àti àdògán, omi Ki ba jẹ omi ẹ̀rọ, omi òjò tàbí kànga ṣe pàtàkì àti oúnjẹ
Ẹ yẹ àwọn orúkọ àti àwòrán àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ti a lè ri ni àyíká ilé ni ojú ewé yi
Ni ayé àtijọ́ ẹsẹ̀ ni gbogbo èrò ma nlo lati rin lati ìlú kan si keji nígbàtí ọkọ̀ ìgbà̀lódé kò ti wọpọ
Ilé Ọba àti Ìjòyè ni a ti le ri ẹṣin nítorí ẹṣin kò lè rin ninu igbó kìjikìji ti o yi ilẹ̀ Yorùbá ká
Ọrọ Yorùbá ayé òde òní ni Ẹsẹ̀ yá ju mọ́tọ̀ ara lo nfàbọ̀ si
Ọ̀rọ̀ yi bá àwọn èrò ayé àtijọ́ mu nítorí ìrìn-àjò ti wọn fi ẹsẹ̀ rin fún ọgbọ̀n ọjọ́, ko ju bi wákà̀̀tí mẹ́fà lọ fún ọkọ ilẹ̀ tàbi ogoji ìṣẹ́jú fún ọkọ̀-òfúrufú
Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn ohun ìrìnsẹ̀ ayé àtijọ́ àti ayé òde òní ni èdè Yorùbá, ohun àti àwòrán ti ó wà ni ojú ewé yi
Gẹgẹ bi Òwe Yorùba,́ Ọmọ ẹni kì í burú títí, ká fi fún ẹkùn pajẹ
Òwe yi bá ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú ti ó ṣẹlẹ̀ si Daniel Pelka mu
Kò tọ́ ki ìyá Daniel Pelka ti o yẹ ki ó dáàbò bo ọmọ fi ìyà jẹ ọmọ ọdún mẹrin yi dé ojú ikú
Ọmọ kékeré yi jẹ̀ ìyà kú lọ́wọ́ ìyá àti ọkọ rẹ
Kini ọmọ ọdún mẹrin lè ṣe lati gbèjà ara rẹ lọ́wọ́ òbí burúkú
Kòsí ohun ti ọmọdé lè ṣe, ṣugbọn Ìjọba fa obìnrin àti ọkùnrin burúkú yi lọ si Ilé-Ẹjo
Wọ́n gba ìdájọ́ èyí ti wọn ni lati lo ọgbọn ọdún ó kéré jù
Ẹ wo ìròyìn yi
Gẹgẹbi òwe Yorùbá Ẹni ti ó ni ki ará ilé ohun má là, ará ìta ni o ya láṣọ
Òwe yi là le fi ba awọn èyaǹ wa wi, nítorí bi Òyìnbó bá bẹ̀rẹ̀ si ṣe irú àjọ̀dún yi, awọn enia wa a tò pẹ̀lú ẹ̀bẹ̀ lati gba àyè lati fi iṣẹ́ ọnà àti àṣà Yorùbá ni irú ibi bẹ́ẹ̀
Bi èrò ìwòran ti ó fẹ́ mọ nípa iṣẹ́ ọ̀na Yorùbá ti pọ̀ tó, kòsí oníṣẹ́ ọnà bi onilù, olórin ìbìlẹ́, oníṣòwò ọjà ìbílẹ̀ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ lati polówó iṣẹ́ ọnà àti àṣà Yorùbá ni àjọ̀dún yi
Awọn ẹ̀ka Yorùbá ti ó wà ni Brazil ló kó onílù àti oníjò Batala ti ó dá awọn èrò lára ya
Awon olonje Yorùbá ri oja ta
Awọn onilù, oníṣòwò ibile, olórin ibile, oniṣẹ ọna ati eléré ìbílẹ̀ Yorùbá ni ìlú-ọba pàdánù àti jẹ ọrọ̀ àti polongo iṣẹ ọwọ́ wọn
Ó ṣe pàtàkì lati parapọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ lati gbé àṣà, iṣẹ́ ọnà àti èdè Yorùbá lárugẹ
Yorùbá ni Ọmọdé ò jobì, àgbà ò jẹ oye, òwe yi bá àwọn òbí ti ó kọ ọmọ sílẹ̀, ìyá ti ó ta ọmọ, bàbá ti ó sá fi ọmọ sílẹ̀ àti àwọn ti o fi ìyà jẹ ọmọ, irú ọ̀pọ̀lọpọ̀ òbí bayi ni òṣì má ta pa
Kò sí àyè fún ọmọ irú àwọn bayi lati mọ wọn lójú nítorí wọn o si nílé lati ṣe ojuṣe wọn gẹ́gẹ́bí òbi ati lati kọ́ ọmọ aláìgbọràn
Irú orin bayi ló tọ́ sí irú òbí bẹ́ẹ̀
Orin yi ni Olùkọ́ ma fi ńkọ́ àwọn ọmọ ilé-ìwé alakọbẹrẹ nigbà ilé-ìwé ọ̀fẹ́ ti àwọn Òṣèlú ilẹ̀ Yorùbá ti Olóyè Ọbáfẹ́mi Awólọ́wọ̀ ṣe olórí rẹ
Ni ayé ìgbà wọnyi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ òbí a ma fi ebi panú, ṣiṣẹ́ kárakára tàbí ta ohun ìní lati pèsè fún àwọn ọmọ àti lati rán ọmọ lọ sí ilé-ìwé gíga
O yẹ ki ọmọ bọ̀wọ̀ fún irú àwọn òbí wọnyi
Ìyàtọ̀ diẹ̀ ló wà láàarín awọn ẹru igbéyàwó ti a kọ́ si ojú iwé yi lati idile si idile
Kò si àyè àti sin abo ewúrẹ́ fún awọn ti o ńgbé ìlú nla tàbi ìlú òyìnbó́, nítorí náà a lè fi owó dipò fún ìyá àgbà ni abúlé ki wọn ra abo ewúrẹ́ lati sin fún ìyàwó
Awọn ẹlẹ́sìn ìgbàlódé lè sọ wipé awọn ò fẹ́ ki wọn fi ataare àti obì ṣe àdúrà fún ọkọ ati ìyàwó
A tún ṣe akiyesi wipé wọn ki tú àpóti ìyàwó mọ, nítorí ni ayé àtijọ́, wọn yio ṣi àpóti ki gbogbo ẹbí ri awọn ohun ẹ̀ṣọ́ ti ọkọ ìyàwó ra fún ìyàwó rẹ, eyi bo àṣírí ìnáwó lori awọn ohun ẹṣọ
Ẹbi tún lè wo ṣe fún ọkọ ìyàwó lati gba idaji oye iṣu tàbi ẹrù lati bo ni àṣiri
Erin jẹ ẹranko ti Ọlọrun da lọ́lá pẹlu titobi rẹ ninu igbo
Yorùbá ni Koríko ti Erin bá ti tẹ̀, àtẹ̀gbé ni láyé, oko ti Erin bá wọ̀, olóko bẹ wọ igbèsè tori ibajẹ ti o ma ṣẹlẹ̀ si irú oko bẹ
Gbogbo ẹranko bọ̀wọ̀ fún Erin, nítorí Kìnìún ọlọ́là ijù kò lè pa Erin
Bi Erin ti tóbi tó, ni ó gọ̀ tó
Ni ọjọ́ kan, gbogbo ẹranko pe ìpàdé lati pari ìjà fún Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ àti Kìnìún
Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ni bi ohun ba pa ẹran, Kìnìún a fi ògbójú gba ẹran yi jẹ
Kàkà ki Erin da ẹjọ́ pẹ̀lú òye, ṣe ló tún dá kun
Ìhàlẹ̀ àti ìgbéraga ni àwùjọ yi bi awọn ẹranko yoku ninu
O bi Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ninu to bẹ gẹ ti kò lè fọhùn
Àjàpá nikan lo dide lati fún Erin ni èsì ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n gbogbo ẹranko yoku bú si ẹ̀rín nítorí wọn fi ojú di Àjàpá
Dipo ki Àjàpá panumọ́, ó pe erin níjà
Ni ọjọ́ ìjà, Erin kò múra nítorí ó mọ̀ pé bi Àjàpá ti kéré tó, bi ohun bá gbé ẹsẹ̀ le, ọ̀run lèrọ̀
Àjàpa mọ̀ pé ohun ko ni agbára, nítorí eyi, ó dá ọgbọ́n ti yio fi bá Erin jà lai di èrò ọ̀run
Àjàpá ti pèsè, agbè mẹta pẹlu ìgbẹ́, osùn àti ẹfun ti yio dà lé Erin lóri lati dójú ti
Ó tọ́jú awọn agbè yi si ori igi nitosi ibi ti wọn ti fẹ́ jà, ó mọ̀ pé pẹ̀lú ibinu erin á jà dé idi ibi ti yio dà le lori
Awọn ẹranko péjọ lati wòran ijà láàarín Àjàpá àti Erin
Àjàpá mọ̀ pe bi erin bá subú kò lè dide, nígbàtí ti ijà bẹ̀rẹ̀, ẹhin ni Àjàpá wà ti o ti nsọ òkò ọ̀rọ̀ si erin lati dá inú bi
Pẹ̀lú ibinú, ki ó tó yípadà dé ibi ti Àjàpá wa, Àjàpá a ti kósi lábẹ́, eleyi dá awọn ẹranko lára yá
Yorùbá ni Bi ìyà nla ba gbeni ṣánlẹ̀, kékeré á gorí ẹni ni ikẹhin, Àjàpá bori erin pẹ̀lú ọgbọ́n, gbogbo ẹranko gbé Àjàpá sókè pẹ̀lú ìdùnnú gun ori ibi ti erin wó si
Òwe Yorùbá ti ó ni Bi ará ilé ẹni ba njẹ kòkòrò búburú ti a ò sọ fun, hẹ̀rẹ̀huru rẹ kò ni jẹ ki a sùn bá iṣẹlẹ ọ̀rọ̀ àti pèsè ina monamona yi mu
Pẹlu gbogbo owó ti ó ti wọlẹ̀ lóri àti pèsè ina mona-mona, ará ilé ẹni ti o ńjẹ kòkòrò búburú ti jẹ́run
Ariwo yi pọ to bẹ gẹ, ti àtisùn di ogun
Àti ọ̀sán àti òru ni ariwo ẹ̀rọ-iná kékèké yi ma ńdá sílẹ̀, ṣùgbọ́n èyí tó burú jù ni herehuru ti òru
Ki ṣe omi, epo-rọ̀bi, èédú nikan ni a fi lè ṣe ètò ina mona-mona
A lè fi oòrùn, atẹ́gùn àti pàntí ti ó pọ̀ ni orílẹ̀ èdè wa ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ pèsè iná mona
Ìlú ti kò ni oòrùn tó ilẹ̀ aláwọ̀-dúdú ńfi oòrùn pèsè iná mona-mona
Ohun ìtìjú ni pé fún bi ọgbọ̀n ọdún ó lé díẹ̀, àwọn Òṣèlú àti ará ìlu, kò ri ará ilé ti ó ńjẹ kòkòrò búburú báwí
Yorùbá ka ọmọ si ọlá àti iyì ti yio tọ́jú ìyá àti bàbá lọ́jọ́ alẹ́
Eyi han ni orúkọ ti Yorùbá nsọ ọmọ bi Ọmọlọlá, Ọmọniyì, Ọmọlẹ̀yẹ, Ọmọ́yẹmi, Ọlọ́mọ́là, Ọlọ́mọlólayé, Ọmọdunni, Ọmọwunmi, Ọmọgbemi, Ọmọ́dára àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
A o tun ṣe akiyesi ni àṣà Yorùbá pe bi obinrin ba wọ ilé ọkọ, wọn ki pe ni orúkọ ti ìyá ati bàbá sọ, wọn a fun ni orúkọ ni ilé ọkọ
Nígbàtí ó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ wọlé wọn a pe ni Ìyàwó ṣùgbọ́n bi ó bá ti bímọ a di Ìyá orúkọ àkọ́bí, bi ó bá bi ibeji tabi ibẹta a di Ìyá Ibeji tàbi Ìyá Ibẹta
Bàbá ọmọ a di Bàbá orúkọ ọmọ àkọ̀bí, Bàbá Ibeji tàbi Bàbá Ìbẹta
Nítorí idi eyi, ìgbéyàwó ti kò bá si ọmọ ma nfa irònú púpọ̀
Ni abúlé kan ni aye atijọ, ọkọ ati ìyàwó yi kò bímọ fún ọpọlọpọ ọdún lẹhin ìgbéyàwó
Nítorí àti bímọ, wọn lọ si ilé Aláwo, wọn lọ si ilé oníṣègùn lati ṣe aajo, ṣùgbọ́n wọn o ri ọmọ bi
Aladugbo wọn gbà wọn niyanju ki wọn lọ si ọ̀dọ̀ Olóri-awo ni ìlú keji
Ọkọ àti ìyàwó tọ Olóri-awo yi lọ lati wa idi ohun ti wọn lè ṣe lati bímọ
Olóri-awo ṣe iwadi lọ́dọ̀ Ifa pẹ̀lú ọ̀pẹ̀lẹ̀ rẹ, o ṣe àlàyé pe ko si ọmọ mọ lọdọ Òrìṣà ṣùgbọ́n nígbàtí ẹ̀bẹ̀ pọ, o ni ọmọ kan lo ku lọdọ Òrìṣà-Omi, ṣùgbọ́n ti ohun bá gba ọmọ yi fún wọn kò ni bá wọn kalẹ́, nítorí ti o ba lọ si odò ki ó tó bi ọmọ ni ilé ọkọ yio kú, Òrìṣà-Omi á gba ọmọ rẹ padà
Ààntére lọ fọ abọ́ lódò
Ìyàwó lóyún, ó bi obinrin, wọn sọ ni Ààntéré eyi ti ó tumọ si Ọmọ Omi
Gbogbo ẹbi àti ará bá wọn yọ̀ ni ọjọ́ ìsọmọ lórúkọ
Ni ọjọ kan, Ààntéré bẹ awọn òbí rẹ pé ohun fẹ́ sáré lọ fọ abọ́, awọn òbí rẹ kọ
Nígbàtí ẹ̀bẹ̀ pọ wọn gbà nítorí o ti dàgbà tó lati wọ ilé-ọkọ, wọn ti gbàgbé ewọ ti Olóri-awo sọ fún wọn pe, o ni lati wọ ile ọkọ ki o to bímọ
Ààntéré dé odò, Òrìṣà-omi, ri ọmọ rẹ, o fi iji nla fa Ààntéré wọ inú omi lai padà
Ìyá àti Bàbá Ààntéré, reti ki ó padà lati odò ṣùgbọ́n kò dé, wọn ké dé ilé Ọba, Ọba pàṣẹ ki ọmọdé àti àgbà ìlú wa Ààntéré lọ
Nigba ti wọn dé idi odò, wọn bẹrẹ si gbọ orin ti Ààntéré nkọ, ṣùgbọ́n wọn ò ri
abi-nibi wọn
Àwa òbí lati yi ìhà ti a kọ si èdè Yorùbá padá, ti a kò bá fẹ́ ki o pòórá
Òwe Yorùbá kan tilẹ sọ wípé, Onígbá Io npe igbá rẹ ni pankara, ti a fi nbaa fi kolẹ
Gẹ́gẹ́ bi òbí, ohun ti a bá fi lélẹ̀ fún àwọn ọmọ wa lati ìgbà èwe ni wọn yio gbọ́njú mọ,
ti wọn yio si dìmú
Ṣugbọn kini a nfi lélẹ̀
Ẹ̀kọ́ Àjòjì, Eyi yi ni Èdè Gẹẹsi
Àwa òbí papa, ti a rò
pé a ti lajú ju pé kaa máà fi èdè abínibí wa maa ba àwọn ọmọ sọ̀rọ̀ nílé lọ
Àti kàwé, a si
ti bọ́ si ipele tó ga ju èyi ti a bi wa si lọ, nítorí na, èdè wa di ohun ìtìjú àti àbùkù, ti kò yẹ
ipò ti a wà
Ẹ jẹ́ ki a kọ́ ọgbọ́n lára àwọn Ìgbò, Hausa, òyìnbó, China àti India,ki a si fi won ṣe àwòkọ́ṣe
Kò si ibi ti àwọn wọnyi wà, yálà nílé tabi lóko, èdè wọn, ni wọn maa ba awọn ọmọ sọ
Àwọn òyìnbó gbé èdè wọn ni arugẹ, ni ó mú ki idaji gbogbo enia ni àgbáyé ki ó maa lo èdè wọn
Àwọn ará ìlú China, ẹ̀wẹ̀, kò fi èdè wọn ṣeré rárá, tó bẹ́ẹ̀ ti odindi ìlú America, àti àwọn kan ni ilẹ̀ adúláwọ̀ ti bẹ̀rẹ̀ si kọ awọn ọmọ ilé-ìwé wọn ni Mandarin, ẹ̀yà èdè China
Ti a kò bá fẹ́ ki èdè Yorùbá ki ó di ohun ìgbàgbé, a ni lati yi padà, ki á si ṣe àtúnṣe
Ẹ jẹ́ ki ó jẹ́ èdè yi ni àwọn ọmọ wa yio kọ́ gbọ́, ti á o si má ba wọn sọ ninu ilé, dípò èdè Gẹẹsi
Yorùbá ni Omi lènìyàn, bi ó bá ṣàn siwájú á tún ṣàn sẹ́hìn
Òwe yi túmọ̀ si wipé lati ọjọ́ ti aláyé ti dáyé ni èniyàn ti nkúrò ni ìlú kan lọ si ikeji fún ọpọlọpọ idi
Èniyàn ma nkúrò ni ìlú abínibí nítorí ogun, ìyàn, ọ̀gbẹlẹ̀, ọrọ̀ ajé, ìtẹ́síwájú ninu ẹ̀kọ́, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú kún fún wàrà àti oyin nítorí ọgọrun-din-marun ohun àlùmọ́nì gbogbo àgbáyé wà ni orílẹ̀ èdè naa
Lára ìwà burúkú yi ló ndá ogun àti ọ̀tẹ̀ si ìlú àti tẹ̀mbẹ̀lẹ̀kun awọn ọ̀dọ́
Èrè awọn ìwà ìbàjẹ́ wọnyi ti ba ìlú jẹ, èyi jẹ ikan ninu ohun ti ó dá kún ohun ti ọ̀dọ́ ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú fi nkúrò lọ si òkè-òkun ni ọ̀nà kọnà
Iroyin awọn ọdọ òṣìṣẹ́ ti o nṣi kúrò ni ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú ti ọkọ̀ wọn dà si òkun ni ìlú Lampedusa, Italy kàn loni ọjọ́ Ẹti, osu kewa, ọjọ́ kẹrin ọdún Ẹgbàálemẹ̀talá
Iroyin ikú ọ̀rùndínrínwó òṣìṣẹ́ tó ṣègbé si òkun kan
Yorùbá ni Ẹ̀bẹ̀ là mbẹ̀ òṣìkà ki ó tú ìlú rẹ̀ ṣe
Òwe yi bá awọn Oṣelu ti a npe ni Alágbádá àti awọn Olórí ìjọ ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, ki wọn jọwọ tún ìlú wọn ṣe
Ọpọlọpọ ewu ti awọn ọdọ nla kọjá iba din kù bi awọn Olórí ìlú bá lè fi ìwà burúkú sílẹ̀, ki wọn tu ìlú ṣe nípa ṣi ṣe ìdájọ́ fún Olórí ti ó bá ṣe iṣẹ́ ibi bi ki kó owó ìlú jẹ àti awọn ìwà ìbàjẹ́ yoku
Ilẹ̀ Yorùbá jẹ́ ikan ninu ẹ̀yà nlá lára orílẹ̀ èdè Nàíjíríà
Orílẹ̀ èdè yi gba ominira lati ọ̀dọ̀ ilú-ọba ni ọdún mẹ́tàléladọta sẹhin
Lati igba ti Nàíjíríà ti gba ominira, Kàkà ki ewé àgbọn dẹ̀, koko ló tún nle si
Bi ọdún ti ńgorí ọdún ni ó nle koko si fún ará ilú
Olórí ilú ti a npe ni Ìjọba mba ọrọ̀ ilú jẹ pẹ̀lú iwà ibàjẹ́ bi gbigba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, ojúkòkòrò, rírú òfin ti wọn fúnra wọn fi silẹ̀, fifi èrú gba Ìjọba, kíkó ọrọ̀ ilú lọ si òkè-òkun àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Kò si ìyàtọ̀ laarin Ìjọba Ológun àti Òṣèlú
Èrè iwà burúkú lati ọ̀dọ̀ Òṣèlú ti ran awọn ará ilu
Oriṣiriṣi iwà burúkú ti kò ṣẹlẹ̀ láyé àtijọ́ ti bẹ̀rẹ̀ si ṣẹlẹ̀
Fún àpẹrẹ, gbọmọgbọmọ ti gbòde, olè jíjà, jìbìtì, tẹ̀mbẹ̀lẹ̀kun, ọ̀tẹ̀ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Kò si iná, omi, ilé-ìwé fún ọmọ aláìní, ojú ọ̀nà ti bàjẹ́, awọn ará ilú njẹ ìyà, ọpọlọpọ ọdọ jade ilé-ìwé wọn ò ri iṣẹ́, èyi to ri iṣẹ́ ngba owó ti kò tó jẹun àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Bi Nàíjíríà ti nṣe àjọ̀dún kẹtaleladọta ni ọjọ́ kini oṣù kẹwa, ó yẹ ká gbé òwe Yorùbá ti ó ni Ọmọ to yi ko gbọn, Ìyá ni ko ma ṣa kú, kilo npa ọmọ bi agọ̀, yẹ̀wò
Ìlú tó bá gbọ́n ni lati kó ara pọ̀ lati ṣe àpérò fún àtúnṣe nkan ti ó ti bàjẹ́, ki agọ̀ ma bà pa orílẹ̀ èdè
Bi ó ti wù ki ó ri, ẹni ọdún bá láyé, ó yẹ ki ó dúpẹ́, ki ó ni ireti pé ọ̀la yi o dára, nítorí eyi, ẹ̀yin olólùfẹ́ èdè àti àṣà Yorùbá, ẹ kú ọdún ominira o
Òwe Yorùbá yi ṣe gba àwọn ti o nbẹ̀rù nigba gbogbo níyànjú wípé ó yẹ ki èniyàn fara balẹ̀ lati ṣe iwadi ohun ti ó fẹ́ ṣẹlẹ̀ ki ó tó kú sílẹ̀ de ikú
Ẹlòmíràn, kò ni ṣe iwadi ohun ti àwọn èniyàn fi ńsáré, ki ó tó bẹ̀rẹ̀ si sáré
Ọpọlọpọ ti sa wọ inú ewu ti wọn rò wípé àwọn sá fún
Fún àpẹrẹ, nígbàtí iná ajónirun balẹ̀ ni àgọ́ Ológun ni Ikẹja ni ìlú Èkó ni bi ọdún mẹjọ sẹhin
Bi àwọn kan ti gbọ́ ìró iná ajónirun yi, wọn sáré titi ọpọ fi parun si inú irà ni Ejigbo ni ọ̀nà jínjìn si ibi ti ìṣẹ̀lẹ̀ ti ṣẹlẹ̀
Àpẹrẹ miran ti a lè fi ṣe àlàyé pé Ọ̀run ńyabọ̀, ki ṣé ọ̀rọ̀ ẹnìkan ni ẹni ti ó sọ pé ohun ri wípé ayé ti fẹ parẹ́, àwọn kan gbàgbọ́, wọn bẹ̀rẹ̀ si ta ohun ìní wọn
Àti ẹni ti ó ta ohun ìní àti ẹni ti ó ra, kò si ninú wọn ti ó ma mú nkankan lọ ti ayé bá parẹ nitotọ
Èkó jẹ́ olú ìlú Nàíjíríà fún ọpọlọpọ ọdún, ki wọn tó sọ Abuja di olú ìlú Nàíjíríà, ṣùgbọ́n Èkó ṣi jẹ́ olú ìlú fún iṣẹ ọrọ̀ gbogbo Nàíjíríà
Nítorí eyi, gbogbo ẹ̀yà Nàíjíríà àti àwọn ará ìlú miran titi dé òkè-òkun ló wà ni Èkó
Yorùbá ni èdè ti wọn nsọ ni ìgboro Èkó, ṣùgbọ́n ọpọlọpọ gbọ èdè Gẹẹsi, pàtàkì àwọn ti ki ṣé ọmọ Yorùbá
Ẹ wo díẹ̀ ni àwọn ìṣe àti ọ̀rọ̀ ni ìgboro Èkó
Gẹgẹbi àpè júwe, ẹranko a fàyà fà jẹ ẹranko ti ó ni àwọ̀, omiran ni oro, omiran ni ikarawun, wọn si ńyé ẹyin
Fún àpẹrẹ irú àwọn ẹran wọnyi ni Ejò, Àjàpá, Alangba àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Ẹ wo àwòrán àti pipe irú àwọn ẹranko wọnyi ni ojú ewé yi
Ni asiko ọdún, pàtàkì, asiko ọdún iranti ọjọ ibi Jésù, bi oúnjẹ ti pọ̀ tó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti o wa ni Òkè-okun àti àwọn díẹ̀ ni ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú, bẹ́ẹ̀ ni o ṣọ̀wọ́n tó fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àgbáyé
Ò̀we Yorùbá ni, Ọ̀kánjúwà-á bu òkèlè, ojú rẹ à lami
Bi enia ò bá ni ọ̀kánjúwà, á mọ irú òkèlè ti ó lè gba ọ̀nà ọ̀fun rẹ, ṣùgbọ́n ọ̀kánjúwa á bu lai ronu pe òkèlè ti ó ju ọ̀nà ọ̀fun lọ á fa ẹkún
Òwe yi bá àwọn ti ó ṣe jura wọn lọ tàbi ki ó jẹ igbèsè lati ra ẹ̀bùn, oúnjẹ ti wọn ò ni jẹ tán, aṣọ, bàtà àti oriṣiriṣi ti wọn ri ni ìpolówó lai mọ̀ pé ọdún á ré kọjá
Lẹhin ọdún, ọ̀pọ̀ a fi igbèsè bẹ̀rẹ̀ ọdún titun, eyi a fa ìrora àti ọ̀rọ̀ ti ó ṣòro si ayé irú ẹni bẹ́ẹ̀
Yorùbá ni Ájẹ ìwẹ̀hìn ló ba Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ, nítorí eyi ìkìlọ̀ fún ẹ̀yin ti ẹ ni ìfẹ́ àti gbé èdè àti àṣà̀̀ Yorùbá lárugẹ, pe ki ẹ ṣe ohun gbogbo ni ìwọ̀ntúnwọ̀nsì
Ẹ kú ọdún o, ọdún titun ti o ḿbọ̀ lọ́nà á ya abo fún gbogbo wa
Lati ọjọ́ ti aláyé ti dá ayé ni Yorùbá ti ni ìgbàgbọ́ ninu ki a gba àdúrà nítorí pe ohun gbogbo fẹ́ àdúrà Ohun ti o dára fẹ́ àdúrà ki ó bà lé dára si, eyi ti kò dára na fẹ́ àdúrà ki ó bà lé yanjú
Bi àwọn Ìgbàgbọ́ tàbi ilé-àdúrà aláṣọ funfun ti ńlo Àbẹ́là gba àdúrà a ni Yorùbá ma ńlo àwọn ohun ọ̀gbin bi Orógbó, Obì, Atare àti Oyin nibi ètò ìgbéyàwó, ìsọmọ lórúkọ, ìṣílé, àjọ̀dún àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Ẹ jẹ ki a ṣe akiyesi bi Yorùbá ti ńlo wọn fún àdúrà Ọpọlọpọ ìgbà ni a ki mọ ẹni ti o gbin igi orógbó nítorí igi rẹ lè pé igba ọdún, nítorí eyi, Yorùbá ma ńlo lati gbàdúrà nibi ṣiṣe fún ẹmi gigun pe wa gbó wa tọ́
Obì wulo fún ọrọ ajé
Yorùbá ni ọdọdún la nri orógbó, ọdọdún la nri obì lori atẹ nítorí eyi wọn a lo fún àdúrà pe obì a bi iku, àti pé ẹni na a ṣe àmọ́dún
Ọmọ pọ ninu atare, nítorí eyi wọn a fi gba àdúrà, pàtàkì fún ẹni ti o nṣe ìgbéyàwó pe ilé wọn á kún fún ọmọ tàbi nibi ìsọmọ lórúkọ pe bi wọn ṣe bi ọmọ na, ilé tirẹ̀ na á kún fún ọmọ
Òwe Yorùbá ni Dídùn là ḿbá láfárá oyin, nítorí eyi wọn a lo oyin lati gba àdúrà nibi ìgbéyàwó, ìsọmọ lórúkọ àti ṣiṣe yoku pe ayé ẹni ti o nṣe nkan á dùn bi oyin
Òwe Yorùbá ti o ni Ká tó ri erin ó digbó, ká tó ri Ẹfọ̀n ó dọ̀dàn, ká tó ri ẹyẹ bi Ọ̀kin ó di gbére fihan pé ki ṣe ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú nikan ni irú Nelson Mandela ti ṣe ọ̀wọ́n, ṣugbọn gbogbo àgbáyé
Melo ninu Olori Òṣèlú àti àwọn Òṣèlú ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú ló lè ṣe bi Nelson Mandela
Bi wọn dé ipò giga wọn ki fẹ kúrò, wọn a paniyan, wọn a jalè, wọn a ta enia wọn àti oriṣiriṣi iwa burúkú miran lati di ipò na mu
Nelson Mandela ṣe ẹ̀wọ̀n fún ọdún mẹta-din-lọgbọn nítorí ó̀ gbìyànjú lati tú àwọn enia rẹ sílẹ̀ ni oko ẹrú
O di enia dúdú àkọ́kọ́ lati dé ipò Olori Òṣèlú ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú
Kò lo ipò yi lati gbẹ̀san iṣẹ́ ibi ti àwọn aláwọ̀ funfun ṣe si tàbi ijiya rẹ ni ẹ̀wọ̀n
Ó fi apẹrẹ onígbàgbọ́ rere han nítorí ó dariji àwọn ti ó fi ìyà jẹ́ ohun àti àwọn enia rẹ tori ki ilú rẹ lè tòrò
Ẹyẹ bi ọ̀kín ṣọ̀wọ́n, kò du lati kú si ori ipò, lẹhin ọdún marun ó gbé ipò sílẹ̀ ki ẹlòmíràn lè bọ́ si
Ọmọ ọdún marun-din-lọgọrun ni ki ó tó pa ipò dà, bi o ti ẹ̀ jẹ́ pé Nelson Mandele ti di arúgbó, gbogbo àgbáyé ò fẹ́ ki ó kú, nítorí ẹyẹ bi ọ̀kín rẹ ṣọ̀wọ́n
Bi àwọn Òṣèlú ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú yoku ba le kọ́gbọ́n lára ìgbà àti ikú Nelson Mandela, ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú á dára
Gbogbo àgbáyé ṣè dárò Madiba Nelson Mandela
Gbogbo ọmọ Yorùbá ni ó dìgbà, ó dìgbóṣe, ó dàrìnàkò, ó dojú àlá ká tó tún ríra
O bi ọmọ mẹta ti wọn jọ ngbe nítorí ìyàwó rẹ ti kú
Bi Bàbá yi bá fẹ́ la ija yio sọ pé ẹ má jà, a ò mọ ohun ti Ọlọrun fi ohun ti ẹ ńjà lé lori ṣe, nítorí náà bi eyi o ṣe, omiran yio ṣe
Ni ọjọ́ kan, ọmọ kú fún obinrin olùbágbélé Bàbá Beyioṣe
Bàbá tún dé ọdọ obinrin yi lati tu ninu, o sọ fún pe Bi eyi o ṣe, omiran yio ṣe – ẹ pẹ̀lẹ́, a o mọ̀ ohun ti Ọlọrun fi ṣe
Ọrọ ìtùnú yi bi ẹniti o ṣe ọ̀fọ̀ ọmọ ti ó kú ninu tó bẹ gẹ ti o fi gbèrò pe ohun yio dán ìgbàgbọ́ Bàbá Beyioṣe wo nípa wiwo ohun ti yio ṣe ti ọmọ ti rẹ náà bá kú
Ni òwúrọ̀ ọjọ́ kan, Bàbá Beyioṣe, sọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé ohun fẹ ji dé ibikan
Ó ṣe ètò pé ki wọn mu ògì àti àkàrà ni òwúrọ̀ ọjọ́ na
Àwọn ọmọ ji, wọn lọ si àrò, wọn po ògì lai mọ pe, obinrin ti ọmọ rẹ ku ti bu májèlé si ògì yi
Àwọn ọmọ gbé ògì wọlé ṣùgbọ́n wọn dúró de ikan ninu wọn ti ó lọ ra àkàrà
Nígbàtí ẹni ti ó lọ ra àkàrà de, ẹ̀gbọ́n àgbà pin àkàrà ṣùgbọ́n ija bẹ silẹ nítorí ẹni ti o pin àkàrà ko pin daradara
Nibi ti wọn ti ńja, ògì ti o jẹ ounjẹ àárọ̀ àwọn ọmọ Bàbá Beyioṣe dànù
Ori igbe ògì ti ó dànù ni àwọn ọmọ wa nígbàtí Bàbá Beyioṣe wọlé
Gẹ́gẹ́ bi iṣe rẹ, ó sọ fún àwọn ọmọ pé ẹ má jà, bi eyi o ṣe, omiran yio ṣe – a o mọ ohun ti Ọlọrun fi ṣe
Obinrin ti o fi májèlé si ògì, ti o reti ki àwọn ọmọ Bàbá Beyioṣe ó kú, ba jade nígbàtí ó gbọ́ ohun ti o sọ lati tu àwọn ọmọ rẹ ninu
Ó jẹ́wọ́ pe nitotọ, onígbàgbọ́ ni Bàbá Beyioṣe nítorí ohun ti ohun ṣe, ó wá tọrọ idariji
Bàbá Beyioṣe dariji, ó fún àwọn ọmọ lówó lati ra ounjẹ miran
Ọ̀gá ninu Olórin Fẹlá Anikulapo-Kuti kọrin pé Ọjọ́ wo la ma bọ o, lóko ẹrú, orin yi fa ìbèrè wípé ọjọ́ wo la ma bọ ninu òkùnkùn ni orílẹ̀ èdè Nàíjíríà
Bi eré bi àwàdà, dákú-dájí iná mọ̀nà-mọ́ná bẹrẹ ni àsikò Ìjọba Sagari, ni bi ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n sẹhin
Ni àsikò yi, ki ṣe pe iná ti ilú pèsè kò tó, ṣùgbọ́n a ṣe akiyesi pé awọn òṣìṣẹ́ ni àsikò na lọ ńyọ nkan lára àpóti iná, nítorí eyi, ki ṣe gbogbo àdúgbò ni ki ni iná
Fún akiyesi, iná ilé-iwé giga àti agbègbè rẹ, awọn ilé iṣẹ́ bi ìlèṣẹ ọkọ̀ òfúrufú, ilé ìwòsàn àti bẹbẹ lọ ki lọ
Bi eniyan ba yọ́ ilẹ̀ dà, ohun burúkú a ma yọ́ni ṣe, nígbàtí awọn òṣìṣẹ́ oníṣẹ́ ibi kò ri ẹni ba wọn wi, ọ̀rọ̀ iná lilọ bẹrẹ si gbòrò si
Pẹlu gbogbo owó ti wọn ti na lati tú ọ̀rọ̀ iná mọ̀nà-mọ́ná ṣe, ó burú si lai ya ilé-iṣẹ́ àti ibi kankan sílẹ̀ ninu òkùnkùn
Yorùbá ni ohun tó yẹ ni, lo yẹ ni, òkùnkùn o yẹ ọmọ eniyan, nítorí òkùnkùn ti ilé-iṣẹ́ mọ̀nà-mọ́ná fa fún ará ilú, ọpọlọpọ ilé-iṣẹ́ ti kò kúrò ni Nàíjíríà eleyi din ìpèsè iṣẹ́ kù, kò si iná lati tọ́jú ounjẹ eleyi jẹ ki ounjẹ wọn si, ìnáwó lori ẹ̀rọ iná mọ̀nà-mọ́ná pẹ̀lú ariwo ki jẹ ki eniyan sùn bẹni kò jẹ́ ki eniyan tabi ilé-iṣẹ́ fi owó pamọ́
Á lérò wípé awọn ilé-iṣẹ́ ti wọn pin iná pi pèsè fún a yọ ilú kúrò ninu òkùnkùn nítorí òkùnkùn kò yẹ ọmọ eniyan
Gbogbo olólùfẹ́ èdè Yorùbá, pàtàkì àwọn ti o fi ìfẹ́ tẹ̀ lé àkọ-sílẹ̀ ọ̀rọ̀ gbígbé èdè àti àṣà Yorùbá́ lárugẹ lóri ẹ̀rọ ayélujára, mo jẹ yin ni àlàyé ohun ti ojú ri lẹhin àbọ̀ oko
Ẹ o ṣe akiyesi wípé, ìwé kikọ wa din kù diẹ nítorí adarí ìwé lọ bẹ ilé wò fún ìgbà diẹ
Ni gbogbo àsìkò ti adarí ìwé fi wa ni ilé ìṣòro nla ni lati lè kọ ìwé lori ayélujára nítorí dákú-dájí iná mọ̀nà-mọ́ná
Lẹhin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún, kàkà ki ewé àgbọn dẹ, koko ló tún nle si
A ṣe akiyesi pé nkan wọ́n ni ilé ju oko lọ, pàtàkì ìnáwó lórí ounjẹ, ẹrọ iná mọ̀nà-mọ́ná àti ọkọ̀ wíwọ̀
Ai si iná, ariwo ẹ̀rọ iná mọ̀nà-mọ́ná, fèrè ọkọ̀ àti sún-kẹrẹ fà-kẹrẹ ọkọ̀ kò jẹ́ ki akọ̀we yi gbádùn ilé bi oko
A lè sọ wípé àwọn Gómìnà ilẹ̀ Yorùbá ngbiyanju, ṣùgbọ́n omi pọ̀ ju ọkà lọ
Àyè iṣẹ́ ti ó yẹ ki Ìjọba àpapọ̀ ṣe ti wọn kò ṣe ńfa ìnira fún ará ìlú
Ẹ̀bẹ̀ là ńbẹ òṣìkà ki ó tú ìlú rẹ̀ ṣe, nítorí eyi, a bẹ Ìjọba àti àwọn Gómìnà pé ki wọn sowọ́ pọ̀ lati tú orílẹ̀ èdè ṣe ni pàtàkì ìpèsè ohun amáyé-dẹrùn
Ìròyìn ti ó nlọ lọ́wọ́ ni orílẹ̀ èdè Nàíjíríà ni pé Aṣojú-ọba nkó ọrọ̀ ilú dànù gẹgẹ bi iṣe awọn yoku lati ra ọkọ̀̀ ojú-ogun
Bi a bá wo iṣe àti àṣà Yorùbá, a o ri pe àwọn Àlejò lati Òkè-Òkun ti o ni Inú Yorùbá ló dùn jù ni àgbáyé kò jẹ̀bi
Kò si ibi ti enia lè dé ni olú-ilú àti ìgbèríko Yorùbá ti kò ni ri ibi ti wọn ti ńṣe àpèjẹ
Yorùbá ni Ọjọ́ gbogbo bi ọdún, pàtàkì ni ilú Èkó, lati Ọjọ́-bọ̀ titi dé Ọjọ́-Àìkú ni wọn ti ńṣe àpèjẹ, ilú miran ńṣe àpèjẹ ni Ọjọ́-Ajé fún àpẹrẹ – Ikẹrẹ-Ekiti
Ọpọlọpọ ayẹyẹ àti Ìjọ́sìn ló mú ìlù, orin, ijó àti àsè dáni
Ni gbogbo ilẹ̀ Yorùbá, àti Ọlọ́rọ̀ àti Òtòṣì ló ńṣe àpèjẹ kan tàbi keji
Bi wọn ò kómọ-jade, wọn a ṣe ìsìnkú tàbi yi ẹ̀hìn òkú padà, ìṣílé, ọjọ́-ibi, igbéyàwó, Ìwúyè, àjọ̀dún àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Òwò tò gbòde ni Ilé-apejọ àti gbogbo ohun èlò rẹ
Ọpọlọpọ àwọn ti o jade ni ilé-iwé giga ti kò ri iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ si kọ́ṣẹ́ bi wọn ti ńwé gèlè, rán aṣọ, àsè sisè àti iṣẹ́ Olù-palèmọ́ ayẹyẹ nígbàtí ẹlẹgbẹ́ wọn ni Òkè-òkun ńṣe àṣe yọri ninú ẹ̀kọ-ijinlẹ
Fún akiyesi, ilé-àpèjọ pọ̀ ju ilé-ìkàwé lọ
Ọpọlọpọ àwọn ti ó ńṣe àpèjẹ yi ló ńjẹ igbèsè lati ṣé
Omiran kò ni ri owó ilé-iwé ọmọ san lẹhin ìsìnkú, tàbi ki wọn ma ri owó lati pèsè oúnjẹ tàbi aṣọ fún ọmọ-tuntun ti wọn ná owó rẹpẹtẹ lati kó jade
Bawo ni a ti lè ṣe àlàyé pé kò si owó lati rán ọmọ lọ si ilé-iwé tàbi bèrè pé ki Ìjọba Òkè-òkun wá pèsè iná mọ̀nàmọ́ná, omi, ilé-ìwòsàn àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ fún àwọn ti Inú rẹ dùn jù ni àgbáyé
Fún idi eyi, Yorùbá ẹ jẹ́ ki á ronú lati ṣe àyipadà
Ọ̀pọ̀ owó ti Ọlọ́rọ̀ fi ńṣe ìsìnkú wúlò fún alàyè lọ, nípa pi pèsè ilé-iwé, omi-ẹ̀rọ, ọ̀nà, ilé-ìkàwé ni orúkọ olóògbé ju ki gbogbo owó bẹ́ẹ̀ lọ fún ayẹyẹ
Òwe Yorùbá ti o ni Bi ikú ilé ò pani, tòde ò lè pani bá ọ̀pọ̀ iṣẹ̀lẹ̀ ti o ńṣẹlẹ̀ nítorí ìfẹ́ owó ti ó gbòde láyé òde òní mu
Ọmọ, ẹbi tabi alábagbe ńdarapọ̀ mọ olè, gbọ́mọgbọ́mọ, oníjìbìtì lati fi ipá gba owó lọ́wọ́ ẹbi ti wọn bá mọ̀ tabi rò pé ó ni owó púpọ̀
Fún àpẹrẹ, ẹni ti o mba enia gbé ló mọ ohun ti enia ni
Bi ọmọ, ẹbi tabi alábagbe wọnyi bá ni ojúkòkòrò wọn á darapọ̀ mọ olè lati gbé ẹrù tàbi owó pẹ̀lú ipá
Ọpọlọpọ obinrin ti o ni ohun ẹ̀ṣọ́ bi wúrà àti fàdákà ni alábagbe ma ńdarapọ mọ olè lati wá gbé ohun ẹṣọ yi fún tita lati di olówó ojiji
Àpẹrẹ pàtàkì miran ni àwọn òṣìṣẹ́ ilé-owó, ilé iṣẹ́ Ijọba àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ti wọn darapọ̀ lati ja ilé iṣẹ́ wọn
Ọ̀pọ̀ igbà ni àṣiri ọmọ, ẹbi tàbi alábagbe tó darapọ̀ mọ́ olè, gbọ́mọgbọ́mọ, òṣìṣẹ́ àti awọn oni iṣẹ́ ibi tókù ma ńtú, ninu ìjẹ́wọ́ awọn oníṣẹ́ ibi wọnyi nígbàtí ọwọ́ Ọlọpa bá tẹ̀ wọ́n
Nítorí eyi, ó yẹ ki a ma ṣọ́ra
Ni igba kan ri, Àmọ̀tékùn ni àwọ̀ dúdú ti ó jọ̀lọ̀, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ kan, Àmọ̀tékùn wá oúnjẹ òòjọ́ rẹ lọ
Ó dé ahéré kan, ó ṣe akiyesi pe obinrin kan ńwẹ̀, inú rẹ dùn púpọ̀ pé òhún ti ri oúnje
O lúgọ de asiko ti yi o ri àyè pa obinrin yi fún oúnjẹ
Yorùbá ni Ọ̀pá tó wà lọ́wọ́ ẹni la fi npa ejò
Nígbàtí obinrin yi ri Àmọ̀tékùn, pẹ̀lú ìbẹ̀rù, ó fi igbe ta, ó ju kàrìnkàn ti ó fi ńwẹ̀ pẹ̀lú ọṣẹ híhó inú rẹ lù
Àmọ̀tékùn fi eré si ṣùgbọ́n, gbogbo ọṣẹ ti ó wà ninu kànrìnkàn ti ta àbàwọ́n si ara rẹ lati ori dé ẹsẹ̀ rẹ, eleyi ló sọ Àmọ̀tékùn di alámì tó-tò-tó lára titi di ọjọ́ oni
Yorùbá ma nlo àwọn àròsọ itàn wọnyi lati kọ́ àwọn ọmọdé ni ẹ̀kọ́
Yorùbá ni Ẹni ti ó bá dákẹ́, ti ara rẹ á ba dákẹ́, nítorí eyi ẹ̀kọ́ pàtàkì ti a ri ninu itàn àròsọ yi ni pé, kò yẹ ki enia fi ìbẹ̀rù dúró lai ṣe nkankan ti ewu bá dojú kọni ṣùgbọ́n ki á lo ohun kóhun ti ó bá wà ni àrọ́wótó lati fi gbèjà ara ẹni
Kòkòrò jẹ́ ohun ẹ̀dá kékeré tó ni ìyẹ́, ti ó lè fò, òmíràn kò ni iyẹ́, ṣugbọn wọn ni ẹsẹ̀ mẹfa
Ẹ ṣe àyẹ̀wò àpẹrẹ, àwòrán àti pi pè ni ojú ewé wọnyi
Ọpọlọpọ ọmọ Yorùbá ti bẹ̀rẹ̀ si tijú lati jẹ orúkọ ti òbí fi èdè Yorùbá sọ wọn
Èwo ni ká kọ Bayọ ni Bayor, Fẹmi ni Phemmy, Tọlani ni Thorlani – kilo njẹ bẹ́ẹ̀
Nígbàtí ẹni to ni orúkọ bá ńbàjẹ bawo ni àjòji ṣe lè pe orúkọ na dada
Lẹhin ọdún pipẹ́ itumọ̀ orúkọ ti wọn ba jẹ yi a sọnù
Ẹni ti kò bámọ̀ itàn ara rẹ̀, wọn á pe lorúkọ ti ki ṣe tirẹ, á si dáhùn
Á gbọ́ ti igbà òwò burúkú Òwò Ẹrú, ti ilú tó lágbára ra àwọn enia bi ẹni ra ohun ini
Ni àsikò yi, bi wọn bà kó enia lẹ́rú, olówó rẹ á fun lórúkọ nítorí ko ma ba ranti ibi ti ó ti ḿbọ̀
Eleyi jẹ ki ó ṣòro fún ẹrú lati mọ ibi ti wọn ti wa lẹhin ti òwò ẹrú pari
Òwe Yorùbá ni Ilé làńwò kátó sọmọ lórúkọ
Ẹ jọ̀wọ́, ẹ maṣe jẹ́ki ẹ̀yà àti èdè Yorùbá parẹ́
Orúkọ ẹni ni ifihàn ẹni, ao ni parẹ máyé o
Ẹ̀gẹ́ fi ara jọ Iṣu nítorí àwọn mejeeji jẹ oúnjẹ ti ó wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá ti wọn ńkọ ebè fún lati gbin
Wọn ma nwa wọn lati inú ebè ti wọn bá ti gbó, wọn ni eèpo ti wọn ma ḿbẹ
Gbaguda ni wọn fi ńṣe gaàrí, bẹni wọn lè ló fún oriṣiriṣi oúnjẹ miran bi wọn ti lè lo iṣu, ṣùgbọ́n oúnjẹ bi iyán ati àmàlà mú iṣu gbayì ju ẹ̀gẹ́ lọ
Fún ẹ̀kọ́ yi, ohun ti a lè fi iṣu ṣe yàtọ̀ si, iyán àti àmàlà ni a fẹ́ sọ
A lè fi iṣu din dùndú, tàbi se lati fi jẹ ẹ̀wà ẹ̀fọ́ rirò ata, tàbi fi se àṣáró
Ìjọba Ìlú-Ọba kò bere lọwọ ará ilú ki wọn tó ṣe ìdàpọ̀ yi, wọn ṣe fún irọ̀rùn ọrọ̀ ajé ilú ti wọn ni
Yorùbá ni À jọ jẹ kò dùn bi ẹni kan kò ri
Nitòótọ, Ijọba Ilu-Ọba ti fún orilẹ̀ èdè Nàíjíríà ni ominira, ṣùgbọ́n èrè idàpọ̀ ti ará ilú kò kópa ninu rẹ kò tán
Gẹgẹbi Olóyè Ọbafẹmi Awolọwọ ti sọ nígbàtí wọn ńṣe àdéhùn fún ominira pe ominira ki ṣe ni ti orúkọ ilú lásán, ṣùgbọ́n ominira fún ará ilú
A ṣe akiyesi pe lẹhin ìdàpọ̀ ọgọrun ọdún, orilẹ̀ èdè ko ṣe ikan
Yorùbá ni A kì í tó́ó báni gbé, ká má tòó ọ̀rọ̀-ọ́ báni sọ Gẹgẹbi òwe yi, ki ṣe ki kó ọ̀kẹ́ aimoye owó lati ṣe àjọyọ̀ ìdàpọ̀ ti ará ilú kò kópa ninu rẹ ló ṣe pàtàkì, bi kò ṣé pé ki a tó ọ̀rọ̀ bára sọ
Yorùbá ni Ọ̀rọ̀ la fi dá ilé ayé
Ẹ̀kọ́ púpọ̀ ni enia lè ri kọ́ ni irin àjò
A lè rin irin àjò fún ìgbà díẹ̀ tàbi pípẹ́ lati bẹ ilú náà wò tàbi lati lọ tẹ̀dó si àjò
Gbogbo ọ̀nà yi ni Yorùbá ti lọ lati dé Ìlú-Ọba
Àṣepọ̀ laarin ará Ìlú-Ọba àti Yorùbá ti lè ni ọgọrun ọdún, nítorí eyi, kò si ibi ti enia dé ni Ìlú-Ọba ni pàtàkì àwọn Olú-Ìlú, ti kò ri ẹni ti ó ńsọ èdè Yorùbá tàbi gbé irú ilú bẹ
A ṣe akiyesi pé lati bi ọdún mẹwa sẹhin, àṣepọ̀ laarin ọmọ Yorùbá ni Ìlú-Ọba din kù
Ni ìgbà kan ri, bi ọmọ Yorùbá bá ri ara, wọn a ki ara wọn
Òwe Yorùbá ni Ibi ti a ngbe la nse, bi a bá dé ìlú adẹ́tẹ̀ a di ìkúùkù, àwọn ọ̀nà ti a lè fi ṣe ibi ti a ngbe Ki ka ìwé nípa àṣà àti iṣẹ ìlú ti a nlọ ninu ìwé tàbi ṣe iwadi lori ayélujára, wiwa ibùgbé, lọ si Ilé-Ìjọ́sìn, Ọjà, Ọkọ̀ wiwọ̀ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Ẹ fi ojú sọ́nà fún àlàyé lori àwọn ọ̀nà ti enia lè lò lati tètè fi idi kalẹ̀ ni àjò
Yorùbá jẹ́ ẹ̀yà ti ó wà ni Ìwọ̀-oòrùn orilẹ̀ èdè Nàíjíríà
Bi Yorùbá ti fẹ́ràn igbádùn tó, bẹ ni wọn fẹ́ràn òwò ṣiṣe àti ẹ̀kọ́ kikọ́
Ọba, Olóyè, Ọlọ́rọ̀ àti aláìní ilẹ̀ Yorùbá ló fẹ́ràn àti rán ọmọ wọn lọ si ilé-iwé bi àwọn fúnra wọn kò ti ẹ lọ si ilé-iwé
Eleyi jẹ ki Yorùbá pọ kà kiri àgbáyé pàtàkì ni Àríwá Nàíjíríà
Nibi ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ Yorùbá ti fẹ́ràn iwé-kikà ni ẹ̀yà miràn ti fi ẹsin bojú lati ṣe àtakò iwé kikà, pàtàkì àwọn ti o ni A ò fẹ́ iwé – Boko Haram
Àwọn ti ó ni àwọn kò fẹ́ lọ si ilé-iwé bẹ̀rẹ̀ si pa ọmọ àwọn ti ó fẹ́ lọ
Wọn kò dúró lóri ọmọ ilé-iwé nikan, wọn ńpa enia bi ẹni pa ẹran ni ọjà, oko, ilú, ọ̀nà àti gbogbo ibi ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilú ni òkè-Ọya pàtàkì ni ilú Borno
Yorùbá ni Bi onilé bá ti ńfi àpárí iṣu lọ àlejò, ilé tó lọ
Ki ṣe àpárí iṣu nikan ni wọn fi ńlọ àjòjì ni òkè-ọya ikú òjiji ni
Àini ifọkàn balẹ̀ kò lè jẹ́ ki àjò ò pé
Lati igbà ti ẹni ti ó so iná ajónirun mọ́ra ti bẹ̀rẹ̀ si pa enia bi ẹni pẹran ni ilé ijọsin – pàtàkì ti onígbàgbọ́, ọjà, áàarín ilú, abúlé àti ilé-iwé ni àjò kò ti pé mọ́
Ìròyìn kàn ni ọjọ́ kẹdogun oṣù kẹrin ọdún Ẹgbàálemẹ́rìnlá, pe wọn ti tún bẹ̀rẹ̀ si ji ọmọ ilé-iwé gbé – ó lé ni ọgọrun ọmọ obinrin ti wọn fi ipá ji wọn gbé, mẹ́rìnlá ni ó ri àyè sá mọ́ ajínigbé lọ́wọ́, òbi àwọn ti ó kù wà ninú ìrora
A lè fi òwe Yorùbá ti ó ni Ẹni àjò ò pé, kó múra ilé gba àwọn Yorùbá ti ó wà ni òkè-ọya ni ìyànjú pé ki wọn bẹ̀rẹ̀ si múra ilé, ki wọn ma ba pàdánù ẹmi, ó sàn ki enia pàdánù owó ju ẹ̀mi lọ
Ni aiyé àtijọ́, ẹsin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ló dàbi ọkọ̀ igbàlódé ti wọn ńpè ni mọ́tò
Ẹni ti ó jẹ́ ọlọ́rọ̀, ló lè ni ẹsin tàbi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
Ẹsẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ fi ńrin irin àjò
Ìtàn yi dá ló̀ri Bàbá àti ọmọ rẹ ti wọn ńsin kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
Wọn múra lati rin irin àjò
Gẹ́gẹ́ bi àṣà Yorùbá lati bu ọ̀wọ̀ fún àgbà, Bàbá ló gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọmọ rẹ bẹ̀rẹ̀ si rin tẹ̀lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
Àwọn enia ti o ri wọn ni Bàbá, iwọ gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ọmọ ńrin ni ilẹ̀
Nítorí ọ̀rọ̀ yi, Bàbá bọ́ silẹ̀, ó gbé ọmọ rẹ gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
Àwọn aiyé tún ri wọn ni Bàbá ńrin nilẹ̀, ọmọ ńgun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọn ti dàgbà, ṣùgbọ́n tori ẹnu aiyé, Bàbá àti ọmọ bá mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ gùn
Wọn ko ti rin jinà nígbàtí àwọn ti ó ri wọn tún ni Ẹ wo Bàbá àti ọmọ tó fẹ́ pa kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
Nítorí àti tẹ́ aiyé lọ́run, Bàbá àti ọmọ bọ́ silẹ̀, wọn bẹ̀rẹ̀ si fi ẹsẹ̀ rin tẹ̀lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́
Àwọn arin irin àjò yókù tún ri wọn, wọn ni Ẹrú aiyé ni àwọn eleyi, bawo ni wọn ṣe lè ni kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ki wọn ma fi ẹsẹ̀ rin
Nígbàtí Bàbá ti gbìyànjú titi, ti kò mọ ohun ti ó tún lè ṣe mọ́, lati tẹ́ aiyé lọ́rùn ni ó ránti ọ̀rọ̀ Yorùbá tó ni Kò si ọgbọ́n ti o lè dá, kò si iwà ti o lè hù, ti o lè fi tẹ́ aiyé lọ́rùn
Yorùbá ni Ẹni à ḿbá ra ọjà là ńwò, a ki wó ariwo ọjà̀
Lára nkan ti itàn yi kọ́ wa ni pé ohun ani là ńlò, ibi ti à ńlọ ni ká dojú kọ lai wo ariwo ọjà àti pé enia ni lati ni ọkàn tirẹ̀ nítorí kò si ẹni ti ó lè tẹ́ aiyé lọ́rùn
Ẹ gbọ bi ògúná gbòngbò ninú àwọn ọ̀gá ninú olórin ilẹ̀ Yorùbá àti ilẹ̀ aláwọ̀ dúdú – Chief Ebenezer Fabiyì ti a mọ si Olóyè Adarí ti fi itàn yi kọrin
Àkàrà jẹ ikan ninu ounjẹ aládùn ilẹ̀ Yorùbá
A lè fi àkàrà jẹ ẹ̀ko, fi mu gaàrí tabi jẹ fún ìpanu
Ki ṣe gbogbo enia ló mọ àkàrà din, awọn enia ma nfẹran ẹni ti ó ba mọ àkàrà din
Àti ọmọdé àti àgbà ló fẹ́rán àkàrà
Awọn ọmọde ma nkọrin bayi
Ki ṣe enia nikan ló fẹ́ràn àkàrà, Àjàpá naa fẹ́ràn àkàrà, ṣùgbọ́n kò ri owó raa, nítorí èyi Ojú ni Àjàpá fi nri àkàrà, ètè rẹ ko baa
Àjàpá wá ronú ọgbọ́n ti ó lè dá lati pèsè àkàrà fún òhun àti idilé rẹ
Ó ronú bi wọn ti lè dá ẹ̀rù ba ọmọ alákàrà ki ó lè sá fi igbá àkàrà, rẹ silẹ̀
Ó gbé agọ̀ wọ̀, ìyàwó àti ọmọ rẹ̀ fi pápá́ bora
Bi alákàrà ba ti kiri kọjá, Àjàpá a bẹ si iwájú ọmọ alákàrà, wọn a ma ko orin bayi
Ẹ̀rù ba alákàrà, á da àkàrà dà nù
Àjàpá àti ẹbí rẹ á bẹ̀rẹ̀ si kó àkàrà
Yorùbá ni Wọ́n mú olè lẹẹkan, ó ni ohun ò wá ri, tani fi ọ̀nà han olè
Ọmọ alákàrà sunkún lọ si ilé, inú Ìya-alákàrà kò dùn si ọmọ rẹ nítorí o pàdánù àkàrà àti owó ti o yẹ ki ó pa
Kò gba ìtàn ọmọ rẹ̀ gbọ́, nítorí náà, ó gbé àkàrà fún ni ọjọ́ keji ati ọjọ́ kẹta, ọmọ tún padà pẹ̀lú ẹkún
Ohun fúnra rẹ̀ tẹ̀lé ọmọ rẹ̀, iwin tún yọjú, àwọn mejeeji sá eré padà si ìlú lai ranti gbé igbá àkàrà
Ìyá alákàrà gba ọ̀dọ̀ Ọba àti àgbà ìlú lọ lati sọ ohun ti ojú wọn ri
Ọba pe awọn òrìṣà ìlú lati ṣe iwadi ohun ti ó fẹ́ ba ọrọ̀ ìlú jẹ yi
Ninu gbogbo òrìsà, Ọ̀sanyìn nikan ló gbà lati yanjú ọ̀rọ̀ yi
Ìyá alákàrà tungbe àkàrà fún ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n ohun àti Ọsanyin tẹ̀lé
Bi alákà̀rà ti bẹ̀rẹ̀ si polówó, Àjàpá tún jade gẹgẹ bi iṣe rẹ̀
Yorùbá ni Ọjọ́ gbogbo ni ti olè, ọjọ́ kan ni ti olóhun
Ìyá alákàrà àti ọmọ rẹ̀ tún méré, ṣùgbọ́n Ọ̀sanyin ti o fi ara pamọ́ dúró lati wo ohun ti ó fẹ́ ṣẹlẹ̀
Àjàpá àti àwon idile rẹ̀ jade nwọn bọ ohun ti nwọn fi bora silẹ̀ lati tún bẹ̀rẹ̀ si kó àkàrà
Orí ti Àjàpá yọ jade lati jẹ àkàrà, Ọ̀sanyin fọ igi ẹlẹgun mọ lórí, awọn ẹbi rẹ̀ sálọ
Ọ̀sanyin gbé òkú Àjàpá lọ si ọ̀dọ̀ Ọba
Inú ará ìlú dùn nítorí àṣiri olè tú
Ọba pàṣẹ pe Àjàpá ni ki nwọn bẹrẹ fi rúbọ si Ọ̀sanyin
Ẹ̀kọ́ ìtàn yi ni pe ojúkòkòrò kò lérè, bó pẹ́, bóyá àṣírí olè á tú
Ikú lèrè ẹ̀ṣẹ̀ – Àjàpá pàdánù ẹ̀mí nítorí àkàrà
Gbé epo kaná
Kó èlò bi ẹ̀jà tútù tàbi gbigbẹ, edé, pọ̀nmọ́ sinú ikòkò epo-pupa yi
Fi iyọ̀ àti iyọ̀ igbàlódé àti omi si inú ikòkò yi lati se omi ọbẹ ìkọ́kọrẹ́
Fọ Iṣu Ewùrà kan
Bẹ Ewùrà yi
Fi iyọ̀ bi ṣibi kékeré kan po ewùrà ri-rin yi
Lẹhin pi pò, dá ewùrà pi pò yi sinú omi ọbẹ̀ ti a ti sè fún bi iṣẹ́jú mẹdogun
Rẹ iná rẹ silẹ̀, se fún bi ogún iṣẹ́jú
Lẹhin eyi bu fún jijẹ
Ẹbi Iṣu ni Ewùrà ṣùgbọ́n a lè pe Iṣu ni ẹ̀gbọ́n Ewùrà nítorí ohun ti a lè fi Iṣu ṣe gbayì laarin gbogbo Yorùbá ju eyi ti a lè fi Ewùrà ṣe
Ọpọlọpọ Yorùbá fẹran oúnjẹ òkèlè bi iyán àti àmàlà ti o gbayì ni ọpọlọpọ ilẹ̀ Yorùbá
Ohun miran ti wọn ńfi iṣu ṣe ni Àsáró, iṣu sisè, iṣu sí-sun, iṣu dín-dín àti àkàrà iṣu
Oúnjẹ ti ó wọ́po laarin àwọn Ijẹbu ti a ńfi Ewùrà ṣe ni Ìfọ́kọrẹ́ tàbi bi àwọn ọmọdé ti ma ńpe Ìkọ́kọrẹ́ ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ Yorùbá na fẹ́ràn Ìfọ́kọrẹ́
A lè jẹ Ìfọ́kọrẹ́ lásá̀n, àwọn miran lè fi jẹ ẹ̀bà
A tún lè lo Ewùrà lati ṣe Ọ̀jọ̀jọ̀
Ọ̀pọ̀ Ewùrà sisè kò dùn lati jẹ bi iṣu gidi
Ẹ ṣe àyẹ̀wò bi a ti ńṣe Ìfọ́kọrẹ́ àti Ọ̀jọ̀jọ̀ lójú iwé yi
Ẹ ṣe àyẹ̀wò bi a ti ńṣe Ìkọ́kọrẹ́ àti Ọ̀jọ̀jọ̀ lójú iwé yi
Ọbẹ̀ ti enia lè yára sè ju ọbẹ̀ ilá ni, nítorí bi a bá ni àpọ̀n kíkù nile, a din àkókò ti ó yẹ ki enia fi rẹ́ ilá kù
Ọbẹ̀ ti a lè fi owó díẹ̀ sè ni
Ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó ni Ẹ jáwọ́ lápọ̀n ti kò yọ̀, ẹ lọ dá omi ilá kaná jẹ́ ọ̀rọ̀ ìyànjú fún ẹni ti ó ba ńṣe iṣẹ́ ti kò ni èrè tàbi ìlọsíwájú, pé ki irú ẹni bẹ gbiyànjú àti ṣe iṣẹ́ miran ki ó má ba fi àkókò ṣòfò
Ẹ yẹ èlò àti sise ọbẹ̀ àpọ̀n ni ojú iwé yi
Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni Àlébù ki ṣe ẹ̀gàn tàbi agọ̀, ṣùgbọ́n, ẹ̀gàn àti agọ̀ ni fún ẹni ti ojú rẹ fọ́ si àlébù ara rẹ
Irú ẹni bẹ́ẹ̀, kò lè ri àtúnṣe tàbi sọ àlèbú yi di ohun ini
Ninú ìtàn bi Àjàpá ti sọ Ẹlẹ́dẹ̀ di ọ̀bùn ti a mọ̀ si titi di oni, Àjàpá jẹ́ ẹranko ti kò lè yára rin tàbi ni agbára iṣẹ́ àti ṣe lówó, ṣùgbọ́n ó ni ọgbọ́n lati bo àlébù rẹ
Yorùbá ni Alágbára má mèrò, baba ọ̀le, Ọgbọ́n ju agbára
Àjàpá́ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ẹwẹ, nígbàtí Ẹlẹ́dẹ̀ jẹ́ alágbá̀ra ti kò mèrò
Kò si ohun ti Àjàpá lè ṣe lai ni idi tàbi ọgbọ́n àrékérekè, nítorí eyi, ó sọ ara rẹ di ọ̀rẹ́ Ẹlẹ́dẹ̀ nítorí gbogbo ẹranko yoku ti já ọgbọ́n rẹ
Ẹlẹ́dẹ̀ kò fi ọgbọ́n wá idi irú ọ̀rẹ́ ti Àjàpá jẹ́
Laipẹ, Àjàpá lọ yá owó lọ́dọ̀ Ẹlẹ́dẹ̀ pẹ̀lu àdéhùn pe ohun yio san owó na padà ni ọjọ́ ti ohun dá
Ẹlẹ́dẹ̀ rò pé ọ̀rẹ́ ju owó lọ, ó gbà lati yá Àjàpá lówó nítorí àdéhùn rẹ
Nígbàtí ọjọ ti Àjàpá dá pé, Ẹlẹ́dẹ̀ reti titi ki ó wá san owó ti ó yá, ṣù̀gbọn Àjàpá kò kúrò ni ilé rẹ nítorí ó mọ̀ pé ohun kò ni owó́ lati san
Àjàpá fi ohun pẹ̀lẹ́ ṣe àlàyé pé bi ohun ti fẹ́ ma kó owó lọ fún Ẹlẹ́dẹ̀ ni olè dá ohun lọ́nà, ti wọn gba gbogbo owó lọ
Inú Ẹlẹ́dẹ̀ kò dùn nítorí kò gba iṣẹ̀lẹ̀ yi gbọ́, ṣùgbọ́n ó gba nígbàtí Àjàpá tún dá ọjọ́ miran lati san owó na
Bi Ẹlẹ́dẹ̀ ti kúrò ló bá aya rẹ Yáníbo dìmọ̀pọ̀ bi ohun kò ti ni san owó padà
Ó ni bi ọjọ́ bá pé, bi Yáníbo bá ti gbọ́ ìró Ẹlẹ́dẹ̀, kó yi ohun padà, ki ó bẹrẹ si lọ ẹ̀gúsí ni àyà ohun lai dúró bi Ẹlẹ́dẹ̀ bá wọlé bèrè ohun
Ni ọjọ́ ti Àjàpá dá pé, Ẹlẹ́dẹ̀ dé lati gba owó rẹ, Yáníbo ṣe bi ọkọ rẹ ti wi
Ẹlẹ́dẹ̀ fi ibinu gbé ọlọ àti ẹ̀gúsí sọnù si ẹrọ̀fọ̀ ti ó wá ni ìtòsí lai mọ̀ pé Àjàpá ni ọlọ yi
Yáníbo fi igbe ta titi ọkọ rẹ fi wọlé
Àjàpá yọ ara rẹ̀ kúrò ninú ẹrọ̀fọ̀, ó nu ara rẹ̀, ó ṣe bi ẹni pé ohun kò ri Ẹlẹ́dẹ̀ nígbàtí ó délé
Ó bèrè ohun ti ó fa igbe ti Yáníbo ńké
Yáníbo ṣe àlàyé
Yorùbá ni Ọ̀bùn ri ikú ọkọ tìrọ̀ mọ́, ó ni ọjọ́ ti ọkọ ohun ti kú ohun ò wẹ̀
Àjàpá ri ohun ṣe àwá-wi, ó sọ fún Ẹlẹ́dẹ̀ pé ọlọ ti ó gbé sọnù ṣe pàtàkì fún idilé àwọn, nítorí náà ó ni lati wá ọlọ yi jade ki ohun tó lè san owó ti ohun yá
Ẹlẹ́dẹ̀ wọnú ẹrọ̀fọ̀ lati wá ọlọ idile Àjàpá
Lati igbà yi ni Ẹlẹ́dẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ si fi imú tú ẹrọ̀fọ̀ titi di ọjọ́ oni
Ni àṣà Yorùbá, ni ayé àtijọ́, ọjọ́ keje ni wọn ńsọmọ obinrin ni orúkọ, ọjọ́ kẹsan ni ti ọmọ ọkùnrin, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, ọjọ kẹjọ ni wọn sọ gbogbo ọmọ lórú̀kọ
Yorùbá ki sọmọ lórúkọ ni ọjọ́ ti wọn bi, ṣùgbọ́n Yorùbá ti ó bá bimọ si òkè-òkun lè fún ilé-igbẹbi lórúkọ ọmọ gẹgẹ bi àṣà òkè-òkun ki wọn tó sọmọ lórúkọ
Òwe Yorùbá ni Ilé làńwò, ki a tó sọmọ lórúkọ nítorí eyi, Bàbá àti Ìyá yio ronú orúkọ ti ó dara ti wọn yio sọ ọmọ ni ọjọ́ ikómọ
Orúkọ Yorùbá lé ni ẹgbẹ-gbẹrun, àwọn orúkọ yi yio jade ni ipasẹ̀ akiyesi iṣẹ̀lẹ̀ ti o ṣẹlẹ̀ ni àsikò ti ọmọ wa ni ninú oyún, ọjọ́ ibi ọmọ, orúkọ ti ó bá idilé tabi ẹsin àtijọ́ àti ẹsin igbàlódé mu
A o ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ igbalode àti àwọn orúkọ ibilẹ ti ó ti fẹ ma parẹ
A o bẹrẹ pẹlu orukọ ti o wọpọ ni idile Ọlá, Ọba, Olóyè àti Akinkanjú ni àwùjọ ni ayé òde òni
Ọlá ninú orúkọ Yorùbá ki ṣe owó àti ohun ini nikan, Yorùbá ka ilera si Ọlà
Ọmọ bibi ni ewu púpọ̀, nítorí eyi ni Yorùbá fi ma nki ìyá ọmọ kú ewu
Ni ọjọ́ ìsọmọ lórúkọ tàbi ìkómọ, Bàbá, Ìyá, ẹbi àti ọ̀rẹ́ òbí ọmọ tuntun á fi ìdùnnú hàn nípa ṣíṣe ọpẹ́ pàtàkì fún Ọlọrun
Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ wọnyi ti òbí lò lati fi ẹmi ìmoore hàn
Òwe yi fi ara han ni itan ìyàwó Aṣojú-ọba, ti a ò pè ni Tinumi pẹ̀lú ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo, ọkùnrin ti a mọ̀ si Mofẹ́
Mofẹ́ dàgbà lati fẹ obinrin
Ó̀ yan obinrin ti à ńpè ni Àyànfẹ́ ni ìyàwó àfẹ́sọ́nà
Nígbàtí ó mú Àyànfẹ́ lọ han àwọn òbi rẹ, Bàbá Mofẹ́ gba Àyànfẹ́ tọwọ́-tẹsẹ̀, ṣùgbọ́n iyá Mofẹ́ fi àáké kọ́ri pé ọmọ ohun kò ni fẹ́ Àyànfẹ́
Wọn bẹ̀rẹ̀ idi ti kò ṣe fẹ́ ki ọmọ ohun fẹ ẹni ti ó múwá, Tinumi kò ri àlàyé ṣe ju pé ohun kò fẹ́ ki ọmọ ohun fẹ́ Àtọ̀hún rin wa – ọmọ ti kò ni iran
Ọmọ rẹ naa fi àáké kòri pé ẹni ti ohun ma fẹ ni Àyànfẹ́
Tinumi sọ àfẹ́sọ́nà ọmọ rẹ di orogún, gbogbo ibi ti ó bá ti pàdé Àyànfẹ ni ibi àjoṣe ẹbi ni ó ti ḿbajà pé ki ó dẹ̀hin lẹhin ọmọ ohun
Àyànfẹ́ lé ọmọ rẹ titi ṣùgbọ́n ó kọ̀ lati dẹhin
Lẹhin ọdún marun ti Mofẹ́ àti Àyànfẹ́ ti ńṣe ọ̀rẹ́, iwé jade pé wọn gbé Bàbá Mofẹ́
Gẹgẹ bi Aṣojú-Ọba lọ si Òkè-òkun
Bàbá ṣètò bi ọmọ àti ìyàwó ti ma tẹ̀lé ohun
Ọmọ kọ̀ pé ohun kò lọ pẹ̀lú òbi ohun ti àfẹ́sọ́nà ohun kò bá ni tẹ̀lé àwọn lọ
Bàbá gbà pé ọmọ ohun ti tó fẹ́ ìyàwó, wọn ṣe ètò igbéyàwó fún Mofẹ́ àti àfẹ́sọ́nà̀ rẹ
Lẹhin ti Mofẹ́ àti Àyànfẹ́ ṣe ìyàwó tán, wọn tẹ̀lé Bàbá àti Ìyá wọn lọ si Òkè-okun lati má jọ gbé
Àrùn ara Tinumi, aya Aṣojú-ọba bẹ̀rẹ̀ si han nítorí ó sọ ìyàwó ọmọ rẹ di orogún
Nígbàtí ọkọ rẹ ri àlébù yi, ó pinu lati wa orogún fun Tinumi nítorí ai ni orogún ni ó ṣe sọ aya ọmọ rẹ di orogún
Gẹgẹ bi a ti mọ, igbéyàwó ibilẹ̀ kò ni ki ọkùnrin ma fẹ ìyàwó keji
Ó jẹ èrè iwà burúkú àti ìgbéraga
Ọkùnrin kan pẹ̀lú ìyàwó púpọ̀ wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá
Àwọn obinrin ti ó bá́ fẹ́ ọkọ kan naa ni à ńpè ni Orogún
Ìwà oriṣiriṣi ni ó ma ńhàn ni ilé olórogún, àrù̀n ìyàwó ti ó ńjalè, purọ́, ṣe àgbèrè, aláisàn, ti ó ńṣe òfófó, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, lè má hàn bi ó bá jẹ́ obinrin kan pẹ̀lú ọkọ rẹ ni ó ńgbe gẹ́gẹ́ bi ti ayé ode oni
Bi ìyàwó bá ti pé méjì, mẹta, bi àrù́n yi bá hàn si ìyàwó keji, èébú dé, pàtàkì ni àsikò ijà
Ni ẹ̀sin ibilẹ̀, oye ìyàwó ti ọkùnrin lè fẹ́, ko niye, pàtàkì Ọba, Olóyè, Ọlọ́rọ̀ àti akikanjú ni àwùjọ
Bi àwọn ti ó ni ipò giga tabi òkìkí ni àwùjọ kò fẹ́ fẹ́ ìyàwó púpọ̀, ará ilú á fi obinrin ta wọn lọ́rẹ
Ẹ̀sin igbàlódé pàtàkì, ẹ̀sin igbàgbọ́ ti din àṣà ikó-binrin-jọ kù
Òfin ẹlẹ́sin igbàgbọ́ ni ọkọ kan àti aya kan
Bi o ti jẹ́ pé ẹ̀sin Musulumi gbà ki Ọkùnrin lè fẹ́ ìyàwó titi dé mẹrin, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin Musulumi igbàlódé ńsá fún kikó ìyàwó jọ
Fẹlá Kúti fẹ́ ìyàwó mẹta-din-lọgbọn ni ọjọ kan
Yorùbá ni Òriṣà òkè jẹ́ ki npé méjì obinrin kò dé nú
Inú obinrin ti wọn fẹ́ ìyàwó tẹ̀lé kò lè dùn dé inú, nítorí eyi, kò lè fi gbogbo ọkàn rẹ tán ọkọ rẹ mọ, owú jijẹ á bẹ̀rẹ̀
ìyàwó kékeré lè dé ilé ri àbùkù ọkọ ti iyálé mú mọ́ra
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé oló-rogún kiki ijà àti ariwo laarin àwọn ìyàwó àti àwọn ọmọ naa
Diẹ̀ ninú ọkùnrin ti ó fẹ́ ìyàwó púpọ̀ ló ni igbádùn
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkùnrin ti ó kó obinrin jọ ni ó ńsọ ẹ̀mi wọn nù ni ọjọ́ ai pẹ́ nítorí ai ni ifọ̀kànbalẹ̀ àti àìsàn ti bi bá obinrin púpọ̀ lò pọ̀ lè fà
Nítorí eyi, ọkùnrin ti ó bá fẹ́ kó ìyàwó jọ nilati múra gidigidi fun ohun ti ó ma gbẹ̀hìn àṣà yi
Yorùbá ni Ọmọ ẹni kò lè burú titi, ká fi fún Ẹkùn pa jẹ, ki ṣe bi ti obinrin Sudan – Mariam Yahia Ibrahim ti wọn gbé si ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú oyún lati dúró de idájọ́ ikú lẹhin ọmọ bibi nítorí ẹ̀sìn
Ohun pẹ̀lú ọmọ ti ó ti bi tẹ́lẹ̀ ni wọn gbé jù si ẹ̀wọ̀n fún ẹ̀sùn pé kò yẹ ki ó fẹ́ ìgbàgbọ́ lábẹ́ òfin Sharia
Lábẹ́ òfin yi, ọkùnrin Ìmàle lè fẹ́ obinrin ni ẹ̀sìn miran, ṣùgbọ́n obinrin wọn kò ni ẹ̀tọ́ lati fẹ́ ẹni ti ó bá ṣe ẹ̀sìn miran
Kò si bi ẹni ti ó fa ọmọ rẹ̀ silẹ̀ nítorí ó fẹ́ ẹlẹ́sìn miran ti lè sọ pé ohun ni òtitọ́ ninú gbàwìn ìkà
Bawo ni enia ṣe lè pa ẹni-keji nítorí ẹ̀sìn
Ìkà ti wà ninú irú àwọn bayi ki wọn to gba ẹ̀sìn, wọn kan fi ẹ̀sìn bojú ṣe ìkà ni
Àjà ni wọn fi ḿbọ̀ Ògún ki ṣe enia
Yorùbá ni A ki fi ọmọ Ọrẹ̀, bọ Ọrẹ̀, òwe yi túmọ̀ si pe abòriṣà Yorùbá kò jẹ́ fa ọmọ rẹ silẹ fún ikú nítorí ó yà kúrò ninú ẹ̀sin ibilẹ̀
Ìròyìn jade pé Mariam Yahia Ibrahim ti bi ọmọ si ẹ̀wọ̀n, a ri ninú ẹbi rẹ ti o ke pe ki won fi ikú si-so pá ti ó bá kọ̀ pé ohun kó padá si ẹ̀sìn Ìmàle
Gbogbo àgbáyé ḿbẹ̀ àwọn Òṣèlú Sudan ki wọn tú obinrin àti àwọn ọmọ rẹ̀ silẹ̀ nítorí irú ẹjọ́ oró yi, kò tọ̀nà ni ayé òde òni
Ọ̀pọ̀ ti ó ni ipò ni àwùjọ ni ó fi iwà ikà ba ipò wọn jẹ
Ìròyìn bi Olóògbé Jimmy Savile ti fi iwà burúkú ba iṣẹ́ ribiribi ti ó ṣe nípa pi pa owó fún ọrẹ-àánú ni ó ńlọ lọ́wọ́-lọ́wọ́
Iṣẹ́ ibi ti ó ṣe ni igbà ayé rẹ fihan pé O ni ikù ló mọ̀ ikà
Gẹ́gẹ́ bi iwadi ti o jáde lẹhin ikú Olóògbé yi, ó lo ipò rẹ ni àwùjọ lati bá ẹ̀dẹ́gbẹ̀ta obinrin ni àṣepọ̀ ni ọ̀nà ti kò tọ́
Òwe Yorùbá ti ó ni Ẹni ti o ni ori rere, ti kò ni iwà, iwà rẹ ni yio ba ori rẹ̀ jẹ́ fihàn pé Jimmy Savile fi iwà àbùkù ba iṣẹ́ rere ti ó ṣe jẹ
Ìṣẹ̀lẹ̀ Jimmy Savile kò ṣe àjòjì ni ilẹ̀ Yorùbá
Ni ayé àtijọ́, àwọn Ọba tàbi Olóyè miran ma ńlo ipò wọn lati ṣe iṣẹ ibi – bi ki wọn gbé ẹsẹ̀ lé ìyàwó ará ilú, fi ipá gba oko tàbi ilẹ̀ ará ilú lai si ẹni ti ó lè mú wọn ṣùgbọ́n láyé òde òni, Ọba tàbi Olóyè ti ó bá hu iwà burúkú wọnyi, yio tẹ́
Olóyè Yorùbá ti ó bá fi ipò tàbi ọlá hu iwà ikà ni ayé igbàlódé yi, kò ri ibi pamọ́ si, nítorí àṣiri á tú ninú iwé-ìròyìn, ẹ̀rọ-asọ̀rọ̀-mágbèsi, ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán àti lori ayélujára
Ki ṣe ará ilú nikan ló lè ṣe ìdájọ́ fún Ọba ti ó bá hu iwà ikà nípa ri-rọ̀ lóyè, gbogbo àgbáyé ni yio ṣe idájọ́ fun, irú Ọlọ́rọ̀ bẹ́ẹ̀ yio tun fi ojú ba ilé-ẹjọ́
Fún àpẹrẹ Ọba Adébùkọ́lá Alli – Alọ́wá ti Ìlọ́wá ti obinrin Agùnbánirọ̀ fi ẹ̀sùn kàn pé ó fi ipá ni àṣepọ̀ àti Déji Àkúrẹ́ ti wọn rọ̀ lóyè nítorí iwa àbùkù – Oluwadare Adeṣina
Gbogbo Ẹranko kó ara jọ lati gbèrò lórí àlébù tí wọ́n rí lára ìyàwó wọn
Ajá, Àmọ̀tẹ́kùn, Ẹkùn, Kìnìún, Ọ̀bọ, Akátá, Ológbò, Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, Ìjàpá àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Ajá ní ìyàwó òhun nṣe àgbèrè, Ẹkùn ní ìyàwó òhun nṣe àfojúdi, Ológbò ní ìyàwó òhun njale, Ọ̀bọ ní ìyàwó òhun lèjàjù àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Àwọn Ẹranko yókù ṣe àkíyèsí wípé,
Ìjàpá kàn mi orí ni lai sọ nkankan ju un!
Kìnìún wa bèrè lọ́wọ́ Ìjàpá wípé ṣe Yáníbo kòní àlébù ni
Àjàpá dìde ó wá fọhùn wípé gbogbo àlébù ti gbogbo wọn sọ nípa ìyàwó wọn kéré lára ti ìyàwó ohun nítorí Yáníbo kò ní ìtìjú
Ẹni ti kó ni ìtìjú a jalè, a purọ́, a ṣe àgbèrè, a ṣe àfojúdi àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Ni Ìlúọba, bi Òṣèlú bá ṣe ohun ìtìjú bi àgbèrè, jalè, gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, bi wọn bá ka mọ tàbí kó rò wípé aṣírí fẹ́ tú, á gbé ìwé sílẹ̀ pé òhun kò ṣe mọ nítorí ki ipò òhun má ba di ìdájọ́ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n apàniyàn, olè, alágbèrè àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, pọ nínú Òṣèlú Nàíjíríà nítorí wọn kò ni ìtìjú
Ipò Òṣèlú tiwọn fún wọn láyè lati ni àlébù àti lati tẹ ìdájọ́ mọ́lẹ̀
Ọ̀rọ̀ Yorùbá tó ni Àìnítìjú lọba gbogbo Àlébù gba èrò lati ri wípé ará ìlú dìbò fún Afínjú Òṣèlú kí wọ́n lè ṣe àtúnṣe nkan tí aláìnítìjú Òṣèlú ti bàjẹ́
Ninú Ẹ̀yà mẹrin-din-logoji orilẹ̀ èdè Nàíjíríà, ẹ̀yà mẹ́fà ni o wa ni ìpínlẹ̀ Yorùbá lápapọ̀
Àwọn ẹ̀yà wọnyi ni Èkó – ti olú ilú rẹ jẹ Ìkẹjà, Èkiti – ti olú ilú rẹ jẹ Adó-Èkiti, Ò̀gùn – ti olú ilú rẹ jẹ Abẹ́òkúta, Ondo – ti olú ilú rẹ jẹ Àkúrẹ́, Ọ̀ṣun – ti olú ilú rẹ jẹ Òṣogbo àti Ọyọ – ti olú ilú rẹ jẹ Ìbàdàn
ọ̀pọ̀ ara Ọ̀ṣun dibò àti bójú tó ibò wọn
Ni Òkè-Òkun, bi enia ba ni ẹjọ́ ni ilé-ẹjọ́, tàbi ó ti ṣe ẹ̀wọ̀n ri, tàbi hùwà àbùkù miran, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò lè gbé àpóti ibò ṣùgbọ́n, ti kò bá ni itiju, ti ó gbé àpóti ibò, ọ̀pọ̀ àwọn èrò ilú kò ni dibò fún irú ẹni bẹ́ẹ̀
Eyi kò ri béè ni orilẹ-èdè Nàíjíríà, nítorí, ẹlẹ́wòn, eleru, olè, apànìyàn àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, ti ó di olówó ojiji ló ńgbé àpóti ibò nítorí wọn mọ̀ pé àwọn lè fi èrú dé ipò
Àwọn èrò ẹ̀yà Ọ̀ṣun fi òwe Yorùbá ti o ni Ọ̀pọ̀ ni eṣú fi ńya igi oko hàn ni idibò ti ó kọjá ni ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹsan, oṣù kẹjọ, ọdún Ẹgbàálemẹ́rìnlá, wọn kò bẹ̀rù bi Ìjọba àpapọ̀ Nàíjíríà ti kó Ológun àti ohun ijà ti àwọn ará ilú lati da ẹ̀rù bà wọn
Wọn tú jáde lati fi ọ̀pọ̀ dibò àti bójú tó ibò wọn lati gbé Góminà Ọ̀gbẹ́ni Rauf Arẹ́gbẹ́ṣọlá padà
Àgbá ti ó kún fún ohun ti ó wúlò bi epo-rọ̀bì, epo-pupa, epo-òróró, epo-òyìnbó, ọ̀dà àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ ki pariwo
Àgbá òfìfo, kò ni nkan ninú tàbi o ni nkan díẹ̀, irú àgbá yi bi o ti wù ki ó lẹ́wà tó, ni ariwo rẹ máa ńpọ̀ ti wọn ba yi lóri afárá tàbi ori titi ọlọ́dà
Àgbá òfìfo ti ó lẹ́wà
Àgbá òfìfo ni àwọn ti ó wà ni ilú òyìnbó ti ó jẹ igbèsè tàbi fi èrú kó ọrọ̀ jọ lati wá ṣe àṣehàn ti wọn bá ti àjò bọ, ohun ti wọn kò tó wọn a pariwo pé àwọn jù bẹ́ẹ̀ lọ
Ni tòótọ́, ìyàtọ̀ ilú-òyìnbó si ilẹ̀ Yorùbá ni pé, àti ọlọ́rọ̀ àti aláìní ló ni ohun amáyé-dẹrùn bi omi, iná mọ̀nà-mọ́ná, titi ọlọ́dà, ilé-iwé gidi, igboro ti ó mọ́ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Àwọn Òṣèlú kò kọjá òfin, bẹni irònú wọn ki ṣe ki á di Òṣèlú lati kó owó ilú jẹ
Ni ayé àtijọ́ ni ilẹ̀ Yorùbá, owó kọ́ ni wọn fi ńmọ ẹni gidi, àpọ́nlé wà fún àgbà, ẹni ti ó bá kàwé, olootọ enia, ẹni tó tẹpá mọ́ṣẹ́, akin-kanjú àti ẹni ti ó ni òye
Ni ayé òde òni, àgbá òfìfo ti pọ ninú ará ilú, àwọn Òṣèlú àti àwọn òṣiṣẹ́ ijọba
Bi wọn bá ti ri owó ni ọ̀nà èrú, wọn a lọ si òkè-òkun lati ṣe àṣehàn si àwọn ti wọn bá lọhun lati yangàn pẹ̀lú ogún ilé ti wọn kọ́ lai yáwó, ọkọ̀ mẹwa ti wọn ni, ọmọ-ọ̀dọ̀ ti wọn ni àti ayé ijẹkújẹ ti wọn ńjẹ ni ilé
Wọn á ni àwọn kò lè gbé ilú-òyìnbó, ṣùgbọ́n bi àìsàn bá dé, wọn á mọ ọ̀nà òkè-òkun fún iwòsàn àti lati jẹ ìgbádùn ohun amáyé-derùn miran ti wọn ti fi èrú bàjẹ́ ni ilú tiwọn
Bi àgbá ti ó ni ohun ti ó wúlò ninú, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹni gidi tó ṣe àṣe yọri ki pariwo
Ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó ni Àgbá òfìfo ló ńdún woro-woro, bá ẹni-kẹ́ni ti ó bá ńṣe àṣehàn tàbi gbéraga wi pé ki wọn yé pariwo ẹnu
Àwọn èlò ọbẹ̀ Yorùbá, ẹni ti ó bá mọ ọbẹ̀ se, yio mọ èlò ọbẹ̀ ti ohun yio ra àti bi yio ti se, ṣùgbọ́n ẹni ti kò mọ ọbẹ̀ se, lè lo owó ai mọye lati se ọbẹ̀, ki ọbẹ̀ rẹ má dùn
Fún àwọn ti ó ńgbé ni Òkè-Òkun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èlò yi ni a lè ri rà ni àyiká
Ẹṣe àyẹ̀wò èlòọbẹ̀ àti pípè rẹ ni ojú ewé yi
Ọkùnrin kan wa láyé àtijọ́, Ògbójú-ọdẹ ni, ṣùgbọ́n bi ó ti pa ẹran tó, kò fi dá nkan ṣe
Ọ̀pọ̀ igbà, ki ri ẹran ti ó bá pa tà, o ma ńpin fún ará ilú ni
Nígbàtí kò ri ẹran pa mọ́, ó di o Ọdẹ-apẹyẹ
Ni ọjọ kan, ògbójú-ọde yi ri ẹyẹ Òfú kan, ṣùgbọ́n ọta ibọn kan ṣoṣo ló kù ninú ibọn rẹ
Gẹgẹbi Ògbójú-ọdẹ, o yin ẹyẹ Òfú ni ibọn, ọta kan ṣoṣo yi si báa
Ó bá wọ igbó lọ lati gbé ẹyẹ ti ó pa, lai mọ̀ pé ẹyẹ yi kò kú
Ó ṣe akitiyan lati ri ẹyẹ́ yi mu, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ si wọ igbó lọ titi ó fi ṣi ọ̀nà dé ilẹ̀ àwọn Ará-Ọ̀run – àwọn ti wọn ńpè ni Abàmi-ẹ̀dá
Inu bi àwọn Ará-Ọ̀run nítorí Ògbójú-ọdẹ yi jálu ipàdé wọn
Wọn gbamú, wọn ni ki ó ṣe àlàyé bi ó ṣe dé ilẹ̀ wọn, ki àwọn tó pá
Ọdẹ ṣe àlàyé ohun ti ojú rẹ ti ri nípa iṣẹ́ àti jẹ àti gbogbo ohun ti ojú rẹ ti ri lẹ́nu iṣẹ́ ọde
Àwọn Ará-Ọ̀run ṣe àánú rẹ, wọn bèrè pé ṣe ó lè dá ẹmu, ó ni ohun lè dá ẹmu diẹ-diẹ
Wọn gbaa ni iyànjú pé ki o maṣe fi ojú di iṣẹ kankan, nítorí naa, ki ó bẹ̀rẹ̀ si dá ẹmu fún àwọn
Wọn ṣe ikilọ pe, bi ó bá ti gbé ẹmu wá, kò gbọdọ̀ wo bi àwọn ti ńmu ẹmu, ki ó kàn gbé ẹmu silẹ ki o si yi padà lai wo ẹ̀hin
Bi ó bá rú òfin yi, àwọn yio pa
Ọdẹ bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún ara orun
Bi ó bá gbé ẹmu dé, a bẹ̀rẹ̀ si kọrin lati jẹ ki àwọn Ará-Ọ̀run mọ̀ pé ohun ti dé, lẹhin èyi á gbé ẹmu silẹ á yi padà lai wo ẹ̀hin gẹgẹ bi ikilọ Ará-Ọ̀run
Ni ọjọ́ keji, á bá owó ni idi agbè ti ó fi gbé ẹmu tàná wá
Ògbójú-ọdẹ á má kọrin bayi
Àyipadà dé fún Ògbójú-ọdẹ ti ó di Ẹlẹ́mu tóó bẹ̀ ti àwọn ará ilú ṣe akiyesi àyipadà yi
Yorùbá ni ojú larí, ọ̀rẹ́ ò dénú
Àjàpá, ọlọ́gbọ́n ẹ̀wẹ́, sọ ara rẹ̀ di ọrẹ kòrí-kòsùn pẹ̀lú Ògbójú-ọdẹ nítorí àti mọ idi ọrọ̀ rẹ
Laipẹ, àrùn Ṣọ̀pọ̀ná bo Ògbójú-ọdẹ, eleyi dá iṣẹ́ àti gbé ẹmu fún àwọn Ará-Ọ̀run dúró
Gẹgẹbi ọ̀rẹ́, ó bẹ Àjàpá pé ki ó bá ohun bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ fún àwọn Ará-Ọ̀run
Ó ṣe ikilọ fún Àjàpá, bi ikilọ ti àwọn Ará-Ọ̀run fi silẹ̀
Àjàpá, bẹ̀rẹ̀ si gbé ẹmu lọ, ni ọjọ́ keji ti ó ri owó rẹpẹtẹ ti àwọn Ará-Ọ̀run kó si idi agbè ẹmu àná, ó pinu lati mọ idi abájọ
Àjàpá, fi ara pamọ́ si igbó lati wo bi àwọn Ará-Ọ̀run ti ńmu ẹmu
Ohun ti ó ri yàá lẹ́nu, ó ri Ori, Ẹsẹ̀, Ojú, Apá àti àwọn ẹ̀yà ara miran ti wọn dá dúró, ti wọn si bẹ̀rẹ̀ si mu ẹmu
Àjàpá, bẹ̀rẹ̀ si fi àwọn Ará-Ọ̀run ṣe yẹ̀yẹ́
Nígbàtí wọn gbọ, wọ́n le lati pá ṣùgbọ́n, Àjàpá, sá àsálà fún ẹmi rẹ, ó kó wọ inú ihò, wọn kò ri pa
Ògbójú-ọdẹ reti titi ki Àjàpá kó owó ẹmu dé
Nígbàtí Àjàpá dé, ó gbé irọ́ kalẹ̀ pé olè dá ohun lọ́nà, wọn gba gbogbo owó ẹmu lọ ni ohun ṣe pẹ́
Ara Ògbójú-ọdẹ ya, ó gbé ẹmu lọ fún ara-orun gẹgẹbi iṣe rẹ tẹ́lẹ̀ lai mọ iwà àkóbá ti Àjàpá, ti hù silẹ̀
Àwọn Ará-Ọ̀run wọ ijàkàdi pẹ̀lú Ògbójú-ọdẹ, nítorí ó rú òfin ikilọ ti wọn fun
Nítorí imọ̀ ti ó ni lẹ́nu iṣẹ Ọdẹ, Ará-Ọ̀run ko ri Ògbójú-ọdẹ pa
Lẹhin ijàkàdi, ó ṣe àlàyé pé ara ohun ni kò yá, ó fi àpá han, pé nítorí eyi ni ohun ṣe bẹ ọ̀rẹ́ ohun Àjàpá, ki ó bá ohun gbé ẹmu lọ fún wọn
Wọn ṣe àlàyé ohun ti Àjàpá ti ó pè ni ọ̀rẹ́ rẹ ṣe fún wọn
Ará-Ọ̀run dariji Ògbójú-ọdẹ pẹ̀lú ikilọ pé ki o maṣe gbára lé ọ̀rẹ́
Wọn ni ọpọlọpọ ọrẹ o ṣe fi okùn ọlà han, nítorí ọ̀pọ̀ ọ̀tá ló ńṣe bi ọ̀rẹ́ nítorí àti jẹ
Orúkọ ẹni ni ìfihàn ẹni, orúkọ Yorùbá fi àṣà, iṣẹ́ àti Òriṣà idile hàn tàbi àtẹsẹ̀bi ọmọ
Yorùbá gbàgbọ́ ninú Ọlọrun ki ẹ̀sin igbàgbọ́ àti imọ̀le tó dé
Ifá jẹ́ ẹ̀sin Yorùbá, nítorí Ifá ni wọn fi ńṣe iwadi lọ́dọ̀ Ọlọrun ki Yorùbá tó dá wọ́ lé ohunkohun
Yorùbá gbàgbọ́ ninú àwọn iránṣẹ́ Ọlọrun ti a mọ̀ si Òriṣà
Àwọn Òriṣà Yorùbá pọ̀ ṣùgbọ́n pàtàkì lára àwọn Òriṣà ni Ògún, Ṣàngó, Ọya, Yemọja, Oṣó, Ọ̀ṣun, Olokun, Ṣọ̀pọ̀ná, Èṣù àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Àwọn orúkọ ti ó fi ẹ̀sin àwọn Òriṣà wọnyi hàn ti ńparẹ́ nítorí àwọn ẹlẹsin igbàlódé ti fi Ọlọrun dipò orúkọ ti ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Ifá, Ògún, Èṣù àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwọn orúkọ wọnyi
Ni ayé àtijọ́, wọn ma ńfi obinrin fún ọkọ ni, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, obinrin á mú̀ àfẹ́sọ́nà lati fi hàn òbi, nítorí Yorùbá gba ọmọ obinrin ni àyè lati lọ si ilé-iwé, tàbi kọ́ iṣẹ́-ọwọ́, àti lati ṣe òwò
Èyi jẹ ki obinrin kúrò lọ́dọ̀ obi wọn
Bi obinrin bá ti dàgbà tó bi ọdún méjì-din-logun, ti ó tó wọ ilé-ọkọ, àwọn òbi yio ma ran léti pé, ó ti tó mú ọkọ wálé
Ẹni ti obinrin mọ̀ pé òhun kò lè fẹ́, bi àfojúdi ni lati fi irú ọkùnrin bẹ́ẹ̀ han òbi
Bi obinrin ti ó ti dàgbà tó lati wọ ilé ọkọ bá mú àfẹ́sọ́nà wá han òbi, wọn yio fi òwe Yorùbá ti ó ni A ki mọ́ ọkọ ọmọ, ki a tún mọ àlè rẹ ṣe iwadi pé, ṣe ó da lójú pé òhun yio fẹ ọkùnrin ti ó mú wá
Òwe yi tún wúlò lati fi ṣe ikilọ nigbà igbéyàwó ibilẹ̀ fún obinrin pé kò lè mú ọkùnrin miràn wá lẹhin igbéyàwó
À ńlo ọ̀rọ̀ yi fún àwọn Ayáni-lówó ki ba jẹ Ilé-owó tàbi àwọn Ayáni-lówó yókù
Ọ̀pọ̀ ìgbà, Ayáni-lówó ló ndá orin nípa oye èlé ti wọn lè fi lé owó ti Onígbèsè ya
Ni ilẹ̀ Yorùbá ohun ti a lè fi ṣe àpèjúwe Ilé-iṣẹ́ Ayáni-lówó ni bi Ọba bá fún ni nilẹ̀ lati fi dá oko, Ọba lè ni ki irú ẹni bẹ kó idá-mẹrin, tàbi idá-marun irè oko náà wá ni igbà ìkórè
Àwọn miran tún ma ńyá owó lọwọ Olówó-èlé
Ẹ̀yà Yorùbá ti a mọ si Ìjẹ̀ṣà ma ńṣe òwò aṣọ àti wúrà tità lati ilú dé ilú àti agbègbè dé agbègbè
Bi wọn ba ti ta àwin fún onibara, bi ọjọ́ bá pé, Ìjẹ̀ṣà á ji lọ si ilé Onígbèsè lati gba owó ọjà, á ni Òṣó máà ló gbowó mi loni nítorí eyi ni wọn fi npe Ìjẹ̀ṣà ni Òṣó máà ló
Ike-ìyáwó kò wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá, ṣùgbọ́n àwọn enia ma ńyá owó lọ́wọ́ ẹbi, ọ̀rẹ́, ẹgbẹ́ àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, lati sin òkú, sán owó ilé iwé ọmọ, ṣòwò àti fún ọ̀pọ̀ idi miran
Èlé owó irú eyi kò pọ̀ tó ti èlé ori Ike-ìyáwó, nigbà miran kò ki ni èlé
Gẹ́gẹ́ bi ọ̀rọ̀ ti ó niẸni sanwó Onífèrè ló ndá orin
Ayáni-lówó ló ńdá orin nípa di dari èlé ori owó Ike-ìyáwó
Ẹni ti o fi owó pamọ́ ki ri èlé gbà tó èlé ti ó wà lori owò Ike-ìyáwó
Nibiti èlé owó ipamọ́ bá jẹ́ idá-ọgọrun, èlé owó ori ike-ìyàwó lè tó idá-marun tàbi jù bẹ́ẹ̀ lọ
Bi owó bá ti tó san, ọ̀pọ̀ Ayáni-lówó lè fi ipá gba owó irú bẹ́ẹ̀
Bi wọn kò ti ẹ̀ fi ipá gba irú owó bẹ́ẹ̀, èlé ori owó yi á sọ ẹni ti ó yá owó di Onigbèsè rẹpẹtẹ
Ike-ìyáwó ni iwúlò fún ẹni ti ó bá lè kó ara rẹ ni ijánu lati dá owó padà nígbàtí ó bá yẹ
Ike-ìyáwó dùn lati nọ́ ju owó gidi lọ nítorí eyi, fún ẹni ti kò bá mọ owó ṣirò tàbi ṣọ́ra, á sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ di òtòṣi, nígbàtí èlé bá gun ori èlé
Onigbèsè pàdánù òmìnira
Ìmọ́tótó borí àrùn mọlẹ̀, bọ́yẹ́ ti ḿborí ooru
Àrùn ìwọ̀sí tinú ẹ̀gbin là wá
Iná ni ḿborí aṣọ ẹlẹ́gbin
Ni ayé àtijọ́ tàbi, lati bi agogo marun idaji ni ìmọ́tótó ti bẹ̀rẹ̀, nípa gbigbá inú àti àyiká ilé
Lẹhin eyi, àwọn àgbàlagbà á ṣe itọ́jú ara, wọn o si bójú tó bi àwọn ọmọ ilé-iwé yio ti ji, wẹ̀, múra, jẹun àti palẹ̀mọ́ àti kúrò ni ilé lọ si ilé-iwé àti ki àwọn àgbàlagbà lọ si ibi iṣẹ́ òòjọ́
Mọ́inmọ́in
Ọ̀lẹ̀lẹ̀ Eléwé
Pàǹtí ni àtijọ́ wúlò fún ajílẹ̀ nítorí ara oúnjẹ ni
Ewé ni wọn fi ńpọ́n oúnjẹ tàbi ki wọn bu oúnjẹ sinú abọ́ àlò-tún-lò, omi wa ninú àmù, ṣùgbọ́n láyé òde òni, ike aláyọ́ ni wọn fi ńbu oúnjẹ, wọn a si mu omi ninú àpò ọ̀rá
Ike àti ọ̀rá ki kẹ̀, ó si léwu fún ẹja odòàti ẹranko lati gbé mi, ó tún léwu fún àyìká
Àwọn ọ̀rá àti ike wọnyi pẹ̀lú nkan ti ó dá kún pàǹtí
Ìmọ́tótó jinà si àwọn ara ilú ńlá, pàtàkì, ilú Èkó nibiti ọpọ òṣiṣẹ́ ti ji jade lọ si ibi iṣẹ́ ki agogo marun idaji tó lù, bẹni wọn kò ni wọlé titi di agogo mẹwa alẹ́ nítorí sún-kẹrẹ fà kẹrẹ ọkọ̀
Eyi kò lè jẹ ki wọn ri àyè tọ́jú inú ilé, àyiká tàbi ara
Ìjọba tún dá kún ẹ̀gbin ti ó gba ilú kan nítorí ai pèsè àyè àti itọ́jú fún pàǹtí
Eleyi ńjẹ́ ki ará ilú kó ohun ẹ́gbin si ibikibi, bi oju-àgbàrá, ẹ̀bá-ọ̀nà, ori titi, inú odò àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Kikó ohun ẹ̀gbin di ojú-àgbàrá ńfa adágún omi ti ó ńfa ẹ̀fọn, ikún omi àti àrùn lati ara kòkòrò ti pàǹtí fa
Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni Ìmọ́tótó borí àrùn mọ́lẹ̀, bi ọyẹ́ ti ḿborí ooru àti orin Ìmọ́tótó ti wọn fi ńkọ́ àwon ọmọ ilé-iwé alakọbẹrẹ ṣe iranti à ti wá nkan ṣe si pàǹtí ti ó gba ilú kan
Ògòngò jẹ ẹiyẹ ti ó tóbi jù ninú gbogbo ẹiyẹ, ẹyin rẹ ló tún tóbi jù
Ọrùn àti ẹsẹ̀ rẹ ti ó gún jẹ́ ki ó ga ju gbogbo ẹiyẹ yoku
Ògòngò ló lè sáré ju gbogbo eiye lọ lóri ilẹ̀
Eyi ló jẹ́ ki Yorùbá pe Ògòngò ni Ọba Ẹiyẹ
Ọpọlọpọ ẹiyẹ bi Ògòngò kò wọ́pọ̀ mọ́ nítorí bi ilú ti nfẹ si bẹni àwọn eiye wọnyi nparẹ́, a fi bi èniyàn bá lọ si Ilé-ikẹransi lati ri wọn
Àwọn onírúurú ẹiyẹ ló wà ni ilẹ̀ Yorùbá, àwọn eyi ti ó wọ́pọ̀ ni ilú tàbi ilé ni, Adiẹ, Pẹ́pẹ́yẹ, Ẹyẹlé, Awó, Ayékòótó́ àti Ọ̀kín
Àwọn ẹiyẹ ti ó wọ́pọ̀ ninú igbó ṣùgbọ́n ti ará ilú mọ̀ ni Àṣá, Ìdì, Òwìwí, Àkàlàmàgbò àti Lekeleke
Àwọ̀ oriṣirisi ni ẹiyẹ ni, irú ẹiyẹ kan lè ni àwọ̀ dúdú bi aró, kó́ tun ni pupa tàbi funfun, ṣùgbọ́n orin Yorùbá ni ojú ewé yi fi àwọ̀ ti ó wọ́pọ̀ lára àwọn ẹiyẹ miran hàn
Fún àpẹrẹ, Lekeleke funfun bi ẹfun, Agbe dúdú bi aró, bẹni Àlùkò pọn bi osùn
Ẹ ṣe àyẹ̀wò àwòrán àti pipè orúkọ di ẹ ninú àwon ẹiyẹ ti ó wọ́pọ̀ ni ilẹ̀ Yorùbá, ni ojú ewé yi
Wúrà jẹ ikan ninú ohun àlùmọ́ni iyebiye, pàtàkì fún ohun ẹ̀ṣọ́
Ẹwà Wúrà ki hàn, titi di ìgbà ti wọn bá yọ gbogbo ẹ̀gbin rẹ̀ kúrò pẹ̀lú iná tó gbóná rara
Àwòrán ti ó wà ni ojú ewé yi fihàn pé bi Wúrà bá ti pọ̀ tó lára ohun ẹ̀sọ́ ló ṣe má wọn tó, ki ṣé bi ohun ẹ̀ṣọ́ bá ti dán tó tàbi tóbi
Fún àpẹrẹ, àwòrán ohun ẹ̀ṣọ́ Wúrà kini tóbi, ó si dán ju àwòrán ohun ẹ̀ṣọ́ Wúrà keji, ṣùgbọ́n ohun ẹ̀sọ́ Wúrà ninú aworan keji wọn ju ohun eso Wúrà kini ni ìlọ́po mẹwa
Ìyàtọ̀ ti ó wà ni Wúrà gidi àti àfarawé ni pé, Wúrà gidi ṣe é tà fún owó iyebiye lẹhin ti èniyàn ti lo o, kò lè bàjẹ, bi ó bá kán, ó ṣe túnṣe, ṣùgbọ́n àfarawé kò bá ara ẹlòmiràn mu, bi ó bá kán, kò ṣe é túnse, kò ki léwó
Gẹ́gẹ́bi òwe Yorùbá ti ó sọ pé Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà, bẹni ki ṣe gbogbo èniyàn ti wọ̀n pè ni Olówó tàbi Ọlọ́rọ̀ ló tó bi àwọn èniyàn ti rò
Ọ̀pọ̀ irú àwọn wọnyi, jẹ igbèsè tàbi fi èrú kó ọrọ̀ jọ lati ṣe àṣe hàn, òmiràn ja olè, gbọ́mọgbọ́mọ àti onirúurú iṣẹ́ ibi yoku
Gbogbo ohun ti wọn fi ọ̀nà èrú kó jọ wọnyi kò tó nkankan lára ọrọ̀ ti ẹlòmiràn ti ó ni iwà-irẹ̀lẹ̀ ni
Fún àpẹrẹ, owó ti àwọn Òṣèlú àti Òṣiṣẹ́-Ìjọba ilẹ̀ Aláwọ̀-dúdú fi èrú kó jọ, ti wọn nkó wá si Òkè-òkun tàbi fi mú àwọn èniyàn wọn lẹ́rú, kò tó ọrọ̀ ti ọmọdé ti ó ni ẹ̀bun-Ọlọrun ni Òkè-òkun ni
A lè fi òwe Gbogbo ohun tó ndán kọ́ ni Wúrà gba ẹnikẹ́ni ni iyànjú pé ki wọn ma ṣe àfarawé, tàbi kánjú lati kó ọrọ̀ jọ
Àfarawé léwu, nítorí ki ṣe gbogbo ohun ti èniyàn ri ló mọ idi rẹ̀
Babá re lé ò
Ilé ló lọ́ tarà-rà
Bàbá re lé ò
Ilé ló lọ́ tarà-rà
Ilé ò, ilé, Ilé ò, ilé
Babá re lé ò
Ilé ló lọ́ tarà-rà
Ni Àṣà Yorùbá, ọmọdé ló nkú, àgbà ki kú, àgbà ma nrelé ni
Ọ̀fọ̀ ni ikú ọmọdé jẹ́, ijó àti ilú ni wọn fi nṣe ìsìnku àgbà lati sín dé ilé ikẹhin
Ìròyìn ikú Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí kàn lẹhin ikú rẹ ni ọjọ́ kẹsan, oṣù kẹjọ,ọdún Ẹgbàálemẹ̀rinlá
A bi ni ilú Ìkọ̀lé-Èkìtì ni ọdún marun-le-lọgọrin sẹhin
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọ̀jọ̀gbọ́n, ọmọdé àti àgbà ilú lati onírúurú iṣẹ́àti àwọn èniyàn pàtàkì ni ilé-lóko péjọ ni ọjọ kọkàn-din-logun, oṣù kẹsan, ọdún Ẹgbàálemẹ̀rinlá lati ṣe ìsìnku rẹ
Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ pé Ẹni ti kò bá mọ ìtàn ara rẹ, yio dahun si orúkọ tí kò jẹ́
Ki awọn bi Olóògbé tó bẹ̀rẹ̀ si kọ Ìtàn Yorùbá àti ilẹ́ Aláwọ̀-dúdú silẹ̀, àwọn Aláwọ̀-funfun kò rò pé Aláwọ̀-dúdú ni Ìtàn nítorí wọn kò kọ silẹ̀, wọn nsọ Ìtàn lati ẹnu-dé-ẹnu ni
Nítorí eyi, ohun ti ó wu Aláwọ̀-funfun ni wọn nkọ
Olóògbé Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí, kọ́ ẹ̀kọ́, ó si gboyè rẹpẹtẹ lori Ìtàn, pàtàkì lati jẹ́ ki Yorùbá mọ ìtàn ara wọn
Ó lo imọ̀ yi lati kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ iwé itan, ikan lára iwé wọnyi ni Ìtàn àti Ogun jijà Yorùbá
Ó tún kọ nípa Ìgbési-ayé Olóògbé Olóri àwọn Alufaa Àjàyí Crowther àti Onidajọ Káyọ̀dé Ẹ̀ṣọ́
Yorùbá pa òwe pé Àgbà ki wà lọ́jà, ki ori ọmọ titun wọ, Olóògbé Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí ni Igbá-keji Ilé-ẹ̀kọ́ Giga, Èkó kẹta
Nítorí ìfẹ́ ti ó ni si ìdàgbà sókè Ilé-ẹ̀kọ́ Giga, ìtàn àti ìpamọ́ ohun-ìtàn, ó kọ iwé si Olóri Òṣèlú Nàíjíríà, nigbà Ìporúkọdà lójiji lati Ilé-ẹ̀kọ́ Giga Èkó si orúkọ Olóògbé MKO Abiọ́lá – ti gbogbo ilú dibò fún lati ṣe Olóri Òṣèlú, ṣùgbọ́n àwọn Ìjọba Ológun kò jẹ́ kó dé ipó yi
Olóri Òṣèlú Nàíjíríà yi ọkàn padà lati ma yi orúkọ Ilé-ẹ̀kọ Giga yi padà lojiji nítorí ọ̀wọ̀ ti ó ni fún Olóògbé
Igbá-keji Ilé-ẹ̀kọ́ Giga Èkó, lọ́wọ́lọ́wọ́, Ọ̀jọ̀gbọ́n Adisa Bello juwe pe, àsikò ti Olóògbé Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí jẹ́ Igbá-keji Ilé-ẹ̀kọ́ Giga Èkó kẹta ni ọdún keji-le-lógóji titi di ọdún kẹrin-din-lógóji ni wọn kọ́ ọ̀pọ̀lọpọ ohun amáyé-dẹrùn fún Akẹkọ ti ó wà titi di ọjọ́ òni àti ibẹ̀rẹ̀ Ẹgbẹ àwọn ti ó kàwé jáde
Ni igbà ayéOlóògbé Ọj̀ọ̀gbọ́n-Àgbáyé Adé Àjàyí, pẹlu idùnú, ẹbi, ọ̀rẹ́, ojúlùmọ̀, àti àwọn èniyàn pàtàkì lati ilé àti Òkè-okun péjọ lati ṣe ìrántíọjọ́-ìbí karun-le-ọgọrin
Wọn gbé iwé ti wọn kọ nípa igbési-ayé rẹ si ìta, bẹni wọn fi hàn pé ó jẹ́ Ọmọluwabi ti wọn fẹ́ràn
Ayé yẹẹ́
Gbogbo Olùkọ̀wé Àṣà àti èdè Yorùbá lóri ayélujára gbàdúrà ki ọ̀run yẹ àti ki iṣẹ́ ti óṣe silẹ̀ má bàjẹ́ lágbára Èdùmàrè. Àṣẹ
Ódìgbóṣe, sùn re o
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ ni, ìlàjú lóri ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán àti ẹ̀rọ asọ̀rọ̀-mágbèsi gbàlà lọ́wọ́ ikú igbẹ́-gburu, nípa ìmọ̀ Omi Oni-yọ lati dipò omi ara
Ẹ ṣe àyẹ̀wò àpẹrẹ bi Àbíkú ti din-ku ni orilẹ̀ èdè Nàíjíríà, nítorí eyi orúkọ Àbíkú din-kù
Ikú ọmọ ti kò ti pé ọdún marun ni ọdún mẹrinlélógún sẹhin jẹ́ Igbalémẹ́tàlá
Ikú ọmọ ti kò ti pé ọdún marun ni ọdún keji sẹhin ti din-kù si Mẹrin-lé-lọgọfa
Ìgbàgbọ́ Yorùbá yàtọ̀ si ohun ti àwọn Ẹlẹko-Ijinlẹ fi hàn ni ayé òde òni
Ni igbà àtijọ́, bi ìyàwó bá bi ọmọ, ti ó kú ni ikókó tàbi ki ó tó gba àbúrò, ọmọ ti wọn bá bi lẹhin rẹ ni wọn ma fún ni orúkọ Àbíkú pàtàkì ti ó bá tó bi méjì, mẹta ki ọmọ tó dúró
Yorùbá gbàgbọ́ ninú àpadà-wáyé, ni igbà miran, wọn á fi ibinú fi àmin, bi ki wọn kọ ilà si ara ọmọ ti ó kú tàbi gé lára ẹ̀yà ara ọmọ yi lati mọ bóyá yio padà wá
Bi ìyá ti ó bi Àbíkú bá bímọ lẹhin ikú ọmọ ti wọn fi àpá si lára, àpá yi ni wọn ma kọ́kọ́ wò lára ọmọ titun
Bi wọn bá ri àpá yi, wọn o sọ ọmọ naa ni orúkọ Àbíkú
Orúkọ àbùkù ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ orúkọ Àbíkú – ó lè jẹ́ orúkọ ẹranko, orúkọ ti ó fi ìbẹ̀rù hàn, tàbi orúkọ fún ìmọràn
Àbíkú jẹ́ ikú ọmọdé àti ìkókó titi dé ọmọ ọdún marun
Ẹkọ-Ijinlẹ fi hàn pé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ikú ọmọdé ti Yorùbá mọ̀ si Àbíkú yi ti ìpasẹ̀ wọnyi wá àrùn tó ṣe-dádúró, oúnjẹ-àìtó, omi-ẹlẹgbin, ilé-iwòsàn ti kò pé tàbi ai si ilé-iwòsàn, àrùn àti àjàkálẹ̀-àrùn, ọmọ ti ó ni iwọn-kékeré nigbà ìkókó
Òwe Yorùbá ti o ni Àbíkú sọ Olóògùn di èké fi ìgbàgbọ́ Yorùbá hàn pé, kò si oògùn ti ó lè dá Àbíkú dúró
Ìmọ̀ Ijinlẹ fi hàn pe ki ṣe gbogbo ọmọ ti ó kú, ni ó yẹ ki ó kú, nítorí lati igbà ti àtúnṣe àwọn ohun ti ó nfa ikú ọmọdé yi ti wà, Àbíkú din-kù – nípa ìpèsè omi ti ó mọ́, ilé-ìwòsàn ọmọdé, ilà-lóye àwọn obinrin nípa ìtọ́jú aboyún àti ọmọdé
Òrùlé wà lára ohun ini pàtàkì ti ó yẹ ki èniyàn ni, ṣùgbọ́n èniyàn kò lè sun yàrá méjì pọ̀ lẹ́ẹ̀kan
Ki ṣe bi èniyàn bá fi owó ara rẹ̀ kọ́ ilé ni ìbẹ̀rẹ̀ ilé gbigbé
Bàbá á pèsè òrùlé fún aya àti ọmọ, ki ba jẹ ilé ẹbi, abà oko, ihò inú àpáta, ilé-àyágbé tàbi kọ́ ilé fún wọn
Ni ayé òde oni, ilé ṣi jẹ ohun pàtàkì fún èniyàn, ṣùgbọ́n á ṣe akiyesi pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ Yorùbá, kò ránti ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó sọ pé Ọ̀kọ́lé, kò lè mu ràjò mọ́
Ọ̀pọ̀ nkọ́ ilé àìmọye ti èniyàn ò gbé, lai ronú pé, bi àwọn bá ràjò, wọn ò lè gbé ikan ninú ilé yi dáni
Ọ̀pọ̀ nkọ́ ilé fún àwọn ọmọ – fún àpẹrẹ, ẹni ti ó kọ ilé marun nítorí ohun bi ọmọ marun si ilú ti wọn ngbé tàbi bi ọmọ si
Ò̀we Yorùbá sọ pé Ọ̀nà ló jin, ẹru ni Baba
Ẹ jẹ́ ki á fi òwe yi ṣe iranti pé, ayé ti lu jára, ọmọ, ẹbi àti ará kò gbé pọ̀ mọ́ bi igbà ayé-àgbẹ̀
Bi wọn bá ti ẹ̀ gbé ilú kan naa, ìṣòro ni ki ọmọ bá Bàbá àti Ìyá gbé lọ lai-lai
Bi ó pẹ́, bi ó yá, ọmọ tó dàgbà, á tẹ si iwájú nítorí bi Bàbá bá kọ́ ilé rẹpẹtẹ si Agége, kò wúlò fún ọmọ ti o nṣiṣẹ ni Ìbàdàn, Àkúrẹ́ tàbi Òkè-òkun
Bi Bàbá ti ó kọ ilé rẹpẹtẹ bá fẹ́ lọ ki àwọn ọmọ, ẹbi tàbi ọ̀rẹ́ ni ilú miran, ìṣòro ni ki ó gbé ikan ninú ilé rẹpẹtẹ yi dáni
Ọ̀pọ̀ oníjìbìtì, Òṣèlú, Oníṣẹ́-Ìjọba ti ó ni ojúkòkòrò ló nkó owó ilé lọ sita lati lọ ra ilé si Òkè-Òkun lai gbé ibẹ̀, ju pé ki wọn lo o ni ọjọ melo kan lọ́dún
Ìnáwó rẹpẹtẹ ni lati tọ́jú ilé si Òkè-Òkun tàbi ilé ti èniyàn kò gbé , nítorí eyi, ọ̀pọ̀ ilé yi kò bá àwọn ti ó kọ́ ilé tàbi ra ilé kiri yi kalẹ̀
Àwọn Òṣèlu àti Oníṣẹ́ Ìjọba ti ó nja ilú lólè, lati fi owó ti wọn ji pamọ́ nípa ki kọ́ ilé rẹpẹtẹ tàbi ra ilé si Òkè-Òkun ni Orúkọ ọmọ, òbí tàbi orúkọ ti kò ni itumọ, kò lè gbé ilé wọnyi lọ irin àjò tàbi lọ si ọ̀run ti wọn bá kú
Ni ayé igbà kan, ọ̀gbẹlẹ̀ wa ni ilú àwọn ẹranko, nítorí ọ̀dá òjò fún igbà pi pẹ́
Ọ̀gbẹlẹ̀ yi fa ìyàn, wọn kò ri omi mu tàbi wẹ̀
Eleyi mú ki gbogbo ẹranko pé jọ lati kó ọgbọ́n pọ̀ bi àwọn yi o ṣe ri omi
Kìnìún, Ẹkùn, Erin, Ẹfọ̀n, Àgbọ̀nrín, Òkété, Ehoro, Ọ̀kẹ́rẹ́, Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, Àjàpá, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Wọn yan Kìnìún ni Alaga, Ẹkùn jẹ́ igbá keji, Erin jẹ́ Baálẹ̀
Yorùbá sọ pé A sọ̀rọ̀ ẹran ti ó ni ìwo, ìgbín yọjú, Àjàpá binú kúrò ni ìpàdé nítorí wọn kò yan ohun si ipò Alaga
Àwọn ẹranko yoku mba ìpàdé lọ, oníkálùkù mú ìmọ̀ràn wá, Àgbọ̀nrín ni ki wọn ṣe ètùtù si Òriṣà-Omi, Òkété ni ki wọn lo ọgbọ́n àti agbára ti Ọlọrun fún wọn, lati gbẹ́ ilẹ̀ jínjìn si ojú odò ti ó ti gbẹ
Lẹhin àpérò, wọn gba ìmọ̀ràn ti Òkété múwá, wọn gbẹ́ ojú odò titi wọn fi ri omi
Bi iroyin pé wọn ti ri omi ti kàn, Àjàpá ti kò bá wọn ṣiṣẹ́ nítorí ibinú, o gbìmọ̀ bi ohun yi o ti ṣe ẹ̀rù ba àwọn ẹranko yoku ni idi odò, ki ohun lè ri àyè dá pọn omi
Ó sọ ara rẹ di Ànjọ̀nú, ó so agbè púpọ̀ pẹ̀lú okùn ti yio fi pọn omi mọ́ gbogbo ara, ó ji lọ idi odò lati dá nikan pọn omi
Ó bẹ̀rẹ̀ si kọrin
Ìparí ọdún sún mọ́lé, àsikò yi ni àwọn oníjìbìtì ma nbọ́ sita lati ṣe iṣẹ́ ibi, nípa ji ja àwọn ará ilú ti kò bá funra ni olè
Ìparí ọdún sún mọ́lé, àsikò yi ni àwọn ẹlẹ́tàn ma nbọ́ sita lati ṣe iṣẹ́ ibi, nípa ji ja àwọn ará ilú ti kò bá funra ni olè
Àṣà Yorùbá ni ayé àtijọ́ ni lati gbé àwọn ti ó bá hùwà rere ga, lati yẹ àwọn ti ó bá ṣe iṣẹ́ àṣe yọri si
Yorùbá ni Ọmọ ẹ o ṣe àgbàfọ̀, ó kó aṣọ wálé, ẹ ò ri ojú olè bi, ọ̀pọ̀ òbi ki bèrè bi ọmọ wọn ti ri owó mọ nítorí àwọn ẹlẹ̀tàn ori ayélujára àti Òṣèlú nkó ohun ti ki ṣe ti wọn wálé
Ẹ̀sìn àti àṣà ayé òde òni ngbe àwọn olè àti oníjìbìtì lárugẹ
Nítorí eyi olówó ojiji pọ si láwùjọ laarin ẹni ti ó wà ni ipò giga àti ipò kékeré
Iṣẹ́ Ọlọrun àti Òṣèlú ti di ọ̀nà ti èniyàn fi le di olówó lojiji
Ọ̀̀pọ̀ ọmọ ilé-iwé giga ti kò ti ilé-ọlọ́rọ̀, tàbi ilé Òṣèlú jade, ti yi si olè jijà lori ayélujára ju pé ki wọn di gun jalè
Ni ayé àtijọ́, bi ọdún bá dé, olè jija pẹ̀lú ipá ló wọ́pọ̀, ṣùgbọ́n ni ayé òde òni iwà ẹ̀tàn ti a mọ̀ si oníjìbìtì pàtàkì ni ori ayélujára ló wọ́pọ̀
Ó ti pẹ ti ẹ̀tàn ori ayélujára ti bẹ̀rẹ̀ ṣùgbọ́n, irú àsikò yi ni àwọn oníjìbìtì ma nko ọ̀pọ̀ iwe lori ayélujára si ẹgbẹgbẹ̀rún èniyàn ni àgbáyé pẹ̀lú èrò lati jẹ nibi ti wọn kò ṣe si
Ẹni ti kò bá funra á jábọ́ si wọn lọwọ, nítorí eyi ẹ ṣọ́ra fún àdàmọdi iwé lati ilé-ifowó-pamọ́ tàbi ọ̀dọ̀ ẹni ti ẹ kò mọ̀
Fún àwọn ti ó wà ni òkè-òkun – America, wọn ni ọjọ́ ti wọn ya si ọ̀tọ̀ gẹ́gẹ́ bi Ọjọ́ Ọpẹ́
Oúnjẹ pọ rẹpẹtẹ ni àsikò yi pàtàkì ni Ọjọ́ Ọpẹ́, Keresimesi àti ọjọ́ ọdún tuntun
Ọ̀pọ̀ á jẹ àjẹ-bi, á tún dà yókù dànù
Ni àṣà ibilẹ Yorùbá, ọjọ́ gbogbo ni ọpẹ́ pàtàkì fún àwọn Yorùbá ti ó jẹ́ Onigbàgbọ́
Kò si ọjọ́ ti ilú yà sọ́tọ̀ fún Ìdúpẹ́, ṣùgbọ́n lati idilé si idilé, ọjọ́ ọpẹ́ pọ
Ki kómọ jade, iṣile, di dé lati àjò láyọ̀, ikórè ni Ìjọ Onigbàgbọ́, ọdún ibilẹ̀ bi Ìjẹṣu àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, mú ọpẹ́ àti ọ̀pọ̀ oúnjẹ dáni
Ọ̀rọ̀ Yorùbá ti ó sọ pé Ai jẹun Ológbò kọ́ ni kò jẹ́ kó tó Ajá, bẹni ki ṣe ai jẹun ajá ni kò jẹ́ kó tó Erin
Fihàn pé, ki ṣe bi a ti jẹun tó, ni a ṣe nga tó, nítorí kò si bi Ológbò ti le jẹun tó, kó tó Ajá, tàbi ki Ajá jẹun titi kó tó Erin
Oúnjẹ púpọ̀ kò mú ara líle wá, nítorí ọ̀pọ̀ àfoògùn-gbin oúnjẹ ayé òde òni lè fa àìsàn
A ki àwọn ti ó nṣe Ìdúpẹ́ pé wọn kú ọdún o
A gbà wọn ni iyànjú ki wọn jẹun niwọn nítorí ọ̀pọ̀ ló wà ni àgbáyé ti kò ri oúnjẹ lati jẹ
Ní ayé àtijọ, Yáníbo ìyàwó Ìjàpá gbìyànjú títí ṣùgbọ́n kò rí ọmọ bí
Ní ayé àtijọ, Yáníbo ìyàwó Àjàpá gbìyànjú títí ṣùgbọ́n kò rí ọmọ bí
Ọmọ bíbí ṣe pàtàkì ní ilẹ̀ Yorùbá, nítorí èyí ìrònú ma mba obìnrin tí kò bá ri ọmọ bi tàbí tí ó yà àgàn
Babaláwo se àsèjẹ fún Yáníbo, ó rán Ìjàpá láti lọ gba àsàjẹ yi lọ́wọ́ Babaláwo
Ó dé́lé ó gbé irọ́ kalẹ̀ fún ìyàwó, ṣùgbọ́n láìpẹ́ ikùn Ìjàpá bẹ̀rẹ̀ sí wú
Yorùbá ni ohun ti a ni ki Baba mágbọ, Baba ni yio parí rẹ
Bi ikùn ti nwu si bẹni ara bẹ̀rẹ̀ si ni Ìjàpá, ó ba rọ́jú dìde, ó ti orin bẹnu bi o ti nsáré tọ Babaláwo lọ
Nígbátí ó dé ilé́ Babaláwo, Babaláwo ni ko si ẹ̀rọ̀
Ikùn Ìjàpá wú títí o fi bẹ, tí ó sì kú
Ìtàn yí kọ wa pe èrè ojúkòkòrò, àìgbọ́ràn, irọ́ pípa àti ìwà burúkú míràn ma nfa ìpalára tàbí ikú
Ìtàn náà bá gbogbo aláìgbọràn àti onírọ́ wí
Òwe yi wúlò lati gba àwọn ènìà tí o gbójúlé ẹbí níyànjú
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ rò wípé ẹ̀tọ́ ni ki ẹni tí ó bá lówó nínú ẹbí tàbí tí ó ngbe ni Òkè-Òkun bá wọn gbé ẹrù lai ro wípé ẹbí tí o lówó tàbí gbé l'Ókè-Òkun ní ẹrù tiwọn lati gbé
Iṣẹ́ lẹ́ni tí ó wa l'Ókè-Òkun nṣe nínú òtútù
Fún àpẹrẹ níbití olówó tàbí àwọn tí ó ngbe Òkè-òkun tí nṣe àwọn nkan níwọnba bí – ọmọ bíbí, aṣo rírà, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbójúlẹ́bí á bímọ rẹpẹtẹ, kó owó lé aṣọ, bèrè ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ olówó nla tí ẹni tí ó wà l'Ókè-Òkun ó lè kó owó lé lórí àti gbogbo àṣejù míràn
Ẹbí olówó tàbí tí ó ngbe Òkè-òkun kò lè dípò Ìjọba
Ọ̀dọ̀ Ìjọba tí ó ngba owó orí lóyẹ kí á ti bèrè ẹ̀tọ́, ki ṣe lọ́wọ́ ẹbí
Ọ̀rọ̀ Yorùbá ni Bi ọmọdé bá tó ni ọkọ́, à fún lọ́kọ́
Ọkọ́ jẹ irinṣẹ́ pàtàkì fún Àgbẹ̀
Iṣẹ́-àgbẹ̀ ni ó wọ́pọ̀ ni ayé àtijọ́
Nítorí eyi, bi bàbá ti nkọ́ ọmọ rẹ ọkùnrin ni iṣẹ-àgbẹ̀, ni ìyá nkọ́ ọmọ obinrin rẹ ni ìtọ́jú-ile lati kọ fún ilé-ọkọ
Iṣẹ́ la fi nmọ ọmọ ọkùnrin, nítorí eyi, bi ọkùnrin bá dàgbà, bàbá rẹ á fun ni ọkọ́ nítorí ki ó lè dá dúró lati lè ṣe iṣẹ́ ti yio fi bọ́ ẹbi rẹ ni ọjọ́ iwájú
Bi ọkùnrin bá ni iṣẹ́, ó ku kó gbéyàwó ti yio jẹ Olorì ni ilé rẹ
Ìyàwó fi fẹ́ bu iyì kún ọkùnrin, nítorí, ó fi hàn pé ó ni igbẹ́kẹ̀lé
Àṣà Yorùbá gbà fún ọkùnrin lati fẹ́ iye ìyàwó ti agbára rẹ bá gbé lati tọ́jú
Nítorí eyi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ Ọba, Baálẹ̀, Ìjòyè àti àwọn enia pàtàkì láwùjọ ma nfẹ ìyàwó púpọ̀
Ìṣòro ni ki wọn fi ọkùnrin ti kò ni ìyàwó jẹ Ọba
Kò wọ́pọ̀ ki Ọba ni ìyàwó kan ṣoṣo
Ìwúyè Ọba Àkúrẹ́, Olóògbé Ọba Adebiyì Adeṣida
Ohun ti a ṣe akiyesi ni ayé òde òni, ni Ọba ti ó fẹ ìyàwó kan ṣoṣo nítorí ẹ̀sìn, pàtàkì ẹ̀sìn Ìgbàgbọ́, ṣùgbọ́n ti ó ni àlè rẹpẹtẹ
Ọba ayé òde òni ndá nikan lọ si òde lai mú Olorì dáni
Gẹgẹbi ọ̀rọ̀ Yorùbá, Àpọ́nlé kò si fún Ọba ti kò ni Olorì, nítorí eyi, kò bu iyì kún Ọba, ki ó lọ àwùjó tàbi rin irin àjò pàtàkì lai mú Olorì dáni
Ohun ti ó yẹ Ọba ni ki a ri Ọba àti Olorì rẹ ni ẹ̀gbẹ́ rẹ
Ìtàn ti ó wọ́pọ̀ ni, bi iyá-ọkọ ti burú lai ri ìtàn iyá-ọkọ ti ó dára sọ
Eyi dákún àṣà burúkú ti ó gbòde láyé òde òni, nípa àwọn ọmọge ti ó ti tó wọ ilé-ọkọ tàbi obinrin àfẹ́sọ́nà ma a sọ pé àwọn ò fẹ́ ri iyá-ọkọ tàbi ki iyá-ọkọ ti kú ki àwọn tó délé
Ni ayé àtijọ́, agbègbè kan na a ni ẹbi má ngbé – bàbá-àgbà, iyá-àgbà, bàbá, iyá, ẹ̀gbọ́n, àbúrò, ìyàwó àgbà, ìyàwó kékeré, ìyàwó-ọmọ, àwọn ọmọ àti ọmọ-mọ
Ṣùgbọ́n ni ayé òde òni, ọ̀pọ̀ kò fẹ́ ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ mọ, ẹbi ti fúnká si ilú nlá àti òkè-òkun nítorí iṣẹ́ ajé àti iṣẹ́-ijọba
Ni ọ̀pọ̀ ọdún sẹhin, iyá kan wà ti a o pe orúkọ rẹ ni Tanimọ̀la ninú ìtàn yi
Ó bi ọmọ ọkùnrin meje lai bi obinrin
Kékeré ni àwọn ọmọ rẹ wà nígbàtí ọkọ rẹ kú
Tanimọ̀la fi ìṣẹ́ àti ìyà tọ́ àwọn ọmọ rẹ, gbogbo àwọn ọkùnrin na a si yàn wọn yanjú
Nígbàtí wọn bẹ̀rẹ̀ si fẹ́ ìyàwó, inú rẹ dùn púpọ̀ pé Ọlọrun ti bẹ̀rẹ̀ si dá obinrin ti ohun kò bi padà fún ohun
Ó fẹ́ràn àwọn ìyàwó ọmọ rẹ gidigidi ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ọmọ rẹ kó lọ si ilú miran pẹ̀lú ìyàwó wọn nítorí iṣẹ́
Àbi-gbẹhin rẹ nikan ni kò kúrò ni ilé nítorí ohun ló bójú tó oko àti ilé ti bàbá wọn fi silẹ
Nígbàtí ó fẹ ìyàwó wálé, inú iyá dùn pé ohun yio ri ẹni bá gbé
Ìyàwó yi lẹ́wà, o si ni ọ̀yàyà, eyi tún jẹ́ ki iyá-ọkọ rẹ fẹ́ràn si gidigidi
Yorùbá ni Ẹni a fẹ́ la mọ̀, a ò mọ ẹni tó fẹni
Tanimọ̀la kò mọ̀ pé àjẹ́ ni ìyàwó-ọmọ ti ohun fẹ́ràn, ti wọn jọ ngbé yi
Bi Tanimọ̀la bá se oúnjẹ, ohun pẹ̀lú ọmọ àti ìyàwó-ọmọ rẹ ni wọn jọ njẹ ẹ
Bi ìyàwó bá se oúnjẹ, á bu ti iyá-ọkọ rẹ
Kò si ìjá tàbi asọ̀ laarin wọn ti ó lè jẹ ki iyá funra
Yorùbá gbà pé ohun burúkú ni ki enia jẹun lójú orun
Ni ọjọ́ kan, iyá ké lati ojú orun ni bi agogo mẹrin ìdájí òwúrọ̀, pe ìyàwó-ọmọ ohun ti fún ohun ni oúnjẹ jẹ ni ojú orun
Ìyàwó-ọmọ rẹ kò sẹ́, bẹni kò sọ nkan kan
Ọkọ rẹ kò gba iyá rẹ gbọ
Lati igbà ti iyá ti ké pé ohun jẹ àsáró-iṣu ti ìyàwó-ọmọ ohun gbé fún òhun jẹ lójú orun ni inú rirun ti bẹ̀rẹ̀ fún iyá
Inú rirun yi pọ̀ tó bẹ gẹ ẹ ti wọn fi gbé Tanimọ̀la kúrò ni ilé fún ìtọ́jú
Wọn gbiyànjú titi, kò rọrùn, nítorí eyi, Tanimọ̀la ni ki wọn gbé ohun padà lọ si ilé ki ohun lọ kú
Ki Tanimọ̀la tó kú, ó pe gbogbo ilé lati ge ẹgun fún ìyàwó-ọmọ rẹ pé Òhun jẹ ìyá lóri ọmọ, nígbàtí àsikò àti jẹun ọmọ tó, ìyàwó-ọmọ ṣe ikú pa ohun
Nítorí eyi, ìyàwó-ọmọ yi ko ni jèrè ọmọ rẹ, ẹlòmiràn ni yio wo ọmọ rẹ dàgbà
Ó ni à fi ti ó bá jẹ ẹ̀ṣẹ̀ ni lati ni ifẹ́ ìyàwó-ọmọ
Bi ó ti ge ẹ̀gún tán ni o mi imi ikẹhin ti ó si kú
Yorùbá ni Ọlọrun àtijọ́, ló npẹ́ dájọ́, oṣù meje lẹhin ikú Tanimọ̀la, ìyàwó bẹ̀rẹ̀ si rù nítorí kò lè jẹun, kò pẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ àìsàn
Ó ni ohun kò lè sùn bẹni ohun kò lè jẹun nítorí iyá-ọkọ kò jẹ́ ki ohun gbádùn
Lóri àìsàn ni ó ti bẹ̀rẹ̀ si jẹ́wọ́ pé tòótọ́ ni ohun gbé oúnjẹ ti ohun gbà ninú ẹgbẹ́ àjẹ́ fún iyá-ọkọ ohun
Ó pariwo titi ó fi kú
Ìtàn yi fihàn pé ẹ̀san mbọ̀ fún oniṣẹ́ ibi
Ẹ̀kọ́ ni fún àwon ọmọge òde òni pé, ki ṣe gbogbo iyá-ọkọ ló burú, bó pẹ́ bóyá, ẹ̀san mbọ̀ fún ìyàwó ti ó ni ohun kò fẹ́ ri iya-oko, tàbi ki iyá-ọkọ kú ki ohun tó délé
Kò si ibi ti ẹ̀tàn tàbi ká dani kò ti lè wá
Ẹni ti ó bá ni iwà burúkú bi ojúkòkòrò, ìlara àti ìmọ-tara-ẹni nikan, lè dani tàbi tan-nijẹ
Ọmọ lè tan bàbá tàbi ìyá, ìyá tàbi bàbá lè tan ọmọ, ọkọ lè da aya, ọmọ-ìyá tàbi ẹbi ẹni lè tan ni jẹ, tàbi dani, ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ìgbà, èniyàn ki reti irú iwà yi lati ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́
Nítorí ifi ọkàn tàn si ọ̀rẹ́, ìbànújẹ́ tàbi ẹ̀dùn ọkàn gidi ni fún èniyàn ti ọ̀rẹ́ bá da tàbi tàn jẹ
Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ pé, Ọ̀rẹ́ dani kò tó pọ́n, abínibí a má dani
Ọ̀rọ̀ Yorùbá sọ pé, Ọ̀rẹ́ dani kò tó pọ́n, ẹbi a má dani
Òwe yi fihàn pé kò si ẹni ti kò lè dani tàbi tan ni jẹ, nítorí Àgbẹ́kẹ̀lé enia, asán ló jẹ́
A lè fi òwe yi ṣe ìtùnú fún ẹni ti irònú bá nítorí ọ̀rẹ́ da a, tàbi ti ó sọ ohun ribiribi nù nítorí ẹ̀tàn ọ̀rẹ́
Oriṣiriṣi ènìyàn miran tiki sọmọ Yorùbá pọ ni ìlú nla bi ti Èkó tàbí àwọn olú ìlù nla miran ni agbègbè ilẹ Yorùbá
fun àpẹrẹ Abéòkúta, Adó-Èkìtì, Akurẹ, Ìbàdàn, Oṣogbo, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Gẹ́gẹ́bí Wikipedia ti kọ, ni orílẹ̀ èdè Nàíjírià, èdè oriṣiriṣi lé ni ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lélógún, méjì ninu èdè wọ̀nyí ko si ẹni to nsọ wọn mọ, mẹsan ti parẹ́ pátápáta
Eleyi yẹ ko kọwa lọgbọn lati dura ki èdè Yorùbá maṣe parẹ
Ilé-ìwé alakọbẹrẹ ti àwọn ènìà nda silẹ
A ṣe àkíyèsí wipé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé-ìwé alakọbẹrẹ ti àwọn ènìà nda silẹ ti ki ṣe ti Ìjọba, kò gba àwọn ọmọ láyè lati kọ tàbi sọ èdè Yorùbá ni ilé ìwè
Eleyi lo jẹ ikan ninu ìdí pípa èdè Yorùbá tàbi èdè abínibí yoku rẹ
Bí àwọn ọmọ ba délé lati ilé ìwè, èdè gẹẹsi ni wọn mba òbí sọ nítorí ìbẹrù Olùkọ wọn to ni ki wọn ma sọ èdè abínibí
Bi òbí ba mba wọn sọ èdè Yorùbá àwọn ọmọ yio ma dahun lédè gẹẹsi
Kíkọ, kíkà èdè Yorùbá ko di ọmọ lọ́wọ́ lati ka ìwé dé ipò gíga
Ọmọdé lo ma tètè gbọ èdè ti wọn si le yara kọ òbí
Ìjọ̀gbọ̀n ni èdè aiyede ma nda silẹ nítorí náà ẹ majẹ ki a di àwọn ọmọ lọ́wọ́ ṣùgbọ́n, ka ran wọn lọ́wọ́ fún ìlọsíwájú èdè Yorùbá
Ó sàn ki gbogbo ọmọ tó parí ìwé mẹfa le kọ, ki wọn le kà Yorùbá tàbi èdè abínibí ju pé ki wọn ma le kọ, ki wọn ma lèkà rárá
Bi ọ̀pọ̀lọpọ̀ oníṣé ọwọ́, oníṣòwò àti àgbẹ̀ bá lè kọ́ lati kọ àti lati ka èdè Yorùbá ni ilé-ìwé ẹ̀kọ́ àgbà tàbi lẹ́hìn ìwé-mẹ́fà, á wúlò fún ìlú
Fún àpẹrẹ, wọn a le kọ orúkọ ní Ilé Ìfowópamọ́, kọ ọjọ́ ìbí ọmọ wọn sílẹ̀, kọ nípa iṣẹ́ wọn sí ìwé àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ
Ìwà alajẹtan ti bori iránti ohun ti Kérésìmesì wà fún